Àwọn ajínigbé jí àwọn arìnrìnàjò gbé l'Ondo

Aworan awọn ajinigbe

Oríṣun àwòrán, Others

Awọn ajinigbe kan kọlu ọkọ akero kan ni opopona Akoko/Imesi lọjọ Abamẹta ti wọn si ji ọpọ eeyan gbe lọ nipinlẹ Ekiti

Awọn ero ọkọ bsi elero mejidinlogun yii lo n ti ode kan bọ ni ipinlẹ Ekiti ti wọn si n pada si Ikare niluu Ondo nigba ti awọn ajinigbe yii kọlu wọn.

Pupọ ninu awọn eeyan ti wọn ji gbe yii lo jẹ alase ti wọn lọ sode lati lọ dana.

Ọga agba fun ikọ Amotẹkun nipinlẹ Ondo, Oloye Adetunji Adeleye fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, to si jẹ ki ko di mimọ pe awọn ikọ ologun Amotekun ti tori bọ ninu igbo lati ṣawari awọn eeyan naa

Nigba to n ba ikọ BBC News Yoruba sọrọ, Adeleye ṣalaye pe awọn ikọ Amotẹkun ti gbiyanju lati doola awọn eeyan kan lọwọ ajinigbe naa.

“Awọn ikọ Ologun mi, ikọ Amọtekun lati Ekiti ati awọn ọmọ ologun to ti wa ninu igbo naa lati gba awọn yii silẹ.

“Ko ki n ṣe gbogbo awọn ero ọkọ naa ni wọn gbelọ, awọn kan ja mọ awọn ajinigbe naa lọwọ, ti awọn ikọ ologun ati Amotekun ri awọn kan gba silẹ ni ooru mọju.

“Lọwọ ti mo n ba yin sọrọ yii, awọn ikọ ologun mi ati ileeṣẹ ologun wa ninu igbo.”|

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Funmi Odunlami naa fidi iṣẹlẹ naa muẹm to si ni awọn eeyan ti fi iṣẹlẹ to ileeṣẹ ọlọpaa leti ni Irun Akoko.

“Eeyan mẹrin ti wa si agọ wa pe lasiko ti wọn n bọ lati Ado Ekiti si Ikara , awọn agbebọn kan kọlu wọn.

“Sugbọn ori ko wọn yọ ninu igbo ti wọn ko wọn si, Ileeṣẹ ọlọpaa ti ni bẹrẹ si ni ma wa awọn eeyan naa.”

Odunlami wa fi da awọn ti ọrọ kan pe awọn eeyan yoo ri itusilẹ gba laipẹ.