US Election: Ààrẹ Trump pe òṣìṣẹ́ ìdìbò ní Georgia pé ko 'wa'ìbò láti dojú ìbò tó gbé Biden wọlé dé

Wọn ti gba ohun aarẹ Trump torilẹede Amẹrika silẹ nigba to pe olori eto idibo kan nipinlẹ Georgia lori aago pe ko wa kun iye ibo ẹgbẹ oṣelu Republican lati yi esi ibo arẹ nibẹ pada;
"Mo fẹ wa ibo ẹgbẹrun mọkanla o le ọrinlelẹẹdẹgbẹrin" ni ọrọ ti aarẹ Donald Trump sọ fun alamojuto ọrọ ilẹ okeere ni ipinlẹ Georgia, Brad Raffensperger ninu fọnran ohun ti wọn ka silẹ kan eleyii ti ileeṣẹ iwe iroyin Washington post gbe jade.
Amọṣa, Ọgbẹni Raffensperger to pe ni ko sohun to jọọ.
Joe Biden lo gbegba oroke ni ipinlẹ Georgia atawọn ipinlẹ nlanla miran ninu ibo aarẹ to waye loṣu kọkanla ọdun 2020 lati igba naa si ni Aarẹ Trump ti n pariwo pe eru wa ninu idibo naa ṣugbọn ti ko lee mu ẹri kankan sita.
Gbogbo ipinlẹ aadọta to wa lorilẹede Amẹrika ni wọn ti fi ontẹ lu esi idibo aarẹ naa naa, awọn miran ṣe eyi lẹyin atunka esi idibo naa.
Bakan naa ni ile ẹjọ si ti ta ọgọta ipẹjọ ti Trump pe lori ibo naa nipa sita pe ko lẹsẹ nlẹ.

Oríṣun àwòrán, EPA
Ki ni ohun to ṣẹlẹ ninu ibanisọrọ ti aarẹ Trump ṣe lori foonu naa?
Ninu akọsilẹ ohun ti wọn ka silẹ naa eleyi ti ileeṣẹ iroyin Washington post gbe sita, Aarẹ Donald Trump n fi ọgbọn ko alakoso ọrọ ilẹ okeere ni ipinlẹ Georgia naa laya jẹ.
O n pariwo pe oun loun bori ibo ni ipinlẹ Georgia ati pe "ko si ohun to buru bi o ba ni ẹ tun ibo naa ka ni".
Ọgbẹni Raffensperger fun un lesi pe: "ipenija ti ẹyin gẹgẹ bi aarẹ n koju, ni peiroyin ti ẹ n gbe kiri kii ṣe ootọ rara."
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Igba to ya ni Aarẹ Trump ba tun mu ọrọ miran ys pe ahesọ ọrọ to n kaakiri ni pe awọn kan ti ya iwe idibo naa ti wọn si ti ko awọn ohun elo idibo kuro lagbegbe Fulton county, eleyi ti agbẹjọro fun Ọgbẹni Raffensperger ni ko si ootọ kankan nibẹ.
Koda aarẹ Trump gbiyanji ati fi ipẹjọ dunkoko mọ oṣiṣẹ idibo naa.

O wa pe fun afikun ibo ẹgbẹrun mọkanla o le ọrinlelẹẹdẹgbẹrinkun ibo rẹ, eleyi ti yoo fun un ni ibo miliọnu meji ati irinwo ẹgbẹrun o le mẹta le laadọrin ati ẹgbẹta oo le mẹrinlelọgbọn, 2,473,634 eyi ti yoo mu ki ibo rẹ fi ẹyọ kan le ju ti Joe Biden to ni ibo miliọnu meji ati irinwo ẹgbẹrun o le mẹta le laadọrin ati ẹgbẹta oo le mẹtalelọgbọn, 2473,633.
Ṣugbọn Ọgbẹni Raffensperger jẹ ko di mimọ fun Trump pe gba-gba-gba lawọn duro lori esi ti awọn gbe sita.












