Dare Adeboye: Ikú ẹ̀gbọ́n mi, ọ̀rẹ́ mi, ẹnìkejì mi, Dare kọ́ja bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n... -Leke Adeboye

Dare Adeboye

Oríṣun àwòrán, Google

Leke Adeboye to jẹ aburo oloogbe Dare Adeboye ti sọrọ lori ohun ti oun yoo bẹrẹ si ni ṣe fun ẹbi ẹgbọn oun ni asiko yii to ti fi aye silẹ.

Ọjọ Kọkanla, Oṣu Karun un ni Dare Adeboye wọ ilẹ sun, lẹyin ti o doloogbe ni ẹni ọdun mejilelogoji ni Ọjọ Kẹrin, Oṣu Karun un, ọdun 2021.

Leke Adeboye lasiko to n sọrọ ni oun yoo sa gbogbo ipa oun lati ri i wi pe awọn ọmọ oloogbe naa ri itọju to peye.

Leke ni: ''Nibayii, mo mọ pe mo ni ọmọ mẹfa nitori mo bi mẹta, ẹgbọn mi si bi mẹta, ma a si ṣe itọju wọn.''

''Gbogbo nkan ti wọn ba n ṣe ni ma a ri wi pe mo peju-pesẹ sibẹ to fi mọ igba ti wọn ba n lọ ṣe ayẹwo ara wọn''

'Mo ti sọ fun iyawo mi pe: Awọn ọmọ rẹ ti da ti temi, ma a si sa gbogbo ipa mi lati wa nibẹ fun wọn.''

Leke Adeboye ati EBI Dare Adeboye

Oríṣun àwòrán, RCCG

Leke tun ni pe: ''Amọ mi o ni ṣe iṣe ajihinrere to gbe kalẹ nitori ọgbọn lati ṣe iṣẹ ihinrere rẹ yatọ si ti temi, ti ọpọlọpọ eniyan si fẹran rẹ ti o ba n waasu.''

'' Ti ẹgbọn mi ba n waasu, awọn eniyan ma n ho fun ayọ ni, amọ ti emi ba n waasu ko si ẹni ti yoo ho fun ayọ nitori mo ma n sọ otitọ ọrọ bii abata ti a na ni pọ̀pá ni, ẹnikẹni ni ọrọ mi le ta ba ni, kii ṣe bi ajihinrere.''

''Ohun gbogbo ni emi ati ẹgbọn mi ṣe papọ, to fi mọ ọjọ igbeyawo...''

Leke Adeboye ati Dare Adeboye

Oríṣun àwòrán, Leke Adeboye

Bakan naa ni Leke Adeboye sọ oriṣiriṣi ohun ti oun ati ẹgbọn oun jọ ṣe papọ lasiko ti wọn n dagba, titi awọn fi di ọdọ langba.

Leke ni ileẹkọ kan naa ni wọn jọ lọ lati ileẹkọ alakọbẹrẹ, girama, to fi mọ kikawe ni oke okun.

''Nigba ti mo gbọ wi pe ẹgbọn mi n lọ ka iwe ni oke okun ti ko si fẹ mu mi lọ, mo sọ fun pe ọkọ baalu rẹ yoo gbina ti ko ba mu mi dani.

Leke Adeboye

Oríṣun àwòrán, Leke Adeboye

Leke tun ni: ''Ẹgbọn mi lo fi ẹjọ mi sun Baba Adeboye, ki o to di wi pe ẹmi naa tẹle e, ti a si jọ lọ ka iwe ni ileewe kan naa ni oke okun''

''Dare Adeboye jẹ ẹni to kun fun ọgbọn, ti kii ṣi ṣe imẹlẹ ni gbogbo nkan to ba n ṣe''

Leke Adeboye ati Dare Adeboye

Oríṣun àwòrán, Leke Adeboye

Ọpọlọpọ igba ni awọn eniyan maa n sọ fun mi pe ṣe mi o le dabi ẹgbọn mi ni? amọ a yatọ si ara wa''

Leke Adeboye wa gbadura wi pe ọrun lo ja ju fun gbogbo onigbagbọ, ati wi pe oun gbadura wi pe bi Dare Adeboye ṣe pari daradara naa ni awọn yoo pari daradara ni ile aye.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa lori BBC Yoruba: Wo díẹ̀ nípa àbùdá Olodumare- Iyabo Ayinde