Sunday Igboho Ogun trip vs Fulani: Mó wá sí ìpínlẹ̀ Ogun láti lé àwọn Fulani ajínigbé dànù lórí ilẹ̀ Yorùbá

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: 'Ǹkan tÍ Sunday Igboho Ṣe ní Ibarapa tún ti ṣelẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ogun'
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Adari egbe Miyetti Allah ni ile Yoruba, Muhammed Kabir Labar ni nkan tÍ Sunday Igboho Ṣe ní Ibarapa tún ti ṣelẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ogun

Kabir Labar lo so bee fun BBC Yoruba.

Labar fẹsun kan Sunday Igboho pe bi o ṣe ṣẹlẹ lẹyin ti o kuro ni Igangan naa tun ti ṣẹlẹ ní Ogun.

Wọn dana sun ile Seriki ni agbegbe Ijọba ibilẹ Igbowa, ni ipinlẹ Ogun.

Sunday Igboho l'Ogun

Oríṣun àwòrán, Facebook/Africa Eyes

Ìjọba ìpínlẹ̀ Ogun kọ́ ló pé Sunday Igboho, ó kàn wá fúnra rẹ ni- Kọ̀míṣọ̀nná Ogun

Kọsmiṣọnna fun ifitonileti ni ipinlẹ Ogun, Abdulwaheed Odusile ti ni ki awọn eeyan mẹnu kuro lori koko pe Gomina Dapo Abiodun lo ranse pe Suinday Igboho.

Odusile fi atẹjade naa sita ni Abeokuta to jẹ olu ilu ipinle Ogun lẹyin ti Sunday Adeyemi wa si ipinlẹ Ogun wa kilọ iwa buruku fawon Fulani ajinigbe.

Kọmiṣọnna salaye ohun to ṣẹlẹ pe, Remi Hazzan to jẹ olubadamọran fun gomina Dapo Abiodun lori ibaraenisoro ni awọn kan dori ọrọ rẹ kodo.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Asa Ondo: Wo ìdí tí Yorùbá ṣe ń lo Ìjàpá ni olú ẹ̀dá ìtàn Àlọ́ Àpagbé- Oyelo

O ni wọn yi ọrọ Hazzan ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe ṣaaju ki Sunday Adeyemo ti ọpọ n pe ni Sunday Igboho to wa si Yewa nirọlẹ ana.

Odusilẹ ni nitootọ ni Hazzan ni ijọba Dapọ Abiodun yoo fọwọsopọ pẹlu awọn ti ọrọ kan ninu ile ati ni ia lati rii pe eto aabo wa fun awọn eniyan ipinlẹ Ogun ṣugbọn ko darukọ pe Sunday Igboho ni wọn n ranṣẹ pe.

O ni rioyin pe ijọba ranṣẹ pe Oloye sunday Igboho lati wa daabo bo awọn eeyan ipinlẹ Ogun jẹ irọ.

Odusilẹ ni ijọba gomina Dapo Abiodun n ko gbogbo eeyan mọra, ko dẹyẹ si ẹnikẹni ati pe ko si ẹni ti ko le fọwọsowọpọ pẹlu fun idagbasoke ati eto aabo ipinlẹ Ogun.

Sunday Igboho l'Ogun

Oríṣun àwòrán, Facebook/Africa Eyes

Ki lo ti kọkọ ṣẹlẹ sẹyin?

Mó wá sí ìpínlẹ̀ Ogun láti lé àwọn Fulani ajínigbé dànù lórí ilẹ̀ Yorùbá- Sunday Igboho

Iroyin to tẹ wa lọwọ lati ipinlẹ Ogun sọ pe gbajugbaja ajijagbara ilẹ Yoruba, Sunday Adeyemo ti ọpọ mọ si Sunday Igboho ti gunlẹ si ipinlẹ Ogun lati kọju ija sawọn janduku Fulani to n huwa ọdaran nibẹ.

Ohun iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe aarọ ọjọ Aje, ọjọ kinini, oṣu keji ni Igboho fi ilu Ibadan silẹ lọ si ipinlẹ Ogun.

Àkọlé fídíò, Tolulope Adeleke Aire: Mo wòye pé àwọn ọkùnrin Nàìjíríà kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa ìtọ́jú ọmọ tu

''A o ba awọn agbaagba ni Yewa ṣe ipade pọ, a si ti wa ni ilẹ Yewa bayii,'' Ọgbẹni Akinpelu ṣalaye.

Fidio kan lori ayelujara ṣe afihan Igboho fun ra rẹ nibi to ti n ba awọn ọmọ ipinlẹ sọrọ ni Ilu Ọja Ọdan.

''Ipinlẹ Ogun ni mo wa bayii, mo wa gba awọn ọmọ Yoruba silẹ lọwọ awọn Fulani ajinigbe, awọn Fulani to fi ipa bawọn obinrin lopọ,'' Igboho sọrọ soke.

Igboho tun ni ''a ko fẹ Fulani ajinigbe mọ lori ilẹ baba wa, o to gẹẹ bayii.''

''O ya ẹ jẹ ki a wọ inu igbo Idua lọ bayii lati lọ pade awọn Fulani to n ji awọn Yoruba gbe.

Ọkan lara awọn ọmọlẹyin Igboho, Ọgbẹni Sina Akinpẹlu to ba BBC Yoruba sọrọ ṣalaye pe Igboho atawọn ọmọlẹyin rẹ gbera lọ si ipinlẹ lati kilọ fawọn Fulani lati so ewe agbejẹ mọwọ bi bẹẹ kọ, wọn o jẹ iyan wọn niṣu.

Ọgbẹni Akinpelu ṣalaye pe ko si ẹni to ranṣẹ pe Igboho atawọn ọmọlẹyin ni pato,

O ni Igboho atawọn to kọwọ rin pẹlu rẹ fi ọrọ naa to awọn lọbalọba leti pe awọn n bọ wa si ipinlẹ Ogun.

Àkọlé fídíò, Big breast: Oluwatosin Adegboro, Oluwaseun Amoo, Remi Fatolu: Ẹlòmíì ń fi irú ọyàn wa tọrọ

''A o ba awọn agbaagba ni Yewa ṣe ipade pọ, a si ti wa ni ilẹ Yewa bayii,'' Ọgbẹni Akinpelu ṣalaye.

Akinpelu sọ pe awọn yoo ranṣẹ si awọn Fulani to wa ni Yewa pe lati kilọ fun wọn pe wọn o gbọdọ na ọba alade kankan tabi fiya jẹ ọmọ Yoruba mọ, lai jẹ bẹ, wọn gbọdọ ko ẹru wọn ki wọn si ipinlẹ Ogun silẹ.

Sunday Igboho l'Ogun

Oríṣun àwòrán, Facebook/Africa Eyes

''A o mọ iye ọjọ ti a maa lo ni Yewa lori ọrọ awọn Fulani yii, gbogbo awọn ọmọ Yoruba to nifẹ si ohun ti a n ṣe lo wa lẹyin wa,'' Ọgbẹni Akinpẹlu lo sọ bẹẹ.

Skip Facebook post

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post

Akinpelu fikun ọrọ rẹ pe awọn ranṣẹ si Gomina Abiodun wi pe awọn n bọ ṣugbọn gomina ko tii fesi.

''Amọ, a ko le duro ki gomina fesi kawọn ti wọn yoo fi pa awọn eeyan wa tan,'' Akinpelu ṣalaye.

Sunday Igboho l'Ogun

Oríṣun àwòrán, Facebook/Africa Eyes

Ṣaaju akoko yii ni oludamọran pataki fun Gomina Abiodun ipinlẹ Ogun, Remmy Hazzan sọ pe ẹnikẹni to ba le ṣe iranwọ lori eto abo to mẹhẹ l'Ogun, ijọba yoo gbaruku tii.

Hazzan ni kii ṣe Igboho nikan, ẹnikẹni to ba le wa ojutu si ipenija ti ipinlẹ Ogun ni lori eto abo ni ijọba yoo ṣe atilẹyin fun un.

Sunday Igboho l'Ogun

Oríṣun àwòrán, Facebook/Africa Eyes

Laipẹ yii ni iroyin kan gbori ayelujara pa pe awọn olugbe agbegbe ijọba ibilẹ ariwa Yewa ke gbajare pe awọn sọja to tẹle awọn Fulani darandaran kan to ko ẹran jẹ oko ni Yewa fiya jẹ awọn.