Awọn akọrin Islam mẹ́ta, tó ṣúnmọ́ Rukaya Gawat, sọ̀rọ̀ lórí ohun tó fa ikú rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Rukayat Gawat/ Facebook
Lẹyin ti iroyin iku Rukayat Gawat ja lulẹ ni owurọ ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹrinlelogun oṣu Kẹsan-an ọdun 2024, ibeere to gba ẹnu awọn eeyan ni pe ki lohun to pa obinrin olorin Islam naa gan-an lojiji.
Ọna lati se awari iru iku to pa akọrin Islam naa, lo mu ki BBC Yoruba ba awọn olorin Islam mẹta, ti wọn sunmọ Oloogbe Rukayat daadaa nigba aye rẹ, sọrọ lori iru iku to pa oloogbe naa.
Awọn gbajumọ akọrin to sun mọ Rukayat bii isan ọrun, ti a ba sọrọ ni Barrytide, Temi ni Success ati Aminat Ọmọtayebi.
Lara awọn akọrin Islam naa, Barrytide, to ni oun wa nibi ti wọn tẹ oloogbe Rukayat si, fi omije salaye fun BBC Yoruba nipa iku to pa akẹẹgbẹ rẹ naa.
"Wọn lo rẹ Rukayat ni, a dijọ wa ni ode ariya Temi ni Success laipẹ yii ni - Barry tide
Nigba to n tara poro nipa iku aitọjọ to pa Rukayat, Barrytide sọ pe:
‘’Haa, Aduke ti lọ o, o ti lọ o. Mi o riru eleyi ri o.
Eleyii ju ẹmi mi lọ o, iwaju ẹ la wa bayii o, ta n pe e, ti ko dahun o.
Aduke ti lọ o, eleyii pọ, haa."
‘’Wọn lo rẹ ẹ ni o. Lọjọ party Temi-ni- Suceess, a jọ wa nibẹ ni, ọjọ yẹn ni mo ri Aduke gbẹyin, ṣugbọn a maa n sọrọ daadaa.
‘’Eeyan daadaa ni, oni la maa sin, ko sẹni kan to gẹẹti ara ẹ ninu gbogbo wa bayii o.’’
A ṣì sọ̀rọ̀ lọ́jọ́ Jimọ, wọn ò ṣe bíi ẹni tí nǹkan kan ń ṣe o, Ọlọ́run ló ń dárà ni o - Temi ni Success
Nigba to n dahun ibeere BBC pẹlu ọkan to wuwo pupọ, Alaaja Mistura Aderohunmu Asafa ( Temi ni success) naa sọ pe:
‘’Ẹ wo o, iya mi ni, Anti mi ni, a ṣi sọrọ lọjọ Jimọ.
Wọn ko ṣe bii ẹni ti nnkan kan n ṣe o, mi o le dahun lori iku to pa wọn, Ọlọun lo n dárà ni ki n sọ.
‘’ Anti mi alaniyan ire, ẹni to ni inu ire ni, nnkan oni nnkan, o maa gbe e sori ni.
Mi o le sọ ju bẹẹ lọ bayii naa, ẹ jọọ ( O bu sẹkun).
Alaaja Aminat Ọmọtayebi:
"Haa, mi o le sọ nnkan kan bayii, ọkan mi wuwo.
Mi o le sọ nnkan kan. Ẹ ma binu, ti a ba pari isinku, boya mo le ba yin sọrọ nigba yẹn’’

Oríṣun àwòrán, Facebook/ Instagram
Wọn yóò sin Rukayat sí Ijebu Ayepe lónìí
Gẹgẹ bi awọn olorin Islam mẹtẹẹta yii ṣe wi, oni yii ti i ṣe ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹrinlelogun oṣu kẹsan-an ọdun 2024, ni wọn yoo sin oku Rukayat Gawat .
Ilu Ijebu Ayepe, ti i ṣe ilu ọkọ rẹ ni wọn yoo sin in si nipinlẹ Ogun gẹgẹ bi wọn ṣe fidi ẹ mulẹ.
BBC Yoruba yoo tun maa mu iroyin wa nipa isinku Oloogbe Rukayat Gawat, bo ba ṣe n lọ.
Lẹ́yìn ọdún méjìlá tí Bàbá rẹ̀ dàwátì, Rukayat Gawat, gbajúmọ̀ olórin Islam, jáde láyé

Oríṣun àwòrán, Oloogbe Rukayat Gawat Oyefeso/ Facebook
Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe gbajugbaja olorin Islam nni, Rukayat Gawat Oyefeso, ti jade laye.
Laarọ kutu ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹrinlelogun oṣu Kẹsan-an ọdun 2024 yii ni iroyin iku obinrin olorin Islam naa gbode kan.
Nigba to n kede iku Rukayat loju opo Facebook rẹ laaarọ ọjọ Iṣẹgun naa, Aafaa Aribidesi, ti At-Tawdeeh Islamic Da’awah, kọ ọ sibẹ pe:
‘’ A ba ẹbi Ruqayat Gawat kẹdun fun òfò nla yii. Ki Allah fori ẹṣẹ rẹ jin in. Ruqayat Gawat ti lọ!

Oríṣun àwòrán, Facebook
Bakan naa, Jubril A. Gawat , tii se ẹgbọn akọrin ẹmi naa, to tun jẹ amugbalẹgbẹ fun gomina Babajide Sanwo-Olu nipinlẹ Eko, gbe iroyin iku Rukayat aburo rẹ soju opo ayelujara X rẹ.

Oríṣun àwòrán, Jubril A. Gawat/X
Ta a ni Rukayat Gawat?
Tẹ o ba gbagbe, ọmọ Oloogbe Abdulrasak Gawat, atọkun eto ‘Ẹ ji saari’ lorii tẹlifiṣan nigba kan ni Ruqayat Gawat.
Lasiko aawẹ Ramadan ni Rasak Gawat maa n ṣe eto rẹ, nigba ti awọn musulumi ba n ji saari lọwọ.
Awọn ẹbun rabandẹ bii ilẹ, aṣọ olowo nla, apo irẹsi ati bẹẹ bẹẹ lọ ti Baba Ruka maa n pin lori eto naa lo sọ ọ di ko ṣee ma wo fun awọn eniyan, titi kan awọn ti ki i ṣe musulumi.
Ṣadeede ni Abdulrasak di awati, ninu oṣu keje ọdun 2012.
Mọto rẹ ni wọn deede ba lori afara ẹlẹkẹẹta (3rd Mainland bridge nipinlẹ Eko), lati ọdun naa ni wọn ko si ti ri Gawat mọ.
Wọn ko ri oku rẹ, bẹẹ ni ẹnikẹni ko foju kan an mọ titi doni.
Iṣẹlẹ iku baba rẹ lo sọ Rukayat Gawat aya Oyefeso di olorin Islam, nigba to gbe awo akọkọ rẹ to pe ni ‘’ Aye le’’ jade.
Ninu awo naa lo ti sunkun kikoro lati daro baba rẹ.
Ọpọlọpọ olorin Islam ni Ruka ti ba kọ orin papọ yatọ si awọn orin tiẹ to da kọ.
Awọn bii Saoti Arewa, Ere Asalatu, Amina ọmọ t’ayebi ati bẹẹ bẹẹ lọ.
















