Atiku àti Davido sọ̀rọ̀ sókè nípa bí ìjọba Buhari ṣé ti àkáúntì ''cryptocurrency'' pa

Aworan afihan cryptocurrency

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Eti yin to gbọ alọ nipa ikede ijọba apapọ Naijria lati ti akaunti awọn to n ṣe karakata owo Crptocurrency yẹ ki o gbọ abọ.

Idi ree ti a fi ni ka mu tọ yin wa ohun tawọn ọmọ Naijriria ti n sọ nipa ikede yi.

Tolori tẹlẹmu lo ti n da si ọrọ. Ninu awọn to gbaujumọ taa le tọka si ni igbakeji aarẹ ana, Atiku Abubakar.

Atiku to jẹ gbajugbaja onisowo to si ni ọpọ ileeṣẹ sọ pe nkan ti Naijria nilo lasiko yi ni pipese iṣẹ lati le jẹ ki ọrọ aje burẹkẹ si.

Aworan Atiku Abubakar

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Asiko yi kọ lo yẹ ki ijọba fofin de karakata ti yoo maa jẹ ki owo wọle si ẹka ọrọ aje wa ni ohun ti Atiku sọ.

O ṣalaye pe ''o ṣeeṣe ki ijọba mojuto cryptocurrency yi ati bi owo ti se n wọle si Naijiria lai se akoba fun aabo orileede wa.Eyi ṣuwọn ju ki wọn ti i pa lọ''

O tẹsiwaju pe ''awọn ọdọ Naijiria n koju inira airiṣe nitori naa o y ki ijọba pese iṣẹ lati le jẹ ki ẹka ọrọ aje gbooro si''

Ki lawọn ọmọ Naijira miran n sọ?

Ẹwẹ awọn ọmọ Naijiria mii ti n da si ọrọ yi.

Ninu wọn ni arakunrin Osasu Obayiuwana to sọ pe aini igbagbọ ninu eto ọrọ aje banki apapọ Naijiri lo mu kawọn eeyan ya sidi Cryptocurrency.

Aworan oro oju opo ayelujara

Oríṣun àwòrán, Twitter

Mo ṣẹṣẹ nronulati ṣowo Crypto ma ni-Davido

Gbajugbaja olorin takasufe Naijiria Davido naa da si ọrọ yi.

Loju opo rẹ ni Twitter, OBO ni oun ṣẹṣẹ n gbero lati darapọ mọ owo crypto ni ki ikede ijọba apapọ yi to jade.

Ọrọ yi gẹgẹ bi o ṣe sọ fun awọn eeyan miliọnu mẹjọ to n tẹle loju opo rẹ jẹ iyalẹnu

Aworan oro oju opo ayelujara

Oríṣun àwòrán, @Davido

Awọn mii to tun sọrọ ati ohun ti wọn wi ree:

Aworan oro oju opo ayelujara

Oríṣun àwòrán, @obyezeks

Aworan oro oju opo ayelujara

Oríṣun àwòrán, @segalink

Wo ìdí tí ìjọba Buhari fi ti àkáúǹtì àwọn tó ń ṣe kátà kárà owó ''cryptocurrency'' pa

Gbogbo ẹyin to n ṣe kata kara owo ''cryptocurrency'' ni Naijiria, ẹ jawọ nbẹ tori o lodi sofin orilẹede yii.

Banki apapọ ni Naijiria CBN ti paṣẹ fun gbogbo ile ifowopamọ lorilẹede Najiria lati gbe apo ikowosi awọn eeyan to ba n ṣe kata kara owo 'cryptocurrency'' ti pa.

Koda CBN paṣẹ fawṣon ile ifowopamọ lati ṣe awari gbogbo awọn onibara wọn to ni apo ikowosi fun owo ''crypo'' ki wọn si ti wọn pa lẹsẹ kẹsẹ.

CBN ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita ti ọga ẹka to n ṣe amojuto ni banki naa, Bello Hassan buwọlu pe kilọ fawọn ile ifowopamọ ni Naijiria ewu to wa ninu kiko owo ''crypo'' si banki wọn.

Banki CBN sọ ninu atẹjade ọhun pe ile ifowopamọ kankan ko gbọdọ ni ohun kohun ṣe pẹlu kata kara mọ bayii.

Banki CBN sọ ninu atẹjade ọhun pe ẹnikẹni to ba tapa si ikede yii yoo foju win ofin.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Àkọlé fídíò, Big breast: Oluwatosin Adegboro, Oluwaseun Amoo, Remi Fatolu: Ẹlòmíì ń fi irú ọyàn wa tọrọ

Ẹwẹ, ọgọọrọ ọmọ Naijiria lo ti bu ẹnu atẹ lu igbesẹ banki apapọ Najiria.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Awọn ilumọọka lori ayelujara bii Shehu Sani, Reno Omokri, Ben Murray-Bruce, Omoyele Sowore, Debo Macaroni, DJ Switch ati awọn mii lo koro oju si igbesẹ ijọba.

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Skip X post, 4

End of X post, 4

Skip X post, 5

End of X post, 5