Chelsea vs Manchester City: Man City gba fújà lọ́wọ́ Chelsea n'íbẹ̀rẹ̀ ọdún tuntun

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn Yoruba maa n gbadura kan wi pe ''aye ko ni gba fuja lọwọ rẹ.''
Amọ iru adura yii gan ni Chelsea nilo lasiko yii ninu idije Premier League lẹyin ti ẹgbẹ agbabọọlu Manchester City ṣe wọn bi ọṣẹ ṣe maa n ṣe oju lọjọ Aiku.
Ṣebi aileja lojude ile baba mi ko de bi. Nile ni Chelsea kuku wa ti Man City ko igbaju igbamu bo wọn bi ole to ji ike owo.
- Ṣé Pochettino lè gba ife ẹ̀yẹ UEFA Champions League tí PSG ń wá fún wọn?
- Sunday Igboho sọ̀rọ̀ lórí ohun tó kan fún ilẹ̀ Yorùbá lọ́dún 2021
- Pásítọ̀ Adeboye bú ẹnu àtẹ́ lú ìjọba tó fofin dé ìsìn ìrékọjá sí ọdún tuntun
- Àwọn ànfààní tó wà nínú ìbálọ̀pọ̀ fún ọkàn àti ara rẹ
- Bá wo ni òrékelẹ́wà Adedoja tó gbàmì ẹ̀yẹ ''Miss Oyo 2020'' ṣe jẹ́ sí Alaafin?
- Èmi gan ni mo pàdànù nípa ikú 'Chief Protocol mi' - Gomina Akeredolu
Agbabọọlu aarin gbungbun Ilkay Gundogan lo kọkọ gba goolu sawọn Chelsea fun Manchester City lẹyin isẹju mejidinlogun ti ere bọọlu ọhun bẹrẹ ni papa iṣere Stamford Bridge.
Ka to wi, ka to fọ, Phil Foden gba goolu keji wọle fun City, lo ba di ami ayo meji sodo.
Ẹlẹsẹ ayo, Kevin De Bruyne lo gba goolu kẹta sawọn fun Man City, lọrọ ba di họ fun Chelsea.
Chelsea gbiyanju lati da goolu kan pada amọ ẹpa ko boro mọ.
Ipo kẹjọ ni Man City wa bayii lori tabili idije Premier League nigba ti Liverpool si wa loke tente.
Ti ẹ ko ba gbagbe, Arsenal lo kọkọ digbaju ru Chelsea laipẹ yii pẹlu ami ayo mẹta si ẹyọkan.












