Kí ni yóò gbẹ̀yìn ìgbẹ́jọ́ Nnamdi Kanu bí adájọ́ ṣe ní òun kò lọ́wọ́ nínú ẹjọ́ rẹ̀ mọ́?

Adajọ to n gbọ ẹjọ Nnamdi Kanu, Binta Nyako, ti yọ ọwọ rẹ kuro ninu ẹjọ naa lẹyin ti olujẹjọ sọ pe oun ko ni igbagbọ ninu rẹ mọ fun idajọ ododo.
Lasiko ti wọn pade nile ẹjọ lọjọ Iṣẹgun ni Kanu sọ ọrọ naa.
Kanu ni “mi o ni igbagbọ ninu rẹ mọ, yọ ara rẹ kuro ninu igbẹjọ yii.”
Ọrọ yii lo jẹyọ lasiko ti agbẹjọro Kanu, Aloy Ejimakor n rọ ile ẹjọ pe ẹjọ naa ko ni le bẹrẹ nitori pe ajọ DSS ko tii tẹle aṣẹ pe ko fun onibara oun laaye lati pinlẹ igbẹjọ rẹ daadaa.
Ẹjọ iditẹgbajọba ati igbesunmọmi ni ijọba apapọ fi kan Kanu latari ijagbara rẹ fun ominira ilẹ Igbo.
Amọ gbogbo igba lo n sọ pe oun ko jẹbi ẹsun ti ijọba ka si oun lẹsẹ.
Lọjọ Iṣẹgun ni ariyanjiyan waye nilẹ ẹjọ laarin agbẹjọro Kanu, Aloy Ejimakor ati agbẹjọro ijọba apapọ, Adegboyega Awomolo.
Agbẹjọro ijọba sọ pe oun ti ṣetan lati bẹrẹ igbẹjọ, oun si fẹ pe ẹlẹri amọ ijọba gbọdọ pese abo to peye fun ẹlẹri oun.
Agbẹjọro Kanu fesi pada pe igbẹjọ naa ko ni le bẹrẹ nitori pe ajọ DSS ko fun oun laaye lati ṣe imurasilẹ onibara oun daadaa.
Nibi ti ariyanjiyan yii ti n lọ lọwọ ni Kanu ti bẹ ile ẹjọ pe oun ni ọrọ lati sọ.
Nigba ti wọn fun lanfani lati sọrọ, Kanu ni “Oluwa mi, kii ṣe igba akọkọ ree ti o ma kọti ikun si aṣẹ ile ẹjọ to ga julọ pe mi o ni salọ ti wọn ba fun ni beeli. Mo si ni ẹjọ kotẹmilọrun mẹta ọtọtọ niwaju ile ẹjọ kotẹmilọrun lori ọrọ yii kan naa.”
Lẹyin ọrọ Kanu ni adajo fesi pe “inu mi yoo dun lati yọ ara mi kuro ninu ẹjọ yii, ohun ti mo si maa ṣe niyẹn, mo maa tare iwe ẹjọ yii siwaju adajọ agba ile ẹjọ giga ijọba apapọ fun igbesẹ to kan.”
Yoo to igba wo ki wọn yoo ri adajọ tuntun ti yoo gbọ ẹjọ Kanu?
Ni bayii ti adajọ Nyako ti yọ ọwọ lawo ọrọ Kanu, ohun to kan ni ki adajọ agba fa ẹjọ naa le adajọ mii lọwọ ti ẹjọ ọhun yoo si bẹrẹ lakọtun.
Nigba ti adajọ Nyako yọ ọwọ kuro ninu ẹjọ naa pe oun yoo fa a le adajọ agba lọwọ, o ni adajọ agba ko si nile, yoo si to oṣu Kejila ọdun yii ko to wa ni itosi.
O ni o ṣeeṣe ko to nnkan bii oṣu mẹfa si asiko yii ki igbẹjọ naa to gberasọ pada.
Agbẹjọro kan to ba BBC sọrọ sọ pe igbẹjọ ọhun yoo falẹ gidi latari pe iye ẹjọ to wa niwaju adajọ agba kii ṣe keremi.
Njẹ o ṣeeṣe lati yanju ọrọ Kanu lẹyin ile ẹjọ?
Agbẹjọro Kanu ti sọ ṣaaju pe o ṣeeṣe ki awọn gba ̣ọna mii lati gba itusilẹ Kanu.
Amọ o fi kun pe aarin awọn agbagba ilẹ Igbo ati ijọba apapọ ni ọrọ naa wa, ko kan awọn agbẹjọro.
O ni eyii n waye latari pe abala ofin 174 ti ọdun 1999 faye gba olujẹjọ lati wa ọna mii lati yanju ẹjọ rẹ ni itubi inubi gẹgẹ bii ọmọluabi.














