Èèyàn 300,000 ní ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́fà ni yóò di aláìnílélórí tí Makinde kò bá yí ìlànà padà lórí líla ọ̀nà Circular yíká Ibadan

Awon olugbe ijọba ibilẹ mẹfa ni ilu Ibadan, olu ilu Ipinlẹ Oyo ni wọn fi ehonu han lọsan ọjọ Aje lati fi ẹhonu wọn han si bi ijọba Ipinlẹ Oyo se n wo dukia won lulẹ.
Igbesẹ naa ni ijọba gbe lati fi aaye gba iṣẹ lila opopona marose titun yika Ibadan eyi tó gba ijọba ibilẹ Lagelu, Akinyele, Ido, Oluyole,Ona-Ara ati Egbeda kọja.
Awọn olugbe awọn agbegbe ọhun lọ ni bi ijọba ipinlẹ Oyo ba tesiwaju pẹlu igbesẹ yìí, o le ni eeyan ẹgbẹrun lọna ọọdunrun 300,00, ti yoo di alainilelori ni ijọba ibilẹ mẹfefa ti opopona naa yoo gba kọja.
Ọdún wó ní èmi ti mọ̀ jẹ́ opó fẹ́ kọ ilé míràn lẹ́yìn tí mò fẹyinti lẹ́nu ìṣẹ ìjọba - Awosika Kikelomo

Ninu ifọrọwerọ pẹlu akọroyin ile iṣe BBC yoruba, iya aafin Awosika Kikelomo, ẹni ti o ti fẹyinti lẹnu isẹ ijọba ipinlẹ Oyo lati ọdun 2016, to tun jẹ opo, ni lati inu oṣu Kẹsan ọdun 2009 ni oun tí ko de ile oun.
Kikelomo ṣalaye wí pe ọdun mẹta lẹyin ti ohun ko de ile naa, to wa ni agbegbe Kole nijoba ibilẹ Akinyele, ni oun to gbọ wi pe opopona marose Circular gba ẹyinkule ile ohun kọja.
O tẹsiwaju wi pe oṣu kẹwaa, ọdun to kọja ni awọn aṣoju ijọba bẹrẹ si ni maaki awọn ile ti yoo di wiwo, ti ile oun ko si si nibẹ.
O ni lẹyin oṣu mẹfa ni awọn aṣoju ijọba to maaki ile oun nitori ijọba tun tí fẹ ọna ọhun loju yatọ si eyi ti o wa tẹlẹ nigbati oun ra ilẹ ọhun, ti wọn si fun oun ni ọsẹ meji lati jade kuro ninu ile naa.
Kikelomo ni idi eyii, lo fa a ti awọn ti ọrọ naa dun fi ko ara wọn jọ lati fi ẹhonu han si igbesẹ ijọba Ipinlẹ Oyo.

Mo di alainile lori lẹyin ti ijọba fi katakata wo ile mi – Fikayo Olalere

Ẹlomiran ti katakata ijọba ti da ile rẹ wo lagbegbe Eniosa nijọba ibilẹ Lagelu, Olalere Fikayo ni, ile oniyara mẹta ni oun kọ.
Lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ, Olalere ni “ Lootọ a gbọ wi pe opopona marose Circular yoo gba agbegbe yii kọja sugbọn ko si ẹni ti o mọ wi pe wọn yoo mu ju ohun to wa ni akọsilẹ lọ.
Ọsẹ kinni ninu osu kẹjọ ọdun yii ni ijọba gbe katakata wa lati wo ile naa ati awọn ile miran ti wọn ṣe ami sii ladugbo naa, lati igba yii ni mo ti di alaini ile lori.”
Ki ni ijọba Oyo sọ nipa awuyewuye yii?

Gomina Seyi Makinde ti Ipinlẹ Oyo ṣeleri lati da igbesẹ ile wiwo duro ni awọn agbegbe to wa ni ayika opopona marose Circular ọhun.
Makinde, nigba to n ba awọn oluwọde naa sọrọ ni lẹyin awọn ile ti wọn ti da wo, o ni ko si ile miran ti yoo di wiwo lulẹ mọ.
Gomina Makinde ni, pẹlu bii ijọba ti yọ mita marun din ni ọgọrin si apa ọtun ati apa osi (75), awọn yoo ri wi pe ni gbogbo ibiti ti ilegbe ba pọ si loju ọna marose Circular naa, ni awọn ko ni fọwọkan.
Gomina Makinde ni oun gborinyin fun awọn to n ṣe ifẹhonuhan naa nitori wọn ko jẹ ki ibinu wọn baa dukia ijọba Ipinlẹ Oyo jẹ.
Ó ni gbogbo awọn ilẹ ti wọn ti kọ ni awọn opopona marosẹ naa ni wọn gbọdọ fọwọkan bayii titi ti opopona naa yoo fi pari.
O wa rọ awọn ti ọna ọhun kan lati yan aṣoju laarin wọn ki wọn le ṣe ipade pọ pẹlu aṣoju ìjọba















