African Idols: Kí ló lè mú kí àlùfáà ìjọ Aguda máa kó ère ìṣẹ̀nbáyé pamọ́?

Reverend Father Paul Obayi

Eewọ! A kii ri aja ni mọṣalaaṣi. Ẹ gbọ na, ki lo kan alufaa ijọ Aguda pẹlu awọn ere iṣẹnbaye?

Bẹẹ laa bi ni o. Ilumọọka alufaa ijọ Aguda kan nilẹ awọn Ibo, Rev Fr Paul Obayi lo n ko awọn ere iṣẹnbaye pamọ o.

Kini idi abajọ ti Rev Fr Obayi fi n ko ere pamọ nigba ti ki i ṣe olooṣa?

Rev Fr Obayi ni oun n ko awọn ere iṣẹnbaye yii pamọ si ile ikonkan iṣẹnbaye oamọ si kawọn ọmọde to m bọ lẹyin wa ọla le lanfaani lati ri wọn.

Alufaa Obayi ni tawọn iran to n bọ lẹyin wa ọla ko ba ri awọn ere yii, wọn ko ni mọ itan iran ẹya Ibo.

''Mi o mọ idi tawọn alufaa atawọn ile ijọsin fi n dan sun awọn ere atawọn oriṣa ilẹ Ibo?''

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa lori BBC Yoruba: Wo díẹ̀ nípa àbùdá Olodumare- Iyabo Ayinde

Ibeere ti alufaa Obayi beere niyii nigba to ba awọn akọroyin sọrọ.

''Ọpọ ere iṣẹmbaye Igboukwu lawọn oloe ti jigbe lọ.

Ki lo n ṣẹlẹ bayii nipa ooṣa to wa nilẹ Ozalla?''

Ara awọn ibeere ti Rev Fr Obayi n beere niyii.

Ọpọ ere ati ooṣa iṣẹnbaye ni awọn to fi ẹsin abalaye silẹ di ọmọ lẹyin Kristi ti dana sun lẹyin ti wọn di onigbagbọ tan.

Amọ, Rev Fr Obayi n kaakiri ilẹ Ibo lati ko awọn ere iṣẹnbaye to ba ti gbọ pe wọn fẹ dan sun pamọ.

Koda, o mu awọn akọroyin lọ si awọn ojubọ to ti ko ọpọ ere ati ooṣa iṣẹnbaye to ti ko pamọ bayii.

Àkọlé fídíò, Alara tí Ilara Epe: Òjò gbọ́dọ̀ rọ̀ lásìkò ọdún Ẹlẹ́gba ni ìlú Epe- Oba Olufolarin Ogunsan