Bola Tinubu: ''Ìròyìn òfegè lásán ni! Tinubu kò lùgbàdí coronavirus''

Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Facebook/Asiwaju Bola Tinubu

Faabada! Gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ, Aṣiwaju Bola Tinubu ti sọ pe ahesọ lawọn kan n gbe kiri pe oun ti karun coronavirus.

Ọrọ naa ti lu ori ayelujara pa pe Tinubu ti lugbadi covid-19, o si n gba itọju lọwọ nile iwosan lorilẹede Faranse loke okun.

Ṣugbọn Tinubu to gba ẹnu oluranlọwọ rẹ, Tunde Rahman sọrọ ṣalaye pe igba mẹẹdogun loun ti ṣe ayẹwo fun covid-19 eleyi to si ja si pe ṣaka lara oun da.

Ọgbẹni Rahman ni irọ funfun balau lati ọrun apaadi ni iroyin ọhun.

''Koko lara Asiwaju le, ko si ṣaisan, bẹẹ ni ko ni arun coronavirus,'' Rahman lo sọ bẹẹ.

Ọgbẹni Rahman sọ pe lootọọ ni Tinubu ko si ni Naijiria lọwọ yii, ṣugbọn o ṣalaye pe ilẹ Faranse kọ ni Asiwaju wa gẹgẹ bi iroyin kan ṣe sọ lori ayelujara.

''Ilu London ni Tinubu wa, kii ṣe orilẹede Faranse gẹgẹ iroyin ẹlẹjẹ ṣe sọ lori ayelujara,'' Ọgbgẹni Rahman ṣalaye.