Ayede Polytechnic, Oyo: Soun Ogbomọṣọ àti Sunday Dare gbóríyìn fún Buhari lórí 'Polytechnic' Ayede

Soun

Oríṣun àwòrán, @Soun

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Lẹyin ti Aarẹ buhari ti kede agbekale ileẹkọ Gbogboniṣe tuntun si Ayede ni ipinlẹ Oyo ni Soun ti n gboriyin fun un.

Soun ti ile Ogbomoso, Oba Oladunni Oyewumi Ajagungbade III ti ki Buhari ku ifọmọniyan ṣe lori ileẹkọ tuntun to kede pe ki wọn wa da silẹ ni ipinlẹ Oyo.

Ileẹkọ naa ni wọn pe ni Federal Polytechnic Ayede, Ogbomoso.

O ni igbesẹ ijọba Buhari yii dara fun ẹkun naa lasiko yii.

Bakan naa ni minista fun ọrọ awọn ọdọ ati ere idaraya, Ogbeni Sunday Dare naa ki aarẹ Buhari pe o ṣeun fun idasilẹ ilẹ ẹkọ tuntun naa.

O ni ileẹkọ naa ti yoo wa ni Ayede ni ijọba ibilẹ Ogo Oluwa ni Ogbomọṣo ni ipinlẹ Oyo yoo jẹ imuṣẹ ala ninu ẹkun naa.

O mẹnuba awọn anfani boo ipese iṣẹ, ilọsiwaju ati idagbasoke ilu ti yoo dide lara agbekalẹ naa.

dare
Buhari

Oríṣun àwòrán, @MBuhari

Kini o kọkọ ṣẹlẹ?

Èrò àwọn eèyàn ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí iléẹ̀kọ́ Gbogbonìṣe tuntun tí Buhari ní kí wọ́n dá sílẹ̀ ní Oyo

Èrò àwọn eèyàn ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí iléẹ̀kọ́ Gbogbonìṣe tí Buhari ní kí wọ́n dá sílẹ̀ ní Oyo

Ìjọba àpapọ̀ ti fọwọ́ si ìdásílẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ Gbogbonìse tuntun nílùú Oyo.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Asa Ondo: Wo ìdí tí Yorùbá ṣe ń lo Ìjàpá ni olú ẹ̀dá ìtàn Àlọ́ Àpagbé- Oyelo

Ààrẹ Muhammadu Buhari náà tún buwọ́lu bílíọ̀nù meji náírà láti bẹ̀rẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ náà.

Ìjọba àpapọ̀ ti buwọ́lu ilé ẹ̀kọ́ gbogbonìse si ìjọba ìbílẹ̀ Ayede, Ogo- Oluwa nípìnlẹ̀ Oyo.

Ìbuwọ́lù náà jẹyọ nínú lẹ́tà kan ti akọ̀wé àgbà ilé iṣẹ́ tó n rí sí ètò ẹ̀kọ́ Sonny Echono fọwọ́ sí to fi sọwọ́ si gómìnà Seyi Makinde

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Bákan náà ló ṣàlàyé pe ààrẹ Buhari fọwọ́ si bílíọ̀nù meji naira ti wọ́n yoo lò láti bẹ̀rẹ̀ isẹ́ nílé ẹ̀kọ́ gbogbonìse náà.

'' Mò ń kọ lẹ́tà yii láti mu wá sí etíìgbọ́ pé ààrẹ Muhammadu Buhari GCFR, ti buwọ́lu ìdásílẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ gbogbonìse ìjọba àpapọ̀ sí ìjọba ìbílẹ̀ Ayede, Ògo-Olúwa nípìnlẹ̀ Oyo"

O ni: "Ààrẹ tún se àgbékalẹ̀ bílíọ̀nù méjì náírà láti bẹ̀rẹ̀ ètò náà lati inú owó ìrànwọ́ TETFund, èyí ni lati fi bẹ̀rẹ̀ àwọn ǹkan ti wọn yóò nílò nílé ẹ̀kọ́ ọ̀hún."

"Nítorí ìdí èyí, àwọn ìgbìmọ̀ amúṣẹ́se láti ilé iṣẹ́ eto ẹ̀kọ́ l'Abuja (NBTE) yóò sàbẹ̀wò si Ayede, Ogo-Oluwa láìpẹ́ láti wo ipò ti ǹkan wà kí eto ẹ̀kọ́ ba le gbéra sọ nínú oṣù kẹwàá ọdún 2021."

Bákan náà ni olùrànlọ́wọ́ pàtàkì fún ààrẹ lórí ìròyìn ìgbàlódé Bashir Ahmed náà fi ọ̀rọ̀ Ìbuwọ́lù naa múlẹ̀ lójú òpó Twitter rẹ̀.

Ni kete ti iroyin yii jade ni awọn ọmọ Naijiria ti n fi ero wọn han lori ayelujara

Bi awọn kan ṣe n sọ pe o dara ni awọn miran ni o ku diẹ kaato

ileẹkọ

Koda, awọn eeyan miran ni ọrọ Gomina Seyi Makinde ṣẹṣẹ ye awọn ni bayii.

won ni bo ṣe sẹ lori ọrọ Sunday Igboho ati awọn Fulani ṣẹṣẹ han de ni.

ileẹkọ

Awọn miran tun bu ẹnu atẹ lu ọna iṣejọba Naijiria labẹ akoso aarẹ Buhari lasiko yii.

ileẹkọ

Bẹẹ naa ni awọn miran ni awọn ti ṣe ẹnu awọn ni Gbolagun nitori pe ọrọ ko ṣee sọ ni fitila lasiko ijọba Buhari yii ti awọn miran si n soju abẹ nikoo.

ileẹkọ

Koko ti awọn miran n pariwo ni pe ki Aare Buhari ba awọn ara ilu sọrọ ni kii ṣe ki awọn olubadamọran rẹ ṣe ikede lori ayelujara fun ara ilu.

Wọn ni kii ṣe ori ayelujara ni awọn ti dibo fun aarẹ Buhari rara.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho; Seriki Igangan ní kò sí ẹni tó ran àwọn lọ́wọ́ látí ìgbà ìṣẹ̀lẹ̀ Ibarapa