Ben Ayade: Mo jẹ́ ọmọlúàbí àti ẹni àpọ́nlé ni mo ṣe lọ sí APC, kìí ṣe ọ̀rọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú

Aworan Gomina Ayade to kuro ninu ẹgbẹ PDP lọ si APC

Oríṣun àwòrán, BEN AYADE/FACEBOOK

Gomina ipinlẹ Cross Rivers, Benedict Ayade, ti salaye ohun to mu kuro ninu ẹgbẹ oṣelu PDP lọ si APC.

Gomina Ayade to kede pe oun ti kuro ninu ẹgbẹ alatako PDP lọ si APC to wa lori alefa ni, ki ipinlẹ oun le jẹ anfaani mudunmudun ijọba apapọ loun fi ṣe bẹẹ.

Ayade to ke gbajare ipenija orisirisi ti ipinlẹ rẹ n koju nipa ọrọ owo, ohun amayederun ati airiṣẹse awọn ọdọ tun sọ pe, isipo pada oun yoo mu ki awọn jẹ anfaani lọdọ ijọba apapọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O wa gba awọn Gomina akẹgbẹ rẹ miran niyanju, lati pawọpọ pẹlu aarẹ Buhari lati mu idagbasoke ba Naijiria.

"A nilo ki gbogbo awọn Gomina mọ wi pe eyi kii ṣe ọrọ ẹgbẹ oṣelu, jijẹ ọmọluabi ni, jijẹ ẹni apọnle si ni. Ifarajin si afojusun Naijiria naa si laa n sọ''

Aworan Gomina Ayade to kuro ninu ẹgbẹ PDP lọ si APC

Gomina Ayade to kuro ninu ẹgbẹ PDP lọ si APC atawọn gomina APC mii

Oríṣun àwòrán, Andre Ekeng Inyang

O ni ti gbogbo awọn ba pawọpọ pẹlu aarẹ ẹni ti yoo gba ijọba lyin rẹ lọdun 2023 ko ni ṣe wahala pupọ.

Lọjọbọ yi ni Gomina Ayade kede pe ohun ko ṣẹgbẹ PDP mọ lẹyin ipade bonkẹlẹ kan to ṣe pẹlu awọn Gomina APC mẹfa.

Ninu awọn to wa nibi ipade naa la gbọ pe awọn aṣofin ile asofin agba mii naa wa.

Lara awọn Gomina to ṣabẹwo si nile ijọba la ti ri Gomina ipinlẹ Kebbi, Imo, Yobe, Plateau, Jigawa, ati Ekiti.