Wo ọ̀nà táwọn ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà tó wà ní Naijiria yóò gbà dìbò tó ń bọ̀

Oríṣun àwòrán, Others
Orilẹede Amẹrika ti gbe ilana sita fun awọn araalu lori bi wọn se dibo, paapa fun awọn ọmọ ilu ti wọn wa ni orilẹede mii saaju eto idibo ti yoo waye ninu oṣu kọkanla.
Ninu atẹjade ti ajọ to n risi ọrọ Amẹrika lorilẹede Naijiria gbe sita loju opo X pe ilana yii wa fun awọn Amẹrika to wa ni oke okun.
Ilana ṣalaye ọna mẹta ti awọn ọmọ ilu Amẹrika to wa ni oke okun gbọdọ tẹle ti wọn ba fẹ ni anfani lati dibo, ti wọn yoo si ka ibo wọn.
Mọ nipa awọn ilana yii
Bere fun iwe idibo: Ọmọ ilu Amẹrika to wa ni oke okun to fẹ dibo yoo kọkọ bere fun iwe idibo ni oju opo ayelujara Federal Voting Assistance Program. Ọpọ iroyin nipa eto idibo naa lo wa loju opo ayelujara.
Gbigba iwe idibo ati didi ibo: Lẹyin iforukọ silẹ fun eto idibo naa, lori ayelujara, oludibo yoo tẹle awọn ilana ti wọn gbe kalẹ, ti yoo si dibo rẹ.
Dida iwe ibo pada: O le mu iwe ibo naa pada lati fi si apoti ti wọn pese niluu Abuja tabi ilu Eko tabi ki oludibo fi ransẹ lati ori ayelujara.
Ileeṣẹ Amẹrika ni ọjọ kẹta, Oṣu kẹwaa ni gbedeke ti wọn fun awọn oludibo to ba fẹ kopa ninu eto idibo nitori ki ibo naa le de si ilu Amẹrika ni ọjọ idibo.
“Lẹyin ọjọ ti a gbe kalẹ yii, a o si ma gba iwe ibo sutgbọn a ko le fogun rẹ gba pe yoo de si ilu Amẹrika.”
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Awọn wo lo ni anfani lati dibo
Awọn ọmọ orilẹede Amẹrika ti wọn ba ti kọja ọdun mejidinlogun ni anfani lati dibo nibi eto idibo aarẹ ti yoo waye ninu oṣu kọkanla ọdun 2024.
Gbogbo awọn eeyan to wa lawọn ipinlẹ lorilẹede Amẹrika ni wọn gbọdọ forukọ silẹ fun idibo naa yatọ si awọn eeyan to wa ni apa ariwa Dakota.
Awọn ọmọ ilu to wa ni oke okun naa le fi orukọ silẹ lati dibo loju opo ayelujara.
Mọ nipa eto idibo aarẹ Amẹrika
Awọn araalu lorilẹede Amẹrika yoo tu sita ni ọjọ karun un oṣu kọkanla lati yan aarẹ tuntun fun orilẹede naa.
Eto idibo ti ọpọ awọn eeyan kakiri agbaye nifẹ si lati mọ ẹni ti yoo di aarẹ tuntun.
Bakan naa ni wọn yoo dibo lati yan awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin.
Awọn oludije meji lo n ja si ipo aarẹ yii – fun ẹgbẹ oṣelu Democrats ni igbakeji aarẹ lọwọ yii, Kamala Harris.
Fun ẹgbẹ oṣelu Republican, Aarẹ ana lorilẹede Amẹrika, Donald Trump ni oludije fun ẹgbẹ oṣelu.














