Atiku Abubakar: Ẹ̀yin gómìnà, ẹ má dúró de ìjọba àpapọ́, kẹ tó wa ojútùú sáwọn ìṣòro Nàíjíríà

Atiku Abubakar

Oríṣun àwòrán, Atiku Abubakar Facebook

Igbakeji Aarẹ tẹlẹ ni Naijiria, Atiku Abubakar ti ke si awọn gomina lati ma duro de ijọba apapọ, ki wọn to wa ọna abayọ si oniruru iṣoro to n dojukọ Naijiria.

Bakan naa lo ni ki awọn gomina naa pe ipade apero lati jiroro lori awọn iṣoro Naijiria, ki wọn si wa ojutu si awọn iṣoro naa laarin ara wọn.

Atiku lo sọ ọrọ ọhun ninu atẹjade kan to fi lede loju opo ibadọrẹ Facebook rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Igbakeji Aarẹ tẹlẹri naa ni, ṣe lo yẹ ki awọn ọmọ Naijiria rere wa ojutu si awọn idojukọ ti Naijiria n koju lai fi ti ẹsin tabi ẹya ṣe.

Oludije sipo Aarẹ labẹ asia ẹgbẹ PDP lọdun 2019 naa sọ siwaju si pe, igbagbọ oun ni pe Naijiria yoo bori gbogbo iṣoro to n dojukọ.

Ọrọ ti Atiku sọ loju opo Facebook rẹ

Oríṣun àwòrán, Atiku Abubakar Facebook

O ni "Iṣoro ti Naijiria n dojukọ ni pe a n pinya laarin ara wa, yatọ si pe a n pinya nipa ti ẹgbẹ oṣelu ati ẹsin."

"Mo ti maa n sọ lọpọ igba pe iyatọ to wa laarin wa kii ṣe ni ti Guusu tabi Ariwa, bi ko ṣe nipa awọn eeyan rere atawọn eeyan buburu.

Mo tun ti maa n sọ lọpọ igba pe ọmọ Naijiria pọmbele ni mi, o si yẹ ki a beere lọwọ ara wa, oun to n tumọ si lati jẹ ọmọ Naijiria."

Atiku sọ pe ojulowo ọmọ Naijiria ni ẹni to n bọwọ fun ẹtọ ẹlomiran labẹ ofin, ti ko si fi ti ẹsin tabi ẹya ṣe, to si n wa ilọsiwaju Naijiria pẹlu gbogbo ipa rẹ ni gbogbo igba.

Àkọlé fídíò, Africa Eye: Ahmed Isah rèé tíí ṣe ààrẹ lásán làsàn ní Nàíjíríà tí inú aráàlú dùn sí

O ni ọmọ "Naijiria rere kii da ilu laamu kii si ṣẹruba awọn alabagbe rẹ."

"Titi di nnkan bii ọdun mẹwa sẹyin, ko si ohun to n jẹ ajinigbe-powo nilẹ yii, o si jẹ ohun ti ko fẹ ẹ ṣẹlẹ ri ninu itan orilẹ-ede wa."

Agba oselu naa sọ pe, a ko le tan iṣoro wa to ba jẹ pe bi a ṣe n ronu lati atẹyinwa naa ni a si ṣe n ronu bayii gẹgẹ bii ọrọ ti onimọ ijinlẹ Albert Einstein sọ.

Atiku wa ke si awọn gomina ni Naijiria lati pe ipade apero laarin ara wọn lori ọna ati wa ojutu si ogunlọgọ iṣoro ti Naijiria n dojukọ nitori awọn iṣoro naa yoo pẹ titi ti wọn ba n duro de ijọba apapọ.

Àkọlé fídíò, Face Transplant: DiMeo ṣùn lásìkò tó n wa ọkọ̀ lálẹ́, ló bá jóná nígbà tí ọkọ̀ gbiná

Lẹyin naa lo ke si gbogbo ọmọ Naijiri lati wa ni iṣọkan ki alaafia le jọba dipo iyapa ti awọn ẹgbẹ kan n pe fun.