Coronavirus in Lagos: Gómìnà Sanwo-Olu ní àìbìkítà ló mú kí èèyàn 712 kó COVID-19 lọ́jọ́kan ṣoṣo ní ìpínlẹ̀ Eko

Gomina Sanwo-olu n ba awọn eeyan kan sọrọ

Oríṣun àwòrán, Twitter/babajide sanwo-olu

Ijọba ipinlẹ Eko ti pariwo sita lori iwa kokanmi tawọn eeyan ipinlẹ naa nkọ si ọrọ ajakalẹ arun COVID-19 bayii.

Ninu ọrọ kan to fi sita lalẹ ọjọ Iṣẹgun, gomina Babajide Sanwo-Olu ni ko si majẹ agbọ kankan lori ootọ ọwọ keji ajakalẹ aarun naa eyi to ni o ti aarin orilẹede Naijiria ati paapaa, ipinlẹ Eko.

O fi kun un pe ni ọjọ Iṣẹgun nikan, eeyan ẹẹdẹgbẹrin o le mejila lo ko aarun naa ni ipinlẹ Eko nikan, eyi to ni ko ṣẹlẹ ri lati igba ti aarun naa ti bẹrẹ ni ọdun 2020.

O ni pẹlu eyi iye awọn to ti ko aarun naa bayii ni apapọ ti di ẹgbẹrun mejilelọgbọn ati okoolelẹẹdẹgbẹrin (32,720)

Gomina Sanwo-Olu ni kii ṣe idunnu ijọba lati gbe ofin konile o gbele miran kalẹ nitori naa o ṣe pataki fun awọn araalu lati maa tẹle ilana ati ofin gbogbo ti wọn fi lelẹ fun igbe aye lasiko COVID-19 naa.