NIN Registration: Mínísítà ní bó yá n'ìjọba kò ní dá ìforúkọsílẹ NIN dúró tórí ewu Covid-19

Oríṣun àwòrán, NIMC
Minisita keji fun eto ilera ni Naijiria, Dokita Olorunnimbe Mamora ti sọ pe o ṣeeṣe ki ijọba so iforukọsilẹ kaadi idanimọ NIN rọ nitori ewu coronavirus.O ni ewu kiko coronavirus wa ninu bi ọpọ eeyan ṣe n to si ibudo iforukọsilẹ kaadi kaakiri Naijiria.Dokita Mamora rọ ajọ NIMC lati ronu ọna miiran ti wọn fi le maa ṣe iforukọsilẹ fawọn eeyan lọna ti ero ko fi ni maa pọ to bi wọn ṣe n pọ bayii.
- Ìlú tuntun tó kún fún ohun àdáyébá láìsí ọkọ̀ tàbí òpópónà ń bọ̀ ní Saudi Arabia
- Lẹ́yìn ọgọ́rùn ún ọjọ́ tí wọn ti Lekki Toll Gate pa, ẹ wo owó gọbọi tíjọba Eko ń pàdánù
- Àwọn olorì Aláàfin fi oríkì awúnilórí yẹ́ ọkọ wọn sí fún àádọ́ta ọdún tó gorí ìtẹ́
- Agbẹjọ́rò àgbà ní Nàìjíríà ti pàsẹ kí wọ́n dáwọ́ ètò ìgbanisíṣẹ́ NDLEA dúró
Mamora to jẹ ọkan lara ọmọ igbimọ amuṣẹya PTF to n ri si ati dẹkun coronavirus ni Naijiria ṣalaye pe ojuṣe ijọba ni lati daabo bo ọmọ Naijiria ni gbogbo igba."Inu mi ko dun si bi ero ṣe n pọ lawọn ibudo iforukọsilẹ fun NIN, o dabi ọna ti arun le gba maa ran bi ina inu ọyẹ, eleyi ti a ko fẹ ko ṣẹlẹ," Dokita Mamora lo woye bẹẹ.Amọ, o fikun ọrọ rẹ pe ileeṣẹ ijọba to n ri si eto ibaraẹnisọrọ to n ṣagbatẹru eto kaadi idanimọ NIN naa ti n ro ọna mii ti wọn le gbe ọrọ naa gba ti ko fi ni da ajakalẹ arun silẹ.Ijọba apapọ lo paṣẹ fawọn ileeṣẹ ẹrọ ibaraẹnisọrọ lati ja awọn onibara wọn ti ko ba ni kaadi idanimọ NIN kuro loju opo wọn.Ọjọ kẹsan an oṣu keji ọdun 2021 yii ni ijọba fawọn eeyan da lati so kaadi idanimọ NIN wọn pọ mọ nọmba ẹrọ ibanisọrọ wọn.
NIMC Mobile App: Wo bí o ṣe lè gba nọ́mbà NIN rẹ tàbí so ó pọ̀ mọ nọ́mbà fóònù rẹ lórí App tí NIMC ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe

Oríṣun àwòrán, Nimc
Awọn ọmọ Naijiria ti le lo ẹ̀rọ ibanisọrọ alagbeka wọn bayii lati gba nọ́mbà idanimọ NIN, lai ṣẹṣẹ ma a to.
Ajọ to n mojuto eto naa, National Identity Management Commission, NIMC ti ṣe 'App' kan ti yoo fun wọn ni anfaani lati gba kaadi idanimọ NIN, tabi fi rọpo kaadi naa.
Wo ilana lati lo 'App' naa
- O le gba app naa sori ẹ̀rọ ibanisọrọ rẹ lati Google play store to ba jẹ pe foonu Android lo n lo, tabi Apple App store to ba n lo IPhone.
- Lẹyin ti o ba ti danloodu rẹ tan, lọ si ọwọ isalẹ rẹ̀, ki o tẹ 'Skip', lẹyin naa, tẹ 'Begin'.
- Tẹ nọ́mbà mọkanla to jẹ NIN rẹ, ki o si tẹ 'Next', lẹyin naa tẹ 'I Agree'.
- Nọ́mbà ẹ̀rọ ibanisọrọ ti o fi ṣe akọsilẹ NIN rẹ yoo jade pẹlu ibeere meji pe:
- Mo ṣi n lo nọ́mbà yii
- Mi o lo nọ́mbà yii mọ
- Tẹ eyi to ba jẹ ninu mejeeji, ki o si tun tẹ 'Next'.
- To ba jẹ pe o ṣi n lo nọ́mbà naa, tẹ àwọn nọ́mbà 'User ID' ati 'OTP' ti NIMC ba fi ṣe atẹranṣẹ si ori nọ́mbà naa lasiko yii, ki o si tẹ 'Proceed'.
- O tun le ṣe akọsilẹ àwọn nọ́mbà mii ti o ba n lo nibẹ.
- Àmọ́, to ba jẹ pe o ko lo nọ́mbà naa mọ, o nilo lati lọ si ọfiisi ajọ NIMC lati ṣe akọsilẹ nọ́mbà tuntun, ki o to le tẹsiwaju.
Sugbọn ṣa, ajọ naa tun ti kede pe o nilo lati san owo fun àwọn ayipada kan nipa akọsilẹ rẹ lori kaadi NIN, botilẹjẹ pe ọ̀fẹ́ ni gbigba nọ́mbà NIN.
Oludari kan ninu ajọ naa, Funmi Opesanwo sọ pe oriṣiriṣi eto ayipada tabi atunse ni ajọ naa ma n ṣe, sugbọn kii ṣe ọ̀fẹ́.
Lati ṣe atunse si akọsilẹ nipa ọjọ ìbí rẹ, ẹgbẹrun mẹẹdogun Naira ni wa a san.
Lati paarọ adirẹsi rẹ, ẹẹdẹgbẹta Naira ni.
To ba jẹ pe o fẹ ẹ gba kaadi miran ni, ẹgbẹrun márùn-ún lo ba de.

















