The Line: Saudi Arabia ní ìlú tuntun náà yóò gba olùgbé 1m, pèsè ìṣẹ́ 380,000

Saudi Arabia

Ọmọ ọba Saudi Arabia, Mohammed bin Salman ti kede erongba ijọba ilẹ naa, lati kọ ilu tuntun kan ti ko ní ní opopona tabi ọkọ.

Ilu tuntun naa, ti iwọn rẹ yoo jẹ kilomita mẹrindinlọgọsan jẹ ọkan lara iṣẹ akanṣe "The Line," eyii ti wọn pe ni "Neom."

Nigba to n sọrọ lori ẹrọ amohunmaworan kan, Mohammed ni iṣẹ ọhun yoo bẹrẹ ni abala kinni ọdun 2021.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ninu atẹjade kan, o ni "ilu tuntun ọhun yoo jẹ eyi ti ko ni si ọkọ ayọkẹlẹ tabi opopona, ṣugbọn yoo jẹ eyi ti yoo da lori awọn ohun iṣẹda ati adayeba.

saudi

Oríṣun àwòrán, @Nawaftayyar

Atẹjade naa tẹsiwaju pe, ilu ọhun yoo ni aye ti yoo gba awọn olugbe miliọnu kan, bẹẹ ni yoo pese iṣẹ to to ẹgbẹrun lọna orinlelọọdunrun ko to di ọdun 2030.

Iṣẹ akanṣẹ Neom jẹ ọkan lara afojusun Mohammed, lati wa ọna miran ti orilẹ-ede Saudi Arabia fi le pa owo wọle, yatọ si owo epo rọbi.

Nigba to n ṣalaye lori idi ti wọn ṣe fẹ gbe ilu naa kalẹ, Mohammed sọ pe nnkan bii biliọnu kan eeyan ni yoo di alairilegbe nitori eefin to n ti ara ọkọ jade.

Ati pe nnkan bi miliọnu meje eeyan lo n ku nitori ijamba ọkọ oju popo, nitori naa ni agbekalẹ ilu ọhun fi ṣe pataki.

Àkọlé fídíò, Nigeria Car Innovator: Olatunde Ibitoye ní ọdún mẹ́ta ní òun fi ṣe ọkọ̀ náà torí ọ̀dá owó

Ṣaaju ni awọn onimọ kan ti kọkọ sọ pe, ala ti ko le ṣẹ ni ilu tuntun naa jẹ, ṣugbọn ijọba ilẹ ọhun ti fesi pe, oun yoo pese lara owo ti wọn yoo fi kọ ilu naa, ti awọn ileeṣẹ aladani ni Saudi ati kaakiri agbaye, yoo lọwọ si.

Ọmọ Ọba Saudi pari ọrọ rẹ pe, ilu ọhun yoo ni ile iwe, ile iwosan, awọn ọgba to dun wo loju atawọn ohun amayedẹrun miran, bẹẹ ni irinajo ninu rẹ ko ni kọja ogun iṣẹju pere lọ.