O ṣòro púpọ̀ láti ya àwọn ológun àti lílo òògùn olóró - Onímọ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ni ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹrindinlogun oṣu kẹsan an ni Ọga agba fun ileeṣẹ ologun lorilẹede Naijiria, Ọgagun Taoreed Lagbaja ke gbajari sita lori bi awọn ọmọ ologun, ti wọn ran lọ koju awọn ọdaran ṣe n lo oogun oloro.
Lagbaja sọrọ yii nibi apero kan to waye niluu Sokoto, nibi ti Ọgagun Ibikunle Ajose ti soju rẹ, to si jẹ ko di mimọ pe ileeṣẹ ologun ti n gbe igbesẹ lori bi adikun yoo se ba lilo oogun oloro laaarin awọn ọmọ ologun.
“Lilo oogun oloro laarin awọn ọmọ ologun to wa loju ogun jẹ nnkan to n ba mi lọkan jẹ pupọ.
“Mo rọ ẹyin ọmọ ologun gbajumọ sise rere ati ohun tuntun, ti ẹ ba se ẹyi, ẹ o mu ilọsiwaju ba ileeṣẹ ologun Naijiria.”
Lagbaja wa fi da awọn ọmọ ologun loju pe yoo tun bọ ma pese iranlọwọ fun lorekore lati le se iṣẹ wọn daada.
BBC News Yoruba ba onimọ nipa eto abo sọrọ lori ewu to dirọ mọ lilo oogun oloro laarin awọn ologun.
Ninu alaye rẹ, Arakunrin, Akin Adeyi ṣalaye pe o nira pupọ lati pin ọmọ ologun ati lilo oogun oloro nitori iṣẹ ati oogun oloro wọ inu ara wọn.
Adeyi ni ọpọ ologun lo ma mu nnkan to ba wu wọn ti wọn ba ti wa loju ogun nitori oju lasan ko se se iru iṣẹ ti wọn n sẹ.
“Awọn ti awọn ologun n lọ ba ja, wọn ma ti mu ogun oloro sugbọn o le jẹ pe awọn ologun ti n lo ni ilokulo fun Ọga Lagbaja lati fọhun sita.
“O soro lati ya iṣẹ yẹn pẹlu oogun oloro ti a ba ni ki a sọ ododo fun ara wa.
“A ri ninu awọn ologun ti wọn ko ki n mu awọn oogun oloro wọnyi ti iwa rẹ si ni agbara gan sugbọn ti awọn mii ko ba mu ninu wọn, bi wọn se ma wo gan ko ni le dabo bo orilẹede rẹ.
“Nigba ti a mọ iṣẹ ologun tipẹ, ni a ti mọ wọn pẹlu mimu imukumu sugbọn ki ṣe gbogbo wọn.
Ewu lo wa fun ilu bi awọn ologun se n lo oogun oloro yii?
Adeyi ṣalaye siwaju pe ewu wa ninu bi awọn ologun se n lo oogun oloro yii, ti wọn si n siwawu ni ọpọ igba.
O ni iko ara ẹni nijanu ti sọnu ni ileeṣẹ ologun ti pora.
“Tẹlẹ tẹlẹ, ẹ o le ri awọn ologun ni igboro sugbọn ni bayii, ẹ ma ri wọn ni ile ọti, ti gbogbo eeyan yoo si da bi Boko Haram loju wọn.
“Ti a ma wo wọn bi pe ki oun pa wọn
“Ni aye igba kan, a ji mu lo jẹ, ti wọn ba n mu sugbọn wọn ti n mu ni igbangba, ti ko si pe wọn n dọgbọn si rara.
“Nnkan le da ori awọn ologun ru, ti wọn ko si wulo fun ileeṣẹ ologun ati mọlẹbi wọn mọ.”















