Baba Ijesha: Agbẹjọ́rò ṣe gbòsà fún adájọ́ tó fún Baba Ijesha ní béèlì, ọwọ́ ọlọ́pàá lọ̀rọ̀ kù sí

Oríṣun àwòrán, other
Ni ọjọ Aje ni iroyin jade pe wọn ti fi aye beeli gbajumọ oṣere to ko si gbaga ofin lori ẹsun iwa aṣemaṣe si majesin ti wọn fi kan an, iyẹn Ọgbẹni Omiyinka Ọlanrewaju ti ọpọ mọ si Baba Ijẹsa silẹ.
Gẹgẹ bi iroyin ti a gbọ, lootọ awọn agbẹjọro rẹ ti n gbe igbesẹ fun gbigba beeli rẹ tẹlẹ, ṣugbọn abẹwo igbimọ to n ri si afọmọ awọn ahamọ ọlọpaa ati ọgba ẹwọn ni ipinlẹ Eko pẹlu adajọ Majisireeti agba kan, ni wọn ṣaayan bi aaye gbigba oniduro ṣe yọ fun Baba Ijẹsa labẹ ailera ara rẹ.
Gẹgẹ bi fidio kan ti ọkan lara awọn agbẹjọro Baba Ijẹṣa, Amofin Adeṣina Ogunyinka gbe sita, o ṣalaye pe ọpẹlọpẹ igboya ati iwa akin Majisireeti agba, Toyin Ogre lo jẹ ki "Baba Ijesha ri ẹtọ rẹ labẹ ofin gba"
Amofin Ogunyinka ni awọn ọlọpaa ko kọkọ fi orukọ Baba Ijẹṣa si iwe orukọ awọn ti igbimọ naa fẹ boju wo ọrọ wọn fun beeli labẹ eto afọmọ ahamọ ọlọpaa naa.
Amọ o ni amọṣa adajọ Magisireeti agba naa lo beere pe ki wọn mu Baba Ijẹsa wa ki oun rii.
Igba ti Baba Ijẹsa n jade bọ wa siwaju adajọ Majisireeti agba naa ati ikọ rẹ ni wọn rii pe o n tiro latari oun ti agbẹjọro Baba Ijẹṣa naa ṣalaye pe o jẹ lilu latọwọ awọn ọlọpaa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wón ti fi Baba Ijesha, Olanrewaju Omiyinka tí wọ́n fẹ̀sùn ìbálòpọ̀ kan silẹ̀
- "Sunday Igboho kò fí lààkáyé kún ìjìjàgbara rẹ̀ nípa àtakò sí ìbò 2023"
- Mò ń wá olè tó jí nńkan ní ọọ́físì mi, ẹ̀bùn owó iyebíye rèé - Afeez Eniola
- Ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ìlú Modakeke àti Ile Ife
- Ṣé lóòtọ́ọ́ ni Baba Ijesha ti jáde ní àhámọ́ ọlọ́pàá?
- Ìròyìn òfegè táwọn èèyàn ń gbé kiri lórí ìjà Israel àti Palestine rèé
- Ohun tí àwon Gómìnà egbẹ́ òsèlú PDP fenukò lé lórí rèé nílùú Ibadan
- Nǹkan dé o! Àwọn àgbébọn tún yìnbọn pa ọlọ́pàá méjì lẹ́nu iṣẹ́, wọ́n dáná sun àgọ́ ọlọ́pàá
Lara awọn ohun ti wọn beere ki wọn to lee gba oniduro rẹ ni oniduro meji ninu eyi ti ọkan gbọdọ jẹ oṣiṣẹ ijọba to wa ni akasọ kẹwaa soke pẹlu mọlẹbi rẹ kan. Bakan naa ni owo beeli ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta pẹlu gbọdọ wa di sisan.

Oríṣun àwòrán, Adesina Ademola Ogunlana Facebook
O ni ohun to kan bayii ni ki ọlọpaa ṣe ifidimulẹ awọn eto beeli rẹ wọnyi ki Baba Ijẹsa lee pada si ile rẹ.
Amofin Ogunlana tun fi kun pe awọn ikọ agbẹjọro rẹ yoo pese gbogbo ohun ti adajọ Majisireeti Toyin Ogre beere naa fun nidi gbigba beeli Baba Ijesha.
O ni ireti awọn si ni pe ni Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kejidinlogun oṣu kini, ọdun 2021 gbogbo eto lori beeli Baba Ijesa yoo to, yoo si pada sile.

Wón ti fi Baba Ijesha, Olanrewaju Omiyinka tí wọ́n fẹ̀sùn ìbálòpọ̀ kan silẹ̀

Oríṣun àwòrán, Nollywood
Omiyinka Olanrewaju, bàbà Ìjẹ̀sà ni àwọn agbófinró tí fi ẹ̀sùn kan pé ó se ọmọ ọdun mẹ́rìnlá basu basuỌmọ yìí wà níle apanilerin osonu ni, Damilola Adekoya tí ọ̀pọ̀ mo sì Princess.Àwọn agbófinró ni wọn kò lè fi bàbà Ijesha sílè tẹ́lẹ̀ nítorí pé àwọn ẹ̀ka eto idajọ wá ní iyanselodi
Gbogbo ejọ ni wọn ti sún síwájú tẹ́lẹ̀ nítorí iyanselodi yìíLosan òní ni ìròyìn jáde pé wọn tí fi bàbà Ìjẹ̀ṣà sílè kúrò ní ahamo ọlọ́pàá
Àwọn Adájọ́ kóòtù ibile yìí ń gbọ́ ejò àwọn èèyàn ti olopaa mú bí ó ti yeÈyí kò seyin àwọn Adájọ́ Majisireeti to n lọ káàkiri àgọ́ ọlọ́pàá ni Ipinle Eko láti mú àdíkù bá àwọn tó wà ni àhámọ́ ni pàntí àti àwọn àgọ́ ọlápàá mííràn.
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, agbẹjọ́rò Omiyinka, Adesina Ogunlana sàlàyé pé Májísíréètì náà ló wọ ibi ti Baba Ijesha wà tí àànú ṣì ṣe nítorí pé ìpo ìlera rẹ̀ ṣeni láànú gidi
Agbẹ́jọ́rò náà ni wọ́n bèrè fún oníduro méjì, kí ọ̀kan jẹ́ òṣìṣẹ́ ìjọba tó wà ni ìpele kẹwàá, àti ẹnikeji tó bá jẹ́ ẹbi rẹ̀, Bákan naáà ni wọ́n yóò pèsè ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀dẹ́gbẹ̀ta nítori tí Baba Ijesha ba na pápá bora.
Agbẹ́jọrò náà ni ìlera Baba Ijesha ti mẹ́hẹ gidi, àti pé ẹ̀ṣẹ̀ to ṣẹ kìí ṣe nńkan ti wọ́n ko le gba oníduró fún.
Títí di àsìkò tí à n kọ ìròyìn yìí wọ́n kò tii gba Bàbá Ijesha jáde nítori pé wọ́n kò tíi parí plẹ̀ú gbogbo ètò tí wọ́ yóò fi tu sílẹ̀
O ní àwọn yóò koju ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Eko nítori pé wọ́n tẹ ẹtọ́ James Omiyinka mọ́lẹ̀ ni àwọn kò si le faramọ
Ẹ̀wẹ̀ ọ̀pọ̀ ìgbà ni a ti pé agbẹ́nusọ ọlọ́pàá ìpińlẹ̀ Eko Muyiwa Adejobi tó sì sọ fún ilé iṣẹ́ BBC pé kò sí nnkan to ń jẹ́ pe wọ́n ti fi James Omiyinka silẹ̀, àti pé òun kò mọ ibi ti àwọn ènìyàn tí gbọ́ ìròyìn ti wan ń gbé kiri.
Ọ̀pọ̀ àwọ olọ́lùfẹ́ Baba Ijesha ló ti n dá músò lójú òpó ìkànsíraẹni gbogbo nítori ìtúsílẹ̀ rẹ̀.









