Oyo Insecurity: Kí lo dé tí ìpànìyàn, ìjínigbé, ìdigunjalè ń peléke síi lábẹ́ Gómìnà Makinde?

Oríṣun àwòrán, Facebook/Sherifat Adisa
Eeyan mẹta lo di oloogbe ni ilu Igboọra ni ipinlẹ Ọyọ lasiko ti awọn ajinigbe ṣọṣẹ nileepo Subawah Oil filling station to wa lagbegbe opopona Idere.
Awọn ọmọ ọdun mẹsan meji ti wọn jẹ ibatan wa lara awọn ti wọn pa lasiko iṣẹlẹ naa nigba ti iroyin sọ pe iya ọkan ninu wọn naa tun fara gbọta.
Ọga agba ile epo naa, Arabinrin Sherifat Adisa wa lara awọn ti awọn ajinigbe naa ji gbe lọ si ibi ti ẹnikẹni ko mọ ki wọn to wa ri oku rẹ lẹsẹ o gbeji kan ni ọjọ Aiku.
Olugbe ilu naa kan ṣalaye fun awọn oniroyin pe awọn to faragbọta naa wa lara awọn to pẹlu arabinrin Sherifat lati sa asala fun ẹmi wọn ni alẹ ọjọ Abamẹta ti wọn ni iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.
Arabinrin to faragbọta naa ni wọn sọ pe o n bọ pẹlu awọn ọmọ meji lati ilu Igboọra wa si Idere ki ọlọkada to n gbe wọn bọ to ja wọn silẹ lẹgbẹ titi lati lee ra epo ni ile epo naa nibi ti ọta ibọn ti ba wọn.
Ileeṣẹ Ọlọpaa ti ṣalaye pe ọwọ ti tẹ awọn afurasi kan bayii nipasẹ ajọṣepọ laarin ọlọpaa atawọn ọlọdẹ adugbo nibẹ.
Bakan naa ni alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọyọ, Fadeyi Olugbenga tun jẹ ko di mimọ pe ifimufinlẹ n lọ ni kikankikan kaakiri agbegbe naa lati lee mu awọn afurasi miran ti wọn n fẹ sa mọ ofin lọwọ nibẹ.
Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa kede pe awọn ajinigbe tun ji eeyan kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Dokita Akindele lagbegbe Tapa, ni ijọba ibilẹ Ibarapa North.
Inu ileewosan rẹ ni wọn ni wọn ti jii gbe.
Lẹnu lọọlọ yi, niṣe ni iṣẹlẹ ipaniyan ati ijinigbe n peleki si ni Ipinlẹ Oyo.
Bi a ko ba gbagbe awọn agbebọn kan pa eekan ẹgbẹ oṣelu PDP Fatai Aborode nigba to n dari bọ lati oko rẹ.
Ni ọjọ kọkanla oṣu kejila ọdun 2020 ni wọn da lọna lopopona Apodun ni Igangan,gẹgẹ bi ọlọpaa ṣe wi.
Awọn afurasi mẹrin ni wọn ni wọn ṣiṣẹ yi ti awọn ọlọpaa ṣi yi n wa awọn afurasi naa di ba ti ṣe n sọrọ yi.
Laarin Tapa ati Aiyete ni Fatai Aborode ti dakẹ nigba ti wọn n gbe lọ si ile iwosan to wa ni Igboora.
Ẹwẹ ẹgbẹ alagbata epo aladani ni Naijiria ti kesi Gomina Makinde lati wa wọrọkọ fi ṣada lori iṣekupani ati ijinigbe to n gbogo ni ipinlẹ Oyo.
Ẹgbẹ naa fi ọrọ yi sita ninu atẹjade kan lọjọ Aiku lẹyin iku Alhaja Sherifat tawọn ajinigbe ṣeku pa.













