Sexual benefits: Àwọn ànfààní tó wà nínú ìbálọ̀pọ̀ fún ọkàn àti ara

Ọkunrin ati Obinrin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Igbeyawo alarede to larinrin ko tii pe lai si ibalopọ ti tọkọ taya yoo jọ gbadun nibẹ.

Ibalopọ to dun jẹ ọkan lara ohun to maa n mu ajọṣepọ to dan mọran wa laarin ọkọ ati iyawo.

Bakan naa, awọn onimọ nipa ibalopọ tun sọ pe ibalopọ maa n ran tọkọ taya lati gbaradi fun ipenija ti wọn le koju ninu igbeyawo wọn lọjọ iwaju.

Oriṣiiriṣii ọna ni lọkọ laya le gba lati rii wi pe wọn gbadun ibalopọ pẹlu ara wọn.

Ọna kan lati ṣe eyi ni igbiyanju lati jẹ ki ibalopọ gbona giri giri. Nigba mii, bi lọkọ laya ṣe n sọrọ nipa ibalopọ niṣe pẹlu bi ibalopọ laarin awọn mejeeji ṣe maa ri.

Bi lọkọ laya ṣe n wo ara gan an ṣe pataki nipa ninu ibalopọ tawọn mejeeji yoo jọ gbadun.

Wiwọ iru awọn aṣọ kan fun ọkọ tabi iyawo ẹni naa le jẹ ki lọkọ laya jọ gbadun ibalopọ.

Anfaani ibalopọ fun ọkan ati ara

Dokita Gloria G. Bramer to jẹ onimọ nipa ibalopọ ṣalaye pe gbogbo ero eeyan nipa ibalopọ bẹrẹ lati inu ọpọlọ.

Dokita Bramer ni oriṣiiriṣii anfaani lo wa ninu ibalopọ fun agọ ara eeyan.

O ni ko si ohun to da bii ki eeyan gbadun ibalopọ.

Àkọlé fídíò, Ṣé ó lòdì sí òfin Ọlọ́run kí Krìstẹ́ni jẹ Ọba ilẹ̀ Yorùba? Pásítọ̀ ìjọ Deeper Life sọ ìran tó rí tó fi gbà láti jẹ Ọba
  • Ibalopọ maa n mu oorun wa

Lẹyin ibalopọ, oorun kan maa wa ni ṣha, Ibalopọ maa n ṣeranwọ fun eeyan lati sun daadaa.

Bi ara eeyan ṣe maa n ri lẹyin ti eeyan ba ti goke lọ tan to si tun sọkalẹ maa n jẹ ki eeyan tete ri oorun sun ni kiakia.

  • Ibalopọ maa n jẹ ki inu eeyan dun

Dokita Bramer ṣlaaye pe ti eeyan ba ṣe iwadii awọn lọkọ laya ti inu wọn ba dun papọ, wọn gbọdọ jẹ tọkọ taya to n ṣe ibalopọ daadaa.

Ninu iṣẹ iwadi kan to ṣe agbeyẹwo ẹgbẹrun un mẹrin tọkọ taya, awọn ti ara wọn dantọ julọ lawọn to n ṣe ibalọpọ deedee.

Awọn naa ni wọn tun nifẹ si ibalopọ julọ ninu awọn ti wọn ṣe agbeyẹwo fun naa.

Dokita Bramer rọ awọn eeyan lati ni ibalopọ ki inu wọn si dun.

  • Ibalopọ maa n jẹ ki eeyan mọ iyi ara rẹ

Dokita onimọ nipa ibalopọ sọ pe o dara lati maa ni ibalopọ to dun nitori ara wa.

O ni ibalopọ maa n ṣe iranwọ fun eeyan lati mọ iyi ara yatọ si igboya to maa n fun eeyan.

Bi eeyan ba ṣe n ni ibalopọ to dara si pẹlu ọkọ tabi iyawo eeyan lo ṣe maa mọ iyi ara rẹ to.

  • Ibalopọ maa n dẹkun irora lasiko nkan oṣu

Awọn dokita onimọ nipa ibalopọ sọ pe oogun gidi ni ibalopọ jẹ fawọn to maa n ni irora ni isalẹ ikun wọn lasiko nkan oṣu.

Akọsilẹ fihan pe ọpọ iyawo ile lo maa n sọ pe ibalopọ maa n jẹ ki wọn gbadun irora to maa n ba nkan oṣu wa.

Awọn onimọ nipa ibalopọ ni ọpọ tọkọ taya ni kii fẹ ṣe ibalopọ deedee mọ nigba ti wọn ba ti n dagba.

Wọn ni ewu to wa nibẹ gan an ni pe oju ara obinrin le ti bẹ fun ti oun ati ọkọ rẹ ko ba maa ṣe ibalopọ deedee.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: