Lílọ ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn le ṣe ìdádúró fún ìdájọ́ Trump - Onímọ̀ ṣàlàyé

Aworan Donald Trump

Oríṣun àwòrán, EPA

Awọn agbẹjọro aarẹ tẹlẹ lorilẹede Amẹrika, Donald Trump ti sọ pe awọn yoo lọ ileẹjọ kotẹmilọrun lati tako igbẹjọ to ni Trump jẹbi gbogbo ẹsun ti wọn kan an.

“Gbogbo abala igbẹjọ yii ni a o gbe lọ si ile ẹjọ kotẹmilọrun,” agbẹjọro rẹ, Will Scharf sọ ni alẹ ana lori Fox News.

Nitori awọn igbẹjọ to gbajumọ yii, o ti dabi pe idajọ Trump – eyi ti wọn ṣeto fun ọjọ kọkanla Oṣu Keje - le jẹ idaduro.

Diẹ ninu awọn amofin ti sọ pe o le waye lẹyin idibo Aarẹ lọjọ karun un Oṣu kọkanla.

"Anfani nla wa pe ileẹjọ kotẹmilọrun yoo fagile idajọ yii ṣugbọn ibeere naa ni: n jẹ iyẹn yoo ṣẹlẹ ṣaaju idibo?

“Gbigbe ẹjọ kotẹmilọrun ṣaaju eto idibo ko dara rara, "agbẹjọro Annemarie McEvoy sọ fun BBC.

Bẹẹ ba gbagbe, aarẹ tẹlẹ ri lorilẹede Amẹrika, Donald Trump ni wọn fẹsun kan pe o fi owo bo asẹwo kan, Stormy Daniels lẹnu.

Arabinrin Daniels fẹsun kan Trump pe awọn mejeeji jọ ni ibalopọ, to si gba owo toto ẹgbẹrun lọna aadoje owo dọla lati ọwọ agbẹjọro Trump tẹlẹ, saaju eto idibo ọdun 2016 lati fi ẹnu mẹnu lori ajọsepọ wọn.

Wo àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Donald Trump, ààrẹ Amẹ́ríkà tẹ́lẹ̀ tó jẹ̀bi ẹ̀sùn mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n nílé ẹjọ́

Donald Trump

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Aarẹ orilẹede Amẹrika tẹlẹ, Donald Trump ti di aarẹ akọkọ lorilẹede Amẹrika ti yoo jẹbi idajọ ile ẹjọ lori awọn iwa ọdaran lẹyin to kuro ni ipo.

Awọn ẹsun ti wọn fi kan da lori awọn iwa aiṣododo pẹlu gbogbo awọn idokoowo rẹ ati bi o ṣe gbiyanju lati da aṣọ bo ajọṣepọ rẹ pẹlu Stormy Daniels, gbajugbaja oṣere sinima ibalopọ kan lọdun 2016 lasiko to n ṣe eto ipolongo ibo fun ipo aarẹ.

Nigba to n sọrọ ni ita ile ẹjọ naa lẹyin ti wọn dajọ pe o jẹbi ẹsun mẹrẹrinlelọgbọn ti wọn fi kan an, Donald Trump ṣe apejuwe igbẹjọ naa gẹgẹ bii eyi to mu idojuti nla wa to si tun lọwọ kan makaruru ninu.

Trump tun lerileka pẹlu pe nigba to ba di ọjọ idibo aarẹ lọjọ karun un oṣu kejila, awọn araalu yoo gbe idajọ tootọ kalẹ.

Aarẹ Biden ti tẹwọgba idajọ naa to si ni ko si ẹnikẹni to kọja ofin.