Israel ń bá Hezbollah ta ayò àmọ́ ọ̀tá tó burú ló ń kojú

Eefin ibugbamu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Jeremy Bowen
    • Role, International Editor, BBC News
    • Reporting from, Jerusalem
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Àwọn olórí orílẹ̀ èdè Israel ni wọ́n ń fò fáyọ̀ látàrí àwọn àṣeyọrí tí wọ́n ń ṣe lórí ìkọlù tí wọ́n ń ṣe sí ikọ̀ Hezbollah pẹ̀lú ṣíṣe ìbúgbàmù àwọn ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ pager àtàwọn ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ mìíràn kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí ní ju àdó olóró sí wọn láti òfurufú.

Mínísítà fétò ààbò Israel, Yoav Gallant kan sáárá lẹ́yìn ìkọlù ọjọ́ Ajé.

“Òní yìí jẹ́ ọjọ́ kan gbòógì… Ọ̀sẹ̀ yìí jẹ́ èyí tó burú jùlọ fún ikọ̀ Hezbollah láti ìgbà tí wọ́n ti da sílẹ̀, tí àwọn èsì rẹ̀ sì ń fojú hàn.”

Gallant ní àwọn àdó olóró táwọn jù láti orí òfurufú náà ló bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ àdó olóró tí ikọ̀ Hezbollah kò bá fi pa àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Israel. Lebanon ní Israel ṣekúpa èèyàn 550, tó fi mọ́ àwọn ọmọdé àádọ́ta.

Èyí ló jẹ́ ìdajì àpapọ̀ àwọn èèyàn tó ti kú lásìkò ogun ogun tó wáyé láàárín Israel àti Hezbollah fún oṣù kan lọ́dún 2006.

Israel gbàgbọ́ pé ṣíṣe ìkọlù alágbára sí Hezbollah yóò mú wọn ṣe nǹkan tí àwọn ń fẹ́.

Àwọn olóṣèlú àti ológun Israel ń fẹ́ àṣeyọrí. Láti bíi ọdún kan tí ogun ti ń wáyé pẹ̀lú Gaza, àwọn ọmọ ogun Hamas ṣì ń ṣekúpa àwọn ọmọ ogun Israel, táwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Israel ṣì wà ní àhámọ́.

Hamas bá Israel ní òjijì nínú oṣù Kẹwàá ọdún tó kọjá. Israel kò rí Hamas bíi ìdúnkokò tó lágbára tó lè ní ipa púpọ̀ àmọ́ ti Lebanon yàtọ̀. Láti ọdún 2006 tí ogun tó wáyé kẹ́yìn láàárín Hezbollah àti Israel ni ikọ̀ ọmọ ogun Israel àti àjọ Mossad spy ti ń ṣe ìgbáradì fún ìkọlù mìíràn.

Olóòtú ìjọba Israel, Benjamin Netanyahu gbàgbọ́ pé ìkọlù tí wọ́n ṣe yìí ń mú àṣeyọrí jáde nípa gbígba agbára lọ́wọ́ ikọ̀ Hezbollah.

Ó ní àwọn fẹ́ ṣe ìdádúrò Hezbollah láti máa ju àdó olóró rọ́kẹ́ẹ̀tì sí Israel. Bákan náà ni iléeṣẹ́ ológun Israel ní èròńgbà àwọn ni láti lé ikọ̀ Hezbollah kúrò ní ẹnubodè àwọn àti láti pa ohun tó lè máa dúnkokò mọ́ ààbò Israel.

Gaza mìíràn

Àwọn ìbúgbàmù tó wáyé ní Lebanon lọ́sẹ̀ tó kọjá mú ìrántí àwọn nǹkan tó wáyé ní Gaza lọ́dún tó kọjá wá. Israel ṣèkìlọ̀ fún àwọn ará ìlú, gẹ́gẹ́ bó ṣe ṣe ní Gaza, láti kúrò ní àwọn ibi tí ìkọlù yóò ti wáyé.

Israel ní Hezbollah, gẹ́gẹ́ bíi Hamas, ń lo àwọn ará ìlú láti fi dá ààbò bo ara wọn.

Àwọn lámèyítọ́, tó fi mọ́ àwọn tí kò fẹ́ràn Israel, ní ọjọ́ tí wọ́n fún àwọn èèyàn náà kéré púpọ̀ láti kó ẹbí wọn. Òfin ogún ní ààbò gbọ́dọ̀ wà fún àwọn ará ìlú.

Àwọn ìkọlù tí Hezbollah ṣe sí Israel dé ibùgbé àwọn ará ìlú, tẹ òfin láti dá ààbò bo ará ìlú lójú mọ́lẹ̀. Israel àtàwọn orílẹ̀ èdè bíi US àti UK ni wọ́n ti pe Hezbollah bíi ikọ̀ agbéṣùmọ̀mí.

Israel ní àwọn ọmọ ogun àwọn ń bọ̀wọ̀ fún òfin àmọ́ ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè káàkiri àgbáyé ni wọ́n ti ń bu ẹnu àtẹ́ lu nǹkan tí wọ́n ṣe ní Gaza.

Àkọlé fídíò, Watch: Small explosion in Lebanon supermarket

Israel ní àwọn ọmọ ogun Hezbollah ni wọ́n ní ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ pager lọ́wọ́ àmọ́ wọn kò mọ ibi tí àwọn ọmọ ikọ̀ náà yóò wà lásìkò tí wọ́n yóò bú gbàmù èyí tó ṣokùnfà ìdí tí àwọn ọmọdé àti ará ìlú ṣe farapa, táwọn mìíràn sì pàdánù ẹ̀mí wọn lásìkò tí ìbúgbàmù náà wáyé ní àwọn ṣọ́ọ̀bù àti ìgboro.

Èyí ló mú kí àwọn agbejọ́rò kan fi sọ pé Israel ń lo àwọn ohun ìjà olóró láì ṣe ìdáyàtọ̀ àwọn ọmọ ogun àti ará ìlú; tó jẹ́ títẹ òfin tó de ogun jíjà mọ́lẹ̀.

Ogun tó ń wáyé láàárín Israel àti Hezbollah bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1980 ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kejì tí Hamas ṣe ìkọlù sí Israel lọ́jọ́ Keje, oṣù Kẹwàá nígbà tí Hassan Nasrallah pàṣẹ fún àwọn ọmọ ogun rẹ̀ láti yabo ẹnubodè láti ṣe ìrànwọ́ fún Hamas ni ìjà tuntun bẹ̀rẹ̀.

Àwọn ikọ̀ Hezbollah so ọmọ ogun Israel mọ́lẹ̀ tí wọ́n sì jẹ́ kí àwọn èèyàn tó lé ní 60,000 tó wà ní ẹnubodè fi ilé wọn sílẹ̀.

Irúfẹ́ ìkọlù tó ti wáyé ṣáájú

Àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn ní Israel ti ṣàpèjúwe ipa àwọn àdó olóró sí Hezbollah pẹ̀lú Operation Focus, ìkọlù tí Israel ṣe sí Egypt lọ́dún 1967.

Ìkọlù náà gbajúmọ̀ fún ipa tó ní lórí àpapọ̀ Egypt, Syria àti Jordan.

Kìí ṣeàfiwé tó dára jùlọ. Lebanon àti ogun pẹ̀lú Hezbollah yàtọ̀. Israel ti ṣe ìkọlù tó lágbára síbẹ̀ kò ṣe ìdádúrò Hezbollah láti ṣe ìkọlù sí Israel.

Àwọn ogun tó ti wáyé láàárín Israel àti Hezbollah tẹ́lẹ̀ rí kìí ṣe àgbéjáde ẹnìkan bíi olúborí. Ó ṣeéṣe kí èyí náà rí bẹ́ẹ̀ àmọ́ ìkọlù tí Israel ṣe lọ́sẹ̀ tó kọjá dùn mọ́ àwọn ọmọ ogun rẹ̀ nínú.

Israel ní ìgbàgbọ́ pé ìkọlù náà yóò mú wọ́n rí ẹ̀yìn Hezbollah, tí Hezbollah yóò kúrò ní ẹnubodè àmọ́ àwọn èèyàn kan ń sọ pé Hezbollah kò ní dúró. Láti bá Israel jagun ni wọ́n fi dá Hezbollah sílẹ̀.

Èyí túmọ̀ sí pé Israel yóò gbé ogun náà síwájú. Tí Hezbollah bá ṣì mú ẹkùn àríwá Israel gbóná janjan si, tí àwọn èèyàn kò ríbi padà sílé wọn, Israel yóò nílò láti tún ṣe ìkọlù orí ilẹ̀.

Ọkọ ofurufu Israel to n fo ni Haifa lọjọ Kẹrinlelogun oṣu kẹsan-an

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ogun tó ń lọ lọ́wọ́ àti èyí tó ń bọ̀

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Israel ti ṣèkọlù sí Lebanon rí. Ní ọdún 1982, àwọn ọmọ ogun Israel wọ Beirut láti ṣe ìdádúrò àwọn ọmọ Palestine láti máa wọ Israel.

Lọ́dún 1990, Israel tún yawọ ẹnubodè Lebanon. Àwọn Ọ̀gágun Israel lásìkò yìí ni wọ́n jẹ́ ọmọ ogun kékeré nígbà náà tí wọ́n jà takuntakun lòdì sí Hezbollah. Ní ọdún 2000 ni Olóòtú ìjọba Israel nígbà náà, Ehud Barak yọwọ́ nínú ogun náà. Ó ní ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ogun Israel ló ń pàdánù ẹ̀mí wọn àti pé kò dá ààbò bo Israel.

Àwọn ọmọ ogun Israel ní kíkojú Lebanon pẹ̀lú yóò lágbára ju kí kojú Hamas ní Gaza. Hezbollaah ti ń gbáradì láti ìgbà tí ogun ọdún 2006 ti parí.

Israel kò ì tíì rí àwọn ihò ilẹ̀ tí Hamas gbẹ́ sínú ilẹ̀ ní Gaza. Ní ẹnubodè ẹkùn gúúsù Lebanon, Hezbollah tí lo ọdún méjìdínlógún láti fi gbẹ́ ihò sínú ilẹ̀ àti inú àpáta pẹ̀lú àtìlẹyìn Iran.

Àjọ Center for Strategic and International Studies ní Washington DC ní ó ṣeéṣe kí Hezbollah ní àwọn ọmọ ogun tó lé ní ẹgbẹ̀rún ọgbọ̀n, tí àwọn tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún wà ní ìpamọ́. Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ogun yìí ni wọ́n ti ní ìrírí láti ìgbà Assad ní Syria.

Wọ́n ní Hezbollah ní àdó olóró missile àti rọ́kẹ́ẹ̀tì tó wà láàárín 120,000 sí 200,000 tí wọ́n lè lò láti fi ṣe ìkọlù sí Israel.

Ọmọ ogun Israel

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Israel le máa rò ó pé Hezbollah kò ní lo àdó olóró na tán, pé wọ́n máa bẹ̀rù pé kí nǹkan tó ṣẹlẹ̀ ní Gaza má wáyé ní Lebanon, níbi tí wọ́n ti pa gbogbo ìlú run, tí wọ́n sì pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ará ìlú.

Iran le má fẹ̀ ẹ́ kí Hezbollah lo gbogbo nǹkan ìjà ogun nítorí Israel lè ṣe ìkọlù sí àdó olóró Iran.

Pẹ̀lú ogun tó ń lọ lọ́wọ́ ní Gaza, àti àwọn làásìgbò tó ń lọ ní West Bank, Israel máa nílò àtìlẹyìn tí wọ́n bá gbógun ti Lebanon.

Òpin tó lágbára

Àwọn alátìlẹyìn Israel bíi Amẹ́ríkà kò fẹ́ kí Israel yawọ Lebanon.

Hassan Nasrallah ní Hezbollah kò ní dáwọ́ ṣíṣe ìkọlù sí Israel dúró àyàfi tí ogun Israel àti Gaza bá dúró. Àmọ́ Hamas àti Israel kò ì tíì pinnu láti fẹnukò láti fòpin sí ogun.

Bí àdó olóró òfurufú Israel ṣe ń tẹ̀síwájú láti máa wáyé ní Lebanon, àwọn ẹbí tí àìrajaja ètò ọrọ̀ ajé ń bá fínra ń kọminú lórí ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí wọn.

Àwọn èèyàn Israel mọ̀ wí pé Hezbollah le ṣe àwọn ní ìjàm̀bá ju ti àtẹ̀yìnwá lọ.

Israel gbàgbọ́ pé àsìkò ti tó fún àwọn láti ṣe gírí láti lé Hezbollah kúrò ní ẹnubodè wọn àmọ́ wọ́n yóò kojú ọ̀tá alágídí.