Custom and Smugglers Iseyin clash: Àwọn eèyàn kan fara gbọta níbi ìjà àwọn Aṣọ́bodè àti Ònífàyàwọ́ nígboro Iseyin lọ́jọ́ ọdún

Iseyin

Oríṣun àwòrán, others

Awọn eeyan kan fi ara gba ọta nibi ija awọn aṣọbode ati onifayawọ n'igboro Iṣẹyin l'ọjọ ọdun.

Eeyan mẹrin ọtọọtọ ni iroyin sọ wi pe wọn padanu ẹmi wọn si ọwọ ọta ibọn ni gbegbe Ọja Ọba nilu Isẹyin lọjọ ọdun Eid Fitri lasiko ti awọn aṣọbode ati awọn onifayawọ doju ija kọ ara wọn.

Bakan naa ni iroyin sọ pe ẹni kan fi ara pa yanayana nibi iṣẹlẹ naa l'Ọjọbọ.

Iroyin fi idi ẹ mulẹ wi pe ibi ajọyọ ọdun itunu awẹ ni awọn eeyan yii wa ki wọn to ṣe kongẹ iku ojiji.

Arakunrin kan to jẹ olugbe ilu Isẹyin, Kehinde Akinsola sọ fun awọn akọroyin pe "aburo oun wa ni agbegbe Ọja Ọba lasiko ti iṣẹlẹ naa waye" gẹgẹ bi o ṣe n ke si ijọba lati gbe igbesẹ ni kiakia.

Aseyin

Oríṣun àwòrán, others

Nibayii, Asẹyin ti ilu Isẹyin, Oba Dr. Abdulganiy Adekunle Salau, Oloogunebi-Ajinese I ti kilọ fun ileeṣẹ aṣọbode lati sun sẹyin ni iwọn kilomita ogoji si ilu naa, bẹrẹ lati ẹnu ibọde to n bẹ ni Ayegun.

Àkọlé fídíò, Ansoogun jagunjagun Iresa Adu Ogbomoso tó máa ń bínú gba ẹbọ- Oloye James Olawale

Ninu atejade ti wọn fi ranṣẹ si awọn akọroyin l'Ọjọbọ, Ọba alade naa ṣe apejuwe ṣiṣe iku pa awọn ọdọ lọjọ ọdun gẹgẹ bi iṣẹlẹ aburu ti ko gbudọ ṣẹlẹ mọ lọjọ iwaju.

Iseyin

Oríṣun àwòrán, others

Ẹwẹ, Oba Dr. Abdulganiy parọwa si awọn eeyan ilu lati fi aye gba alaafia gẹgẹ bi o ṣe n jẹjẹ wi pe awọn to ṣiṣẹ ibi naa ko ni ọ lai fi oju wina ofin.