Baba Ijesha: Àwọn ọlọ́paàá àti àwọn agbẹjọ́rò kan ló fẹ́ gba owó, kí wọ́n to fi Omiyinka sílẹ̀

Asaaju ikọ agbẹjọ́rò fun bàbá Ìjẹshà, Adesina Ogunlana ti ke gbàjàrè pé, ó ti pé ọjọ́ kẹrin báyìí ti wọ́n ti fi Bàbá Ijesha sílẹ̀ láti gba onídurò rẹ̀ sùgbọ́n àwọn ọlọ́paàá kọ̀ láti tu sílẹ̀.
Lásìkò tó ń bá BBC Yorùbá sọ̀rọ̀ lọ́sàn òní ló sàlàyé pé gbogbo ìgbìyànjú òun láti gba Bàbá Ijẹsa sílẹ̀ ni àgọ́ àwọn ọlọ́paàá lo já si pàbo.
Gẹ́gẹ́ bi ó ṣe sọ, àwọn ìlànà tí adájọ́ gbé sílẹ̀ fún ìtúsílẹ̀ Bàbá Ijesa ló rọ̀rùn, gbogbo rẹ̀ si ti wà nílẹ̀.
- Ẹ̀sùn gbígbìyànjú láti wọ́lé sí ojú ara ọmọdé pẹ̀lú ìpá àtàwọn ẹ̀sùn mìí tí Baba Ijesha yóò jẹ́ rèé
- Baba Ijesha gba béélì níléẹjọ́ Májísírétì, àmọ́ ọ̀rọ̀ kù kó tó jáde l’àhámọ́
- Iyabo Ojo gbé fídíò jáde nípa bí ọwọ́ ṣe tẹ Baba Ijesha
- 'Nígbá tí a rí Baba Ijesha lónìí ní Panti, ohun tójú wa rí, ẹnu kò lè sọ o!'
- Iyabo Ojo fèsì lórí béèlì tí wọ́n fún Baba Ijesha
- Ṣé lóòtọ́ ni Iyabo Ojo ti bẹ Yomi Fabiyi lórí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha tó wà ní Panti?
- Ẹni tó bá ní láàkàyè, a mọ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, àwà ti kọ lẹ́tà, èsì t'Ọ́lọ́pàá sì fún wa rèé - Yomi Fabiyi
- Wo ẹ̀sùn mẹ́rin tí ìjọba fi kan Baba Ijesha àti ìjìyà tí ìkọ̀ọ̀kan ní lábẹ́ òfín
Sùgbọ́n owó tí wọ́n sọ pé kí ó wà nílẹ̀ fun beeli nítorí ti Baba Ijesha bá sálọ, ni àwọn oníduró yóò san, sùgbọ́n àwọn ọlọ́paàá ni ti àwọn kò bá rí owó náà àwọn ko ni fí sílẹ̀.
Nínú àlàyé rẹ̀, o ní màgòmágo ọlọ́pàá àti apá kan àwọn agbẹ́jọ́rò tó n dúro fún Baba Ijesha, ló n fa ìdádúró.
Ogunlana ni obìnrinn náà kọ́kọ́ fẹ̀sùn kan òun pé kíló de ti òun fi lọ sọ lori ayelujára pé Bàbá Ijesa rù.
"Nígbà tí mo de àgọ ọlọ́pàá, mó lọ bá ọlọ́pàá tó n moju to ọ̀rọ̀ Baba Ijesha, Magret Ighodalo to jẹ́ olórí alábòjútó ọrọ to níi ṣe pèlú ọrọ sise obinrin básubàsu."
Ogunlana ni obìnrinn náà kọ́kọ́ fẹ̀sùn kan òun pé, kí ló de ti òun fi lọ sọ lori ayelujára pé Bàbá Ijesa rù, tó sì bá òun jiyàn pé kò rù, bíkòṣe pé nígbà tó dé ọ̀dọ̀ àwọn gan ló sanra si.
Agbẹ́jọ́rò náà ni èyí ló mú òun fèsì pé ó rù, kóda kò tún le rìn dáradára, ó fi kun pé ṣe ni Baba Ijesha ń wo sùù bi ẹni ti wọ́n ti kó láyà jẹ, àfi ìgbà tí òun pariwo mọ pé, ṣe kò mọ òun gẹ́gẹ́ bi agbẹ́jọ́rò rẹ̀ ni?
Ọgbẹni Ogunlana ni lẹ́yìn ti òun bèèrè fún fóònù rẹ̀ láti le pe àwọn ẹbi rẹ̀, ki gbogbo èto le bẹ̀rẹ̀ ni Baba Ijesa sọ fun òun pé, fóònù wà lọ́wọ́ "Madam" (Magret Ighodalo).
O ni sùgbọ́n lẹ́yìn tí òun gbìyànjú láti gba fóònù náà ni wọ́n sọ pe ko si ina lórí rẹ, àti pé lẹ́yìn wákàti kan ti wọ́n fi fóònù náà sínú iná, síbẹ̀ wọn ko fún òun ni àànfàní láti ri ẹbi kankan bá sọ̀rọ̀..
Àṣẹ̀yìnwá àṣẹ̀yìn bọ̀, Magret Ighodalo sọ pé Baba Ijesha ni agbẹjọ́rò mííràn, òun si fẹ́ kí wọ́n jọ ma ṣe iṣẹ́ pọ̀ fún Bàbá Ijesa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìbúgbàmù wáyé nílé ìyáwé-kàwé Obasanjo, èèyàn méjì dèrò iléwòsàn
- Ìyàwó kẹrin gún ọkọ rẹ̀ lọ́bẹ pa torí ó fún obìnrin míì lóyún
- Yóò dára kí APC kópa nínú ìbò káńsù, kí ẹsín wọn lè hàn sí aráàlú - PDP
- Princess jèbùrẹ́, ọ̀rọ̀ Baba Ijesha gbóná ju èrò ọ̀pọ̀ èèyàn lọ - Adewale Eleso
- Yomi Fabiyi bá Sanwo-Olu, gómìnà Eko sọ̀rọ̀ lórí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha
- Àkúntúnkú, ìgbà mẹ́fà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ rè é tí Shekau kú, tí wọ́n ní kò kú mọ
- Ìrọ́ lẹ pa, ìbò ìjọba ìbílẹ̀ kò ní wáyé l‘Oyo ní Sátidé - APC fárígá
- Èèmọ̀ wọ̀lú! Àwọn jàndùkú jí Adájọ́ gbé lọ nínú kóòtù lọ́sàn án gangan
- Ẹ̀yin tí ẹ sọ pé irọ ni mo ń pa bayii ni yoo ri fún yín
" Mó wa ni ṣe o kò mọ̀ mi ni? Ṣe bi ìwọ náà lo fun mi ni nọnba ẹni naa sáájú àsìkò yìí?
Sùgbọ̀n nǹkan tí mo sàkíyèsí ni pe ni pé, wọ́n ti ko baba Ijesa láyà jẹ àti pé, àwọn agbẹ́jọrò kan wa tí wọ́n ti lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ àwọn ọlọ́pàá lórí ọ̀rọ̀ Baba Ijesa."
Lẹ́yìn ti mo pé agbẹ́jọ́rò náà, ṣe lo jágbe mọ́ mi, tó sì pa fóònù rẹ̀, mo tun padà rán àwọn ọmọ mi pada ní ìrọ̀lẹ́, níbẹ̀ ni wọ́n ti sọ pé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta nàìrà tó wà nínú ètò beeli rẹ̀, o di dandan ki wọ́n san."
Ogunlana sàlàyé pé, owó yìí kìí ṣe fún ṣisan, wọ́n yóò bèèrè fun-un, tí Baba Ijesa ba sálọ ni lẹyin ti wọn ti gba oniduro fun tan.
Sùgbọ́n nnkan ti mo ri ni pe àwọn ọlọ́pàá àti àwọn agbẹjọ́rò kan ni wọ́n jọ n pàdí àpò pọ̀, tí wọ́n si n pé àwọn ènìyàn láti san owó sí àkàntì Baba Ijesa, ki owó náà fi le pé láti pin láàrín ara wọn.
Lọwọ lọwọ bayii, Ogunlana ni awọn ọlọpaa ni owow tawọn eeyan n da jọ lati fi san beeli naa ti to ẹgbẹrun lọna ọọdunrun naira, ₦300,000, o si seese ki wọ̀n fi silẹ, ti owo naa ba pe.
"Emi yari mọ awọn ọlọpaa naa lọwọ ni nigba ti wọn ni ka wa san ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta owo beeli, iru radarada wo niyẹn, nibo ni wọn ti n sanwo beeli?





















