Oduduwa Nation: Ẹ̀yìn tí ẹ̀ ń pè fún Yoruba Nation, òpè ní yín, ẹ kò ní ìmọ̀ - Ladoja

Ladoja

Oríṣun àwòrán, Twitter

Gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹ, Rasheed Ladọja ti kilọ fun awọn to n beere fun idadurọ orilẹede Yoruba, Oduduwa Nation lati jawọ nitori ibẹrẹ ogun ni yoo jẹ.

Ladọja lo sọrọ nibi adura Eid lasiko ọdun Ramada ni ilu Ibadan.

Ninu ọrọ rẹ, Ladọja ni ibeerẹ ogun ni ọpọlọpọ eniyan ma n mọ, wọn ki n mọ opin rẹ.

O fikun wipe awọn to n beere fun Oduduwa Nation ko mọ itunu rẹ ati ohun ti yoo jasi fun awọn eniyan.

''Ko si ẹni to mọ bi ogun to bẹ silẹ ni Syria ṣe bẹrẹ, ti wọn si ti wa lẹnu rẹ fun ọpọlọpọ ọdun bayii lai tii si ọna abayọ si ogun naa, ti ọpọlọpọ ẹmi si ti ba iṣẹlẹ naa lọ''

''Adura to yẹ ki a maa gba ni wi pe ki Ọlọrun fun wa ni adari to dara lorilẹede Naijiria''.

Àkọlé fídíò, Ansoogun jagunjagun Iresa Adu Ogbomoso tó máa ń bínú gba ẹbọ- Oloye James Olawale

Ladoja ni: ''Nigba miran Ọlọrun si le e fun wa ni awn adari ti ko dara lati koju awọn ipenija kọọkan, to ba jẹ igbayi ni a fẹ yapa kuro ni ara Naijiria, o yẹ ki a ro o daadaa pẹlu agbekalẹ to danmọran''.

''Ati wi pe ta lo sọ fun yin wi pe awọn ara ẹya Ariwa naa fẹ duro pẹlu Naijiria, awọn Guusu naa wa nibẹ ti wọn fẹ lọ, amọ suuru ni gbogbo rẹ gba''.

Ladoja

Oríṣun àwòrán, Twitter

''Ẹyin darandaran, dida ẹran kaakiri igboro ko bojumu mọ ni Naijiria''

Bakan naa ninu ọrọ rẹ ni Rasheed Ladọja ti kesi awọn darandaran lorilẹede Naijiria pe iṣe wọn ko ba ti igbalode mu mọ kaakiri agbaye.

Ladọja ni ko si ibi ti wọn ti n da ẹran kaakiri igboro, ti wọn si n ba oko oloko jẹ.

Ladọja ni opin gbọdọ deba dida ẹran kaakiri igboro nitori ipaniyan to n mu dani loore-koore.

O gboriyin fun awọn gomina kaakiri ipinlẹ ni Naijiria to ti sọ di ofin pe ko gbọdọ si dida ẹran kaakiri igboro mọ ni ipinlẹ wọn.

Amọ, o ni awọn gomina naa gbọdọ ri daju pe awọn eniyan n tẹle ofin naa, nipa fifi idi rẹ mulẹ ni awọn igberiko naa.

Àkọlé fídíò, International Nurses Day 2021: Wo ìpèníjà àti àǹfàní inú iṣk nọ́ọ̀sì- Adetokunbo Shaba