NIN registration: Ìjọba Nàìjíríà ti sún ọjọ́ ìforúkọsílẹ káàdi ìbánisọ̀rọ̀ síwájú síi

Nin

Oríṣun àwòrán, others

Ijọba Naijiria ti kede laarọ oni ọjọ Iṣẹgun, ọjọ keji, oṣu keji, ọdun 2021 pe wọn ti fi kun asiko iforukọsilẹ ti wọn kede tẹlẹ.

Eto iforukọsilẹ yii ni lati ni idanimọ gbogbo awọn to n lo kaadi ipe ori foonu ni Naijiria.

Ọsẹ mẹjọ ni ijọba Naijiria fi kun gbendeke naa ki op le tubọ rọrun sii fawọn eniyan Naijiria lati le forukọsilẹ paapaa lasiko ajakalẹ arun coronavirus yii.

Saaju ni ijọba ti kede ọjọ kesan an, oṣu keji tẹlẹ ki wọn to sun un di oṣu kẹrin bayii.

Oludari ẹka gbogboogbo ni ileeṣẹ ijọba to n mojuto eto iforukọsilẹ naa Nigerian Communications Commission, Ikechukwu Adinde, lo fi ọrọ naa sita.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Asa Ondo: Wo ìdí tí Yorùbá ṣe ń lo Ìjàpá ni olú ẹ̀dá ìtàn Àlọ́ Àpagbé- Oyelo

Adinde ṣalaye pe o di dandan ki wọn fi asiko kun igba iforukọsilẹ naa nitori pe awọn eeyan n kun lori ero to pọ nibudo iforukọsilẹ ati awọn kudiẹ kudiẹ mii to nilo asiko sii lati yanju ni irọrun fun awọn oluforukọsilẹ.

Àkọlé fídíò, Big breast: Oluwatosin Adegboro, Oluwaseun Amoo, Remi Fatolu: Ẹlòmíì ń fi irú ọyàn wa tọrọ

Isa Patami to jẹ minista ileeṣẹ ijọba apapọ lori ona ibaraẹnisọrọ naa ṣalaye nipa bo ṣe ṣe pataki lati fi kun asiko naa.

Patami sọ eyi di mimọ lasiko to n ṣe ipade pẹlu ikọ to n mojuto ọrọ itankalẹ ajakalẹ arun Coronavirus lọjọ kinni, oṣu yii.