Railway Vandals in Kaduna: Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá tún mú àwọn ọ̀daràn mííràn tó jí irin ọkọ̀ ojú irín kó

Oríṣun àwòrán, @TVC
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kaduna ni òun ti mú àwọn afurasi márun kan to n jí irin tó wa ni ojú ìrìnà ọkọ̀ ojúrin, ti wọ́n sì gba tirélà méji tí wọ́n kó irin náà sí bámú.
Agbẹnusọ ọlọ́pàá ni ìpínlẹ̀ náà ASP Mohammed Jalige kéde bi wọ́n ṣe fi panpẹ́ ọba mú wọ́n nínú àtẹjáde kan tó fi síta ni Kaduna.
Jalige ni lọ́jọ́ kẹtàlá ni àwọn ara ilú jẹ́ kí ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá gbọ́ ibi ti àwọn ọdaran náà wá, ni ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá náà bá gbá àwọn ọdàràn náà mú ni abúlé Dalle, níjọba ìbílẹ̀ Jema, nípìnlẹ̀ Kaduna.
- Àwọn Aláṣẹ ilẹ̀ Palestine ní eèyàn 139 ló ti kú ní Palestine nínú ìja Isreal àti Palestine
- Kò sẹ́ni tó lè ní kí n má yan àwọn Baálẹ̀ nílùú Akure- Ọba Aladetoyinbo Aladelusi
- 'Nígbá tí a rí Baba Ijesha lónìí ní Panti, ohun tójú wa rí, ẹnu kò lè sọ o!'
- Sunday Igboho àtwọn ọmọ Yoruba láti ìpínlẹ̀ mẹ́jọ bẹ̀rẹ̀ ìwọ́de 'Yoruba Nation' nílùú Osogbo
Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ń se ìfọ̀rọ̀wánílẹ́nuwò lọ́wọ́ láti mọ àwọn tí wọ́n jọ n jùmọ̀ ṣiṣẹ́ pọ̀ láti ba ohun amúludùn Nàìjíríà jẹ́.
Bákan náà ni Jalige ṣe àlàyé lórí àwọn fọ́nran àti fótò tó n jà ràìràin lórí ayélujara pé kò ni nǹkan ṣe pẹ̀lú ojú irin Abuja-Kaduna nítorí pé ìgbòkègbodo reluwé kò dúró lọ́nà náà.
Ó ní fọ́nran tó jà ràìnràìn lórí ayéjara jẹ́ ti èyí tó wáye ni ìlú Enugu, ní bi ti ikọ àbò araẹni àbò ilú (NSCDC) ti mú àwọn kan to jí iru irin bẹ́ẹ̀ kó.
Jalige rọ àwọn ará ilú láti keti ikún sí ìròyìn tó sọ pé ti Kaduna- Abuja ni
Agbẹnusọ náà sọ pé ìṣẹ̀lẹ̀ méjèèjì kò níṣe pèlú ojú irin Kaduna-Abuja .
Tí ẹ kò bá gbàgbé, ilé isẹ́ ọlọ́pàá Enugu náà fójú àwọn ọdáràn tó ṣe irú iṣẹ́ náà hàn












