Fulani herders: Ṣé lóòtọ́ọ́ láwọn Fulani tún ṣá aráàlú Igangan méjì ládàá nínú ilé wọn?

Awọn Fulani darandaran

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iroyin to tẹ wa lọwọ lati ilu Igangan lagbegbe Ibarapa nipinlẹ Oyo sọ pe awọn afurasi Fulani darandaran ṣa Ọgbẹni Adekola Adeyemo, ẹni ọdun marunlelọgọta lori.

Bakan naa ni a tun gbọ pe awọn Fulani ọhun tun ṣa Jamiu Saedu, ẹni ọgbọn ọdun ladaa lori.

Iroyin sọ pe awọn mejeeji n sun lọwọ ninu ile wọn nigba ti awọn Fulani ọhun lọ kawọn mọle.

Eekan ilu Igangan kan, ọgbẹni Taiwo Adeagbo sọ fawọn akọroyin pe awọn eeyan mejeeji ti n wa nile iwosan nibi ti wọn ti n gba itọju bayii.

Ọgbẹni Adeagbo fikun ọrọ rẹ pe ẹjọ naa ti de ọdọ awọn ọlọpaa fun iwadii.

Ẹwẹ, awọn araalu ilu Kajola ati Gbagba ni ijọba ibilẹ Ayete lagbegbe Ibarapa nipinlẹ Oyo ni a gbọ pe wọn ti fi ilu wọn silẹ bayii.

Awọn araalu ọhun sọ fawọn akọroyin pe Fulani kan ti orukọ rẹ n jẹ, Iskilu Wakil lawọn sọ fun pe ko fi ori ilẹ to wa silẹ nitori ko ra ilẹ naa lọwọ ẹnikan kan.

Eleyi ni iroyin sọ pe o bi Wakil ninu ti o si bẹrẹ si ni leri pe oun ni oriṣiiriṣii ija oloro lakata oun.

Àkọlé fídíò, Lawal Ayankemi Oluwatoyin: Mo kọ̀ láti máa tọrọ owó nítorí ojú mi tó fọ́, iṣẹ́ ló wù mí

Asawo ti Ayete, Oba Emmanuel Okeniyi ṣalaye pe ọpọ awọn agbẹ lo ki fi oko wọn silẹ lọ lori ẹru pe Wakil le wa ṣe wọn ni ijamba.

Oba Okeniyi sọ pe lootọọ ni Gomina Seyi Makinde ipinlẹ ti ran awọn ẹṣẹ Amotekun wa si Ayete, ṣugbọn o ni awọn ẹṣọ naa ko tii lọ sawọn ilu to wa ni Ayete.

Ẹnikan to ko fẹ ki a darukọ rẹ ṣalaye pe niṣe ni Wakil atawọn ọmọọṣẹ rẹ lọ di ọna to lọ si awọn ilu meji yii to si sọ pe oun ṣetan lati yinbọn fun araalu to ba sun mọ ibẹ.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo, Olugbenga Fadeyi ṣalaye fun BBC Yoruba pe awọn agbofinro ti wa kaakiri agbegbe Ibarapa lati ri pe ko si ẹni to ṣe nkan to tapa si ofin.

Ọgbẹni Fadeyi ni ko si ewu fawọn araalu to wa lagbegbe Ibarapa.

Bakan naa lo sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ awọn afursai Fulani ti wọn ni wọn ṣa awọn araalu ilu ladaa.

Àkọlé fídíò, Pangolin Covid-19: Ẹ wo ẹranko tó ṣeéṣe kó ní ǹkan ṣe pẹ̀lú à[rùn Coronavirus!