Eniola Afeez: Ẹ̀rọ ayàwòrán CCTV ti tú àṣírí ẹni tó ja mi lólè, ẹ bá mi wá a

Oríṣun àwòrán, eniolaafeez/Instagram
Gbajumọ oṣere tiata Yoruba, Eniola Afeez ti fi oju okunrin kan han fun araye, ẹni to fẹsun kan pe o ja oun lole.
Ninu fidio kan ti Afeez fi lede loju opo Instagram rẹ lo ti fi oju ọkunrin naa han fun gbogbo awọn ololufẹ rẹ.
Nigba to n fi oju afurasi naa lede, o ni inu ọọfisi ti awọn ti n ṣiṣẹ ni ọkunrin naa ti ja oun lole.
- Wọ àwòrán àwọn ẹbí òṣèré Nollywood yii!
- Àwọn òṣèré Nollywood tí wọn ò sí lóri amóhùmáwòrán mọ́
- Ta ló ní kí Adebimpe Oyebade bóra nígbà tí ó darapọ̀ mọ́ Nollywood?
- Ó ti tó àsìkò kí Nollywood fòpin sí èré ilé babaláwo lílọ - Clarion Chukwura
- Mo ti ní ìyàwó àfẹ́sọ́nà, ayẹyẹ ìgbeyàwó mi ń bọ̀ láìpẹ́ - Lateef Adedimeji
- Àwọn òṣèré tíátà Yorùbá tó bá 2018 lọ
O ni "Ọkunrin ti ẹ n wo yii wa jale ninu ọọfisi wa to wa ni Oluyole lonii, o si ko oniruru ohun eelo olowo iyebiye lọ, agbegbe ti wọn ti foju ganni rẹ kẹyin ni adugbo Mobil, to wa ni Ring Road."
"Aworan CCTV yii n ṣafihan bo ṣe ja wa lole ati bo ṣe salọ, a bẹ ẹnikẹni to ba le sọ bi a ṣe le ri mu, ki wọn pe awọn ẹrọ ibaraẹnisọrọ wa."

Oríṣun àwòrán, eniolaafeez/Instagram
O fi kun pe ẹbun nla wa fun ẹnikẹni to ba le ṣamọna bi ọwọ ṣe le tẹ afurasi ọhun.
Pupọ ninu awọn ololufẹ rẹ lo ti bẹrẹ si n fi erongba wọn lede lori ọna to le fi ri afurasi naa ni kankan.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹ̀yin Gómìnà, ọwọ́ yín ni ọ̀nà àbáyọ sí ìṣòro Nàíjíríà wà - Atiku
- Àwọn gómìnà ẹgbẹ́ PDP wọ̀lú Ibadan fún ìpàdé
- Ẹ fi Baba Ijesha sílẹ̀ fún mi, màá ṣe onídùróó rẹ̀ - Yomi Fabiyi
- Àgbà ọ̀jẹ̀ akọrin Fuji, Amoo Igisekele, jáde láyé
- Òkùnkùn birimùbirimù ni Kaduna bi àwọn òṣisẹ ṣe gùn le ìyànṣẹ́lódì-wo bi yóò ṣe kan ìwọ naa
- Wo ìdí méje tí olólùfẹ́ rẹ fi le kọ ìbálòpọ̀ pẹ̀lú rẹ
- Digbí ni ojú irin Kaduna- Abuja wà - Ọlọ́pàá Kaduna
- Ojú mi rí màbo nígbà tí mo bímọ àkọ́bí, ẹ̀ṣẹ̀ ni ká bímọ láì rí owó tọ́jú rẹ̀ - Lizzy Anjorin
Eniola Afeez jẹ ọkan pataki lara awọn olupilẹsẹ ati oṣere tiata Yoruba to dantọ.
O ti gba ọpọlọpọ ami ẹyẹ fun iṣẹ ribiribi to ti ṣe nidii iṣẹ naa ti oun ati iyawo rẹ, Esther Kaleyaye jọ n ṣe.

Oríṣun àwòrán, eniolaafeez/Instagram


















