Wo àwọn olóṣèlú mẹ́ta tó díje dupò ààrẹ Amẹ́ríká láti inú ọgbà ẹ̀wọ̀n

- Author, Mark Shea
- Role, World Service
Ninu akọsilẹ itan oṣelu ilẹ Amẹrika, Aarẹ ana nilẹ naa, Donald Trump, lẹni akọkọ tile ẹjọ da lẹbi ọkan o jọkan ẹsun iwa aṣemaṣe.
Ọpọ awọn ọmọran lo gbagbọ pe, o ṣeeṣe ki Trump faṣọ pempe roko ọba fun awọn ẹsun bii mẹrinlelọgbọn tile ẹjọ kan nilu Manhattan fi kan an lọjọbọ.
Ẹkọ ti bẹrẹ sini soju mimu pe, Trump yoo pe ẹjọ kotẹmilọrun tako igbesẹ naa, leyi toti sunmọ asiko eto idibo apapọ to maa waye ni orilẹ ede Amerika losu kọkanla ọdun 2024.
Bi ile ẹjọ kotẹmilọrun ba lee fidi igbesẹ naa mule, o tumọ sii pe Trump yoo san owo itanran, ki wọn baa wi fun iwa aṣemaṣe ọhun tabi ki wọn maa ṣọ iṣesi rẹ ni gbogbo igba.
Ṣugbọn to ba jẹ wipe awọn ẹsun naa pada sọọ dero ẹwọn, nibẹ ni yoo ti maa tẹsiwaju gẹgẹbi oludije, ati wi pe to ba jawe olubori lẹyin o rẹyin, latinu ọgba ẹwọn ni yoo ti maa tukọ ilẹ Amẹrika gẹgẹbi Aarẹ.
Bawo ẹni tile ẹjọ ti da lẹbi iwa ọdaran ṣe le e forukọ silẹ lati dije idibo?
Latọdun 1789, ti George Washington ti di Aarẹ akọkọ ni orilẹ ede Amẹrika, ko tii si ayipada ninu ilana ti wọn fi n forukọ silẹ lati gbe apoti fun ipo Aarẹ nile naa titi di asiko yi.
Ọjọgbọn Iwan Morgan, onimọ nipa itan ni unifasiti tilu London ṣalaye fun BBC pe, awọn ofin to tun rọmọ igbesẹ naa, ilẹ Amerika ni wọn gbọdọ bi iru ẹni to ba fẹ dupo Aarẹ ibẹ si.
Leyi to ṣokunfa bi awuye wuye ṣe gbode nipa boya Aarẹ Barrack Obama, jẹ ọmọ ilẹ Amerika tabi bẹẹ kọ, bẹẹ ni ọjọ ori ẹni ọhun si gbọdọ to ọdun marundinlogoji.
Ọjọgbọn Morgan tọka sii pe, iru eeyan bẹẹ si ti gbọdọ gbe ni ilẹ Amerikaa fun odindi ọdun mẹrinla gbako, Ṣugbọn o salaye siwaju sii pe ofin wa to de ẹnikẹni tilẹ ba ti da lẹbi iwa ko tọ lati gbapoti fun ipo Aarẹ nilẹ naa.
Ọjọgbọn Morgan ko sai fidi ọrọ rẹ mulẹ ninu iwe itan ilẹ Amerika, nipa bo ti tọka sii pe ko sini lara awọn baba nla to ṣagbekalẹ iwe ofin ilẹ naa lọdun 1787.
Ti ijọba ilẹ Britain mu nigbekun, ṣugbọn ti diẹ lara wọn sunmọ bebe rẹ nigba naa.
Ọjogbọn Morgan sọ pe “ti awọn baba nla ilẹ Amẹrika ko ba ṣaṣeyege nidi ọrọ ayipada ijọja naa ni, o seese ki wọn jiya fun ẹsun igbesẹ gbigbe tako ilana iṣejọba Ọbabinrin ilẹ Britan nigba naa”
Eredi bẹẹ ni awọn to ṣagbekalẹ iwe ofin ilẹ Amerika ko fi lee sọ ni pato iru ẹni to jẹ Aarẹ nibẹ, leyi to sokunfa bi awọn oludije mẹta kan fi lee maa polongo ibo latinu ọgba ẹwọn.
Eugene V Debs

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Eugene V Debs ni ẹni akọkọ ti dije fun ipo Aarẹ ile Amerika latinu ọgba ẹwọn lọdun 1920, gẹgẹbi alaye Ọjogbọn Morgan.
Debs ni wọn sọ sẹwọn fun odindi osu mẹfa gbako lẹyin to lewaji iwọde ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lọdun 1894 tako ile iṣẹ kan, igbesẹ ọhun lo ṣakoba fun erongba oṣelu rẹ nigba naa.
Ọjogbọn Morgan ṣalaye wi pe, ni ọpọlọpọ ọdun sẹyin Debs jẹ ọkan gboogi ninu ẹgbẹ oṣelu, Communist Party of America (SPA), nibi ti ti gbe apoti labẹ aṣia ẹgbẹ naa lọdun 1904, 1908, 1912 ati 1920 lera lera.
Debs lo ni iye ibo to din diẹ ni millionu kan leyi to ko ida mẹfa ninu apapọ ibo ti awọn eeyan di lọdun naa nilẹ Amẹrika,bẹẹ ninu akọsilẹ itan, ko tii sọmọ ẹgbẹ oṣelu SPA to ni iye ibo ọhun ri nibẹ.
Ọjọgbọn Morgan salaye siwaju sii pe, ogun agbaye akọkọ lo sọ ẹgbẹ oselu naa sinu iporuru, lori bi Debs ko ṣe faramọ ogun ọhun, to si sọ fun awọn eeyan ilẹ Amerika lati kọyin si ogun naa.
Losu kẹrin ọdun 1919 ni wọn fi ẹsun iditẹmọ ijọba kan Debs to si dero ọgba ẹwọn titi ti eto idibo fi waye, Ẹwẹ aisan kọluu lasiko to wa lọgba ẹwọn.
Debs gba iyọnda rẹ kuro lọgba ẹwọn lẹyin to ti lo ọdun mẹta nibẹ, nitori bi aisan naa ti wọọ lara gidi, bẹẹ lo si dagbere faye lọdun 1926.
Lẹyin iku Debs ni ẹgbẹ oṣelu communist party ko ti pada gberi mọ nilẹ Amẹrika.
Lyndon LaRouche

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lyndon laRouche ni elomiran to tun gbe apoti fun ipo Aarẹ ilẹ Amerika latinu ọgba ẹwọn nitori pe o gbajumọ daada nigba naa.
Ọjogbọn Morgan mẹnuba bi Lyndon ṣe n dije labẹ ẹgbẹ oṣelu Democrat, ti yoo si tun da duro laaye ara rẹ polongo ni ọpọ igba, bẹẹ lo kopa nibi gbogbo awọn eto idibo to waye laarin ọdun 1976 si 2008.
O darapọ awọn ikọ kan nilẹ Amerika to n pefun bi adinku yoo ti ba owo ori ati sise aridaju bi ijọba ko ni sẹ gbona aitọ maa yọju si nkan ti awọn eeyan ilu ba n ṣe.
Lọdun 1986 ni wọn fi ẹsun iwa jẹgudujẹra kan Lyndon, ti wọn si ran lẹwọn fun ọdun marundinlogun. Wọn yọnda rẹ lẹwọn lọdun 1994.
Lyndon si tun pada gbe apoti fun ipo Aarẹ lọdun 1996, 2000, 2004, ati 2008, nipa bi ko ṣe fi bẹẹ ọrọ to pọ rẹpẹtẹ ninu iwe itan oṣelu ile naa.
Lyndon dagbere faye ni ọdun 2019.
- Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú Republican 'fẹ́ pa mí', ọmọ ààrẹ Amẹ́ríkà fọhùn lórí ìgbẹ́jọ́ owó orí tó ń kojú
- Kí ló wà nínú ìpàdé Putin, ààrẹ Russia àti adarí North Korea to ń fọ́ àwọn orílẹ̀èdè alágbara àgbáyé lórí?
- Àyájọ́ Juneteenth: Wo bí àyájọ́ fífòpin sí òwò ẹrú ṣe bẹ̀rẹ̀ ní orílẹ̀èdè Amẹ́ríkà
- Ọ̀rọ̀ oyún ṣíṣẹ́ ṣe wá di wàhálà t’áwọn aláboyún fi ń pe ìdájọ́ ilé ẹjọ́ níjà?
Joseph Smith.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lọdun 1830 ni Joseph Smith ṣe idasilẹ ikọ ẹsin kan to n jẹ mormonism, to wa fun iyapa ọrọ ẹsin kuro lara ijọ aguda, bakan naa lo foju awọn alatilẹyin rẹ mọ asa nini iyawo pupọ.
Ọjọgbọn Morgan sọpe Igbesẹ naa ni wọn f ri Smith bi ẹni to n tako ọrọ ominira nilẹ Amerika, nipa bi wọn ṣe ni ọran ni irufẹ iwa naa jẹ, ati wipe awọn iyawo rẹ le ni ogun niye.
Leyin ẹyi ni smith dojukọ wahala to mu ipinya deba ikọ ẹlẹsin mormon ọhun., nidi eyi ni Smith fi paṣẹ fun awọn ọmọ ikọ rẹ lati ṣe iwọde nibi ti wọn ti ba ọpọ nkan jẹ ley ti sọ ọ dero ẹwọn ni ilu lllinois.
ẹgbẹ oṣelu rẹ ko fa elomiran kalẹ gẹgẹbi oludije lasiko eto idibo to waye lọdun 1844.
Ninu akọsilẹ iwe itan ilẹ Amerika eeyan mẹta lo ti gbapoti fun ipo Aarẹ lasiko ti wọn wa latimọle ọgba ẹwọn, ṣugbọn to yẹ ki wọn pe mẹrin, to ba jẹ wi pe Joseph Maldonado- Passage gbe apoti nibi eto idibo osu kọkanla ni ile Amerika.
Joseph Maldonado- Passage ti wọn tun saba maa peni Joe Exotic, lo jẹ oṣere tiata, to ṣe agbejade sinima Tiger King Lọdun 2020, ko to kede erongba rẹ lati dije funpo aarẹ labe asia ẹgbẹ oselu Democratic Party.
Wọn ran lọ sẹwọn ogun ọdun fẹsun hihu iwa ko tọ si awọn eranko ati ẹsun igbiyanju lati dẹmin eeyan to ni ibudo ikẹranko pamọ kan.












