Deji Akure and Ondo Government: Irọ́ ni pé ìjọba fòfin dè mí láti yan àwọn Baálẹ̀ nílùú Akure- Ọba Aladetoyinbo Aladelusi

Deji of AKure

Oríṣun àwòrán, @Ojuasha

Deji ti ilu Akure, Ọba Aladetoyinbo Ogunlade Aladelusi ti sọ pe oun ni aṣẹ lati maa yan awọn Olu ati Baalẹ ni ariwa ati guusu Akure tako ọrọ ti ijọba ipinlẹ naa sọ pe ko ni irufẹ agbara bẹẹ.

Akọwe oriade naa, Adeyeye Michael, lo sọ ọrọ na ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ si awọn akọroyin.

Atẹjade naa ni "Deji ti ilu Akure ti ri awọn iroyin kan to n lọ ninu awọn iwe iroyin pe ijọba ipinlẹ Ondo ti fofin de e lati yan awọn oloye ati Baalẹ."

"A fẹ ki o ye gbogbo eeyan pe irọ pata ni awọn iroyin naa ati pe awọn to kọ irufẹ iroyin bẹẹ gbe igbesẹ ọhun lọna ati ṣi awọn araalu lọna ni."

Wọn ni bo tilẹ jẹ pe awọn gba lẹta kan lati ọọfisi ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Ondo to n ri si ọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ lori ọrọ naa to ti wa nile ẹjọ tẹlẹ, ile ẹjọ ti da ẹjọ naa nu.

Deji of AKure

Oríṣun àwòrán, @DailyPostNGR

Atẹjade ọhun ni lati igba iwasẹ ni Deji ti jẹ alaṣẹ lori ilẹ Akure ati awọn ilu kereje to wa ni agbegbe rẹ, Deji si ni ẹni to maa n yan awọn oloye ati Baalẹ lori awọn ilu naa.

Àkọlé fídíò, Alara tí Ilara Epe: Òjò gbọ́dọ̀ rọ̀ lásìkò ọdún Ẹlẹ́gba ni ìlú Epe- Oba Olufolarin Ogunsan

Bo tilẹ pe awọn Baalẹ kan ti kọkọ gbe Deji lọ ile ẹjọ lori iṣẹlẹ to jọ mọ ọrọ oye jijẹ naa ṣaaju, atẹjade ọhun ni ile ẹjọ ti da ẹjọ naa nu, Deji si ni alaṣẹ lori gbogbo ilẹ Akure.

Àkọlé fídíò, India, Coronavirus: Ìtọ́jú aláìsàn ló jẹ́ mi lógún nítorí ètò ìlera wa mẹ́hẹ- Nọ́ọ̀sì Kama

Ọjọ kẹtala, oṣu Karun un, ọdun yii ni iroyin kan gbode pe ijọba ipinlẹ Ondo ti paṣẹ fun Deji ti ilu Akure lati jawọ kuro ninu yiyan awọn Baalẹ.

Lara awọn ilu ti iroyin naa sọ pe Deji ko laṣẹ lati yan Baalẹ rẹ ni Ago Sonibare ni Ala/Ajagbusi, Eleyewo, Ago-Ajapada ni igbo Ofosu, Ago Tedibomi ni Ala/Ajagbusi, Agunla to wa ni Ayede-Ogbese, Ilado/Elemo ati ilu Isinigbo.

Àkọlé fídíò, Iganmu shanty demolition: Oníṣẹ́ ibi pọ̀ tó ń ṣọṣẹ́ lábẹ́ afárá Iganmu yìí ti pẹ́ ṣùgbọ́n.