Seyi Makinde: 'Ẹ yé bú Seyi Makinde, owó rẹ̀ ló fí ra Ọkọ bọ̀gìní fún Alhaja Abosede Adedibu, Taye Currency, Mutiat Ladoja'

Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Twitter/Seyi Makinde

Ijọba ipìnlẹ Ọyọ ti ni ko si otitọ ninu iroyin to n ja nilẹ ranyin pe owo ijọba ni Seyi Makinde fi ra ọkọ bọgini fun awọn ololufẹ rẹ.

Iroyin kan lo jade pe awọn eekan kan ni ẹgbẹ oṣelu PDP ti bẹrẹ si ni fi apa janu lẹyin ti Seyi Makinde ra ọkọ fun awọn ololufẹ ari alatilẹyin rẹ ninu ẹgbẹ oṣelu PDP ati awọn ọmọ ile Igbimọ Aṣofin ipinlẹ kọọkan.

Gẹgẹ bi iroyin naa ṣe sọ, lara awọn ti gomina fi ọkọ bọgini da lọla ni Alhaja Abosede Adedibu to jẹ iyawo gbajugbaja oloṣelu ni ipinlẹ Oyo, oloogbe Lamidi Adedibu.

Bakan naa ni o fun olorin Fuji, Taye Currency ni ọkọ naa ati Mutiat Ladoja to jẹ iyawo gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹri, Rasheed Adewolu Ladoja.

Amọ, agbẹnusọ fun gomina ipinlẹ Oyo, Taiwo Adisa ni ko si otitọ kankan ninu ẹsun ti awọn oniroyin ẹlẹjẹ fikan gomina Seyi Makinde nitori owo ara rẹ lo fi ra ọkọ fun awọn ololufẹ rẹ.

Àkọlé fídíò, Big breast: Oluwatosin Adegboro, Oluwaseun Amoo, Remi Fatolu: Ẹlòmíì ń fi irú ọyàn wa tọrọ

Taiwo Adisa ni: ''Gomina Seyi Makinde ko fi owo ijọba ra ọkọ fun ẹnikẹni, bẹẹ si ni ko ya owo lati ra ọkọ fun awọn ololufẹ rẹ''

''Owo ara rẹ lo fi ṣe oore fun awọn ololufẹ rẹ nitori nkan ti eniyan ba ni lo fi n ṣe alejo.''

Àkọlé fídíò, Tolulope Adeleke Aire: Mo wòye pé àwọn ọkùnrin Nàìjíríà kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa ìtọ́jú ọmọ tu

''Bẹẹ si ni ẹ̀ni ti ko ba kan loni, o le e kan ni ọla.''

Oni kọ ni gomina ti n fun awọn eniyan ni ọwọ iranwọ ẹkọ ọfẹ ati ọkọ bogini lọdọọdun fun awọn ololufẹ rẹ.''

Bakan naa ni ijọba ipinlẹ Oyo wa rọ awọn eniyan lati ma a wadii ohun gbogbo daju daju, ki wọn to ma a gbe iroyin ẹlẹjẹ fun awọn eniyan.