Wo ìgbésẹ̀ mẹ́ta tí ìjọba Ààrẹ̀ Tinubu gbé, ṣùgbọ́n tí ààrẹ tẹ́lẹ̀, Olusegun Obasanjo ní kò bójúmu

Aworan Obasanjo

Oríṣun àwòrán, GETTY IMAGES

Aarẹ tẹlẹri lorileede Naijiria, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ti bu ẹnu atẹ lu iṣakoso Bọla Ahmẹd Tinubu to n sunmọ ọdun kan gbako lori ipo.

Ọbasanjọ sọ pe eto ọrọ aje Naijiria n jiya lọwọ awọn agbekalẹ ilana ti ko bojumu to, ati pe o n fa ọwọ agogo ilọsiwaju orileede yii sẹyin ni.

Aarẹ tẹlẹri naa lo sọ eyi di mimọ lopin ọsẹ to kọja yii nibi eto apero ti wọn pe ni Paul Aje Colloquium (tPAC) to waye niluu Abuja.

Ninu akori idanilẹkọọ rẹ to pe akọle rẹ ni ‘Idagbasoke Naijiria; Gbigba awọn ọna abayọ kuro ninu ipenija wahala eto ọrọ aje ati aisi eto aabo’, Ọbasanjọ ṣalaye erongba rẹ lẹkunrẹrẹ.

Bi ẹ ko ba gbagbe, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu karun-un, ọdun 2023 ni Aarẹ Bọla Tinubu gbajọba lọwọ Aarẹ ana, Muhammadu Buhari.

Ninu atẹjade ti akọwe iroyin Ọbasanjọ, Kẹhinde Akinyẹmi fi sita, o ni baba naa mẹnuba bi awọn kan ṣe n lodi si atunṣe ileeṣẹ ifọpo to wa niluu Prot Harcourt, ipinlẹ Rivers.

O lawọn to n tako atunṣe ileeṣẹ ifọpo naa ti gbagbe pe oun gbe igbesẹ yii lọdun 2007, paapaa lati gbe le awọn aladani lọwọ lẹyin oriṣiriṣi agbeyẹwo.

Bẹẹ lo tun sọ awọn ọna abayọ to le mu ki eto ara aje Naijiria dagba, ati awọn igbesẹ ọdun marundinlọgbọn to le mu orileede yii dagbasoke.

Atẹjade ọhun ṣalaye pe

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

“Lonii, ijọba ti ṣe ipinnu mẹta, eyi ti meji ninu rẹ ṣe jẹ dandan, ṣugbọn to jẹ pe ọna ti wọn gbe e gba ni ko bojumu, eyi to jẹ ki eto ọrọ aje dẹnukọle fun Naijiria ati awọn araalu.

“Awọn wọnyi ni yiyọ owo iranwọ ori epo, didi alafo to wa laarin ọja paṣipaarọ laarin ilu ati ti ijọba, ati pe ẹlẹẹkẹta ni ọna ti wọn n gba da si iditẹ-gbajọba lorileede Niger.

“Ọna abayọ ni gbigbe igbesẹ ati awọn ohun to yẹ nipa igbagbọ ninu awọn adari ijọba ti yoo mu itẹsiwaju wa. Ko si ọna abuda si itẹsiwaju, bi ko ṣe nipa titẹpa mọṣẹ ati oogun.

“Eto ọrọ aje kii gbọ aṣẹ, ko da aṣẹ ologun paapaa. Mo mọ iyẹn. Bi a ṣe rii ṣe daadaa, laarin ọdun meji, a maa bẹrẹ sii ri imọlẹ to n tan. O ni nilọ ayipada ninu iṣẹsi, iwa nipa idari tootọ ni gbogbo ẹka lati le fi ni igboya ati igbagbọ ninu awọn to n da okoowo silẹ ti wọn ni ọna miran.

“Total Energy ti lọ lati ko biliọnu mẹfa owo dọla lori okoowo si Angola dipo Naijiria. Bi a ba fẹẹ sọ otitọ, ijọba asiko yii ko tii wa ọna to tọ lati gbaajumọ eto ọrọ aje, eyi ti yoo jẹ ki awọn olokoowo ni igbagbọ ninu rẹ lati maa sare wọle.

Aarẹ Oluṣẹgun Ọbasanjọ

Oríṣun àwòrán, Punch newspapers

“Wọn mọ wa ju bi a ṣe mọ ara wa lọ. Ati pe ni bayii, niṣe ni wọn n fi wa ṣe yẹyẹ, ti wọn ko si ri tiwa wo. A ni lati gbe ara wa kalẹ lọna ti yoo jẹ ki wọn nigbagbọ pe a ko ṣere. Bi awọn olokoowo ti a ni ba n kẹru wọn kuro lorileede yii, bawo la ṣe fẹẹ ba awọn olokoowo tuntun sọrọ lai wọle wa.

“A le jẹ ki wọn mọ pe a ko ṣere nigba ti a ba yi pada kuro ninu awọn adari ti wọn n lo anfaani lati dokowo laarin ara wọn, si ti awọn adari to n mu ileri ṣẹ nipa sisin ilu tọkantọkan lati ni aṣeyọri rere.

“Pẹlu ayipada nipa wa, awọn olokoowo yoo tun fun wa ni anfaani agbeyẹwo ẹlẹẹkeji, ati pe eto aabo yoo fi ọkan wọn balẹ.

“Pẹlu ilana eto ọrọ aje to yẹ, iwa ọmọluabi to ṣee fọkan tan, ati iwa igbagbọ ninu ara ẹni fun aṣeyọri rere, gbogbo ọwọ lo ni lati wa lori tabili, ki ijọba le di ohun amuṣagbara fun itẹsiwaju, idagbasoke ati ilọsiwaju.

“Lati maa gbiyanju lati tun eto ọrọ aje ṣe lọna ti ko yẹ kii ṣe ọna abayọ. Idahun ni aitasera ninu ilana agbekalẹ lati rii pe eto ọrọ aje duro loju kan.

“Ni ọna yii, a maa rii pe niṣe la n wawọ si awọn olokoowo lati ilẹ okeere lati wọle wa. Otitọ gbọdọ wa, ko si gbọdọ si ohun ti a n fi pamọ ninu ijọba ninu ohun gbogbo ti a ba n ṣe, ati lai purọ tabi tan ara wa jẹ lori ohun to n ṣẹlẹ yii.

“Nigba ti a ba n rii pe ijọba n gbiyanju lati ṣagbekalẹ awọn ilana to tọ, awọn ileeṣẹ aladani naa yoo bẹrẹ iṣẹ wọn lati le rii pe iṣẹ n jade.”

“Ayipada ṣeeṣe, ṣugbọn o gbọdọ bẹrẹ lati ori ipo adari”

Aarẹ tẹlẹri naa tun mẹnuba ọrọ ileeṣẹ ifọpo ti Port Harcourt, eyi ti wọn ni yoo bẹrẹ iṣẹ ninu oṣu kinni, ọdun yii.

O sọ pe lati le kuro ninu ipenija eto ọrọ aje to dẹnukọlẹ lorileede yii, ijọba ati awọn ti wọn n ṣejọba le lori ni lati ṣagbeyẹwo atẹyinwa, asiko yii, ki wọn si beere pe ‘bawo la ṣe de ibi’?

“Nipa wiwo akori eto tonii, ibeere ti maa beere ni pe bawo la ṣe maa ri in ti a fi maa kuro ninu ipenija ati wahala yii, ti a si maa yóri si ebute ayọ.

“Mo nigbagbọ ibeere yii, ọna to pọ lo pin si lati gba, eyi ti yoo jẹ ka mọ gbongbo ipilẹ ohun to fa ipenija yii. Awọn ibeere aarin gbungbun ni pe ‘nibo la wa’, ati pe ‘bawo la ṣe de ibi ti a wa lonii’.

“Akọkọ ni pe, a ni lati mọ ibi ti a ti n bọ. Eto ọrọ aje latigbadegba lo ti n jiya tipẹtipẹ lọwọ ilana ti ko bojumu, aini ilana ọlọjọ pipẹ to le gbe e duro, aile tẹsiwaju, erongba onikaluku ati iwa jẹgudujẹra lori iwa imọ tara-ẹni-nikan, ai kaju oṣuwọn, aini imọ ayi aini oye ati aini ọkan akikanju.

“Bi apẹẹrẹ, awọn ọrọ ti a ti sọ lati ọdun marundinlaadọta sẹyin nipa fifi opin si iṣoro aisi epo naa ni a tun ṣi n mẹnuba titi di oni.

“Mo ranti pe nigba ti mo sọrọ naa wi pe awọn ileeṣẹ ifọpo ko le ṣiṣẹ, awọn alaimọkan ati awọn ọmọwe to wa ninu ijọba lasiko yii ni wọn bu ẹnu atẹ lu mi nigba naa wi pe mi o kii ṣe onimọ-ẹrọ nipa ọrọ epo, ati pe mi o mọ ohun ti mo n sọ.

“Wọn gbagbe pe ipinnu lati sọ awọn ileeṣẹ ifọpo di ti awọn aladani lapa kan lo jẹ pe emi ni mo ṣagbekalẹ lọdun 2007 lẹyin agbeyẹwo finifini ti mo ṣe lee lori. Ṣugbọn ẹni to gba ipo lọwọ mi lo yi ipinnu naa pada, owo dọla $750m ti a san ni wọn da pada.”

Ki lọna abayọ?

Lori ọna abayọ, aarẹ tẹlẹri naa sọ pe a ni lati panupọ lori ipinnu ọdun marundinlọgbọn to le mu ilọsiwaju ba eto idagbasoke, ti gbogbo ẹgbẹ oṣelu to wa lorileede yii gbọdọ fọwọ si, ti ile igbimọ aṣofin agba si gbọdọ buwọ lu, ti awọn ile igbimọ aṣofin lawọn ipinlẹ naa si gbọdọ buwọ lu nile igbimọ aṣofin.

“Ọdun marun-marun ni amulo awọn ipinnu yii yoo maa waye. Ka sọ tootọ, ipinnu yii yoo ni ipa rere ninu iwe ofin wa. Ohun ti yoo jẹ pataki ninu ipinnu yii yoo jẹ lori eto ẹkọ fun gbogbo eeyan.

“Ẹlẹẹkeji ni lori ounjẹ ati aabo lori ọrọ iṣẹ agbẹ. Ẹlẹẹkẹta ni nipa ọrọ ina mọnamọna. Ẹlẹẹkẹrin ni lori idaṣẹsilẹ ati ṣiṣe awọn ohun elo jade. Ati pe ẹlẹẹkarun yoo wa lori imọ ijinlẹ sayẹnsi, tẹkinọlọji, imọ ẹrọ igbalode ati eyi ti wọn n pe ni Artificial Intelligence, AI.

“Ninu gbogbo awọn wọnyi, ki ijọba pese awọn agbegbe aabo to dara fun awọn ileeṣẹ aladani lati le ṣiṣẹ wọn lai ni idiwọ. Ati pe nibi ti ijọba yoo ba ti da si rara, yoo jẹ lori ibaṣepọ ileeṣẹ aladani ati tijọba ti wọn n pe ni PPP, ti ijọba yoo si jẹ ọmọlẹyin.

“A ni lati dẹkun fifi ọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ eto aabo. A ni lati dide si awọn ti wọn ko ṣetan lati dẹkun iwa ọdaran ati iwa ọdaju lawujọ, wọn ni lati ko wọn pamọ fun erongba ọtun. Ko gbọdọ si ọmọ Naijiria ti ko gbọdọ ma gba ile-ẹkọ kọja fun ọdun mọkanla gbako, titi de ipele girama.

“Igbanisiṣẹ gbọdọ jẹ ẹtọ gbogbo ọmọ Naijiria lati ọdun mejidinlogun titi de ọdun marundinlaadọrin. Pẹlu eyi, lati wa, a ko gbọdọ fi ọwọ yẹoẹrẹ mu ọdaran.

“Ọdun marun la gbọdọ la kalẹ fun gbogbo ọmọ Naijiria ti wọn ko si nile-ẹkọ lati wa nile-ẹkọ, ko si gbọdọ yọ ẹnikẹni silẹ. Ile-ẹkọ agba gbọdọ pada bẹrẹ lati rii pe awọn agbalagba lo ọdun mẹfa gẹgẹ bii eyi ti wọn n lo ni ẹkọ aṣẹṣẹbẹrẹ.

“A ni lati fun ara wa ni ọdun mẹwaa lati rii pe gbogbo ọmọ Naijiria lo gba ile-ẹkọ kọja. Ko nii ṣe pẹlu ohun ti a ba ṣe, bi a ko ba wa ọna lati kọ awọn eeyan lẹkọọ, ki a fun wọn ni imọ ati irolagbara

“Awọn ọmọde ni Naijiria to le ni miliọnu lọna ogun ti wọn wa nita lai kawe lonii ni wọn yoo gbẹyin si mimu egboogi oloro amupara, ṣiṣẹ Boko Haram, agbebọn ati awọn iwa ibajẹ miran lawujọ.”