Orisabunmi: Èyí ni àlàyé lórí àsìkò ìkẹyìn olóògbé Orisabunmi àti ohun tó paá gan láti ẹnu Baba Ijesa

orisabunmi nibudo sinmi yiya kan

Oríṣun àwòrán, Instagram/themakingstv

Kii ṣe iroyin mọ bayii pe gbajugbaja oṣere tiata ati sinima Yoruba, Iyaafin Fọlakẹ Arẹmu ti ọpọlọpọ eeyan mọ si Oriṣabunmi ti jade laye, amọṣa ohun ti o n ṣe ọpọlọpọ eeyan, paapaajulọ awọn ololufẹ wọn ni kayefi ni irufẹ iku to pa wọn.

Eyi ko ṣa dede ri bẹ bikoṣe nitoripe ko si eeyan to gbọ iroyin aarẹ kankan nipa eekan oṣere naa ki ọlọjọ to de.

Amọṣa ninu fidio kan to fi si ori ikanni ayelujara, Facebook, eekan apanilẹrin ati elere itage, Ọlanrewaju Omiyinka ti ọpọ mọ si Baba Ijeṣa jẹ ko di mimọ pe "ikọ lasan" lo pa oloogbe Oriṣabunmi.

Baba Ijẹṣa ṣalaye pe ko si idi fun oloogbe naa lati ku kani awọn ohun elo irapada ẹmi gbogbo to yẹ ba wa lawọn ileewosan lorilẹede Naijiria ni.

Baba ijẹṣa ṣalaye pe ohun to n ba awọn oṣere ninu jẹ pups julọ ni pe ijọba orilẹede Naijiria ko ṣai maa ja araalu to dibo fun wọn kulẹ.

Bakan naa lo fi idi rẹ mulẹ pe ọjọ Iṣẹgun, ọjọ karun un oṣu kini ọdun 2021 ni Oriṣabunmi jade laye.

Bakan naa ni aarẹ ẹgbẹ awọn oṣere sinima, TAMPAN, Bọlaji Amuṣan ti ọpọ mọ si Baba Latin pẹlu fi idi eyi mulẹ ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu ileeṣẹ iroyin abẹle kan.

"Ni alẹ ana (Ojọ Iṣẹgun) ni wọn ku" Baba Latin ṣalaye.

Alaye lori asiko ikẹyin Oriṣabunmi

oriṣabunmi

Oríṣun àwòrán, Instagram/standard_presenter

Nigba to n tẹsiwaju ninu fidio naa, Baba Ijẹṣa ni ọpọlọpọ awọn oṣere ni inu wọn ko dun si bi ijọba lẹkajẹka gbogbo ṣe n ja awọn oṣere sinima kulẹ nipa aitọju wọn ati airi tiwọn ro.

Ninu ọrọ rẹ, O ni o yẹ ki Mama Oriṣabunmi, gẹgẹ bi awọn oṣere ṣe maa n pe e o wa ni ili Ilẹ Oluji fun iṣẹ sinima kan ti Lọla Adegoke ti ọpọ mọ si Mọremi agbaye fẹ ya nibẹ ni ti Mama Oriṣabunmi funra rẹ gan ti pe lati le tete mọ ọjọ ti yoo kan ipa ti o fẹ ko nibẹ.

Bakan naa lo ni Oriṣabunmi ṣẹṣẹ pari iṣẹ kan to lọ ya ni ilu Ẹdẹ ni ipinlẹ Ọṣun laipẹ yii ni pẹlu ti ko si si ohun kan to ṣe ilera rẹ.

"Ko si nnkankan to ṣe iya yii nibẹ. A jọ n ṣe awada, a jọ n jo nibẹ ni"

O ni Oriṣabunmi n wu ikọ, ko lee mi daadaa. O fi kun un pe ka ni ileewosan ti wọn gbee lọ ni ohun elo iranwọ fun eemi, o ṣeeṣe ki Oloogbe Oriṣabunmi ṣi wa laye.