Kí ni yóò gbẹ̀yìn ọmọ Áfríká tó jẹ̀bi ẹ̀sùn ìpànìyàn ní Saudi Arabia yìí?

Stephen Munyakho

Oríṣun àwòrán, Dorothy Kweyu

Àkọlé àwòrán, Stephen Munyakho lọdun 2010, ọdun kan ki wọn to fi si ahamọ
    • Author, Waihiga Mwaura
    • Role, BBC Focus on Africa TV, Nairobi

Iya kan ni Kenya ti bẹrẹ si n sa kijokijo lọna ati gba ọmọ rẹ lọwọ iku ni Saudi Arabia.

O yẹ ki wọn ti pa ọmọ obinrin naa lẹyin to jẹbi ṣiṣẹ iku pa ọkunrin ọmọ orilẹede Yemen kan lọdun 2011.

Orukọ ọkunrin naa ni Stephen Munyakho, o si jẹ ẹni aadọta ọdun.

Iku Munyakho le waye nipa yiyẹgi fun, bibẹ lori tabi nipa abẹrẹ iku tabi ki wọn gbẹmi rẹ nipa yinyin ibọn fun un.

Ori bibẹ ni ọna ti Saudi Arabia ṣaba maa n lo lati gbẹmi ọdaran julọ.

Bo tilẹ jẹ pe ijọba ilẹ naa ti dawọ iku ọkunrin naa duro fun saa diẹ, iya rẹ sọ pe wọn ko sọ fun oun ohun ti yoo ṣẹlẹ laipẹ yii.

Ohun ti obinrin naa n ṣe bayii ni lati wa owo ti wọn pe ni ‘diyah’ tabi owo ẹjẹ labẹ ilana ofin Sharia, eyii ti wọn yoo fun mọlẹbi ẹni ti ọmọ rẹ ṣekupa ki wọn ma ba ṣekupa ọdaran ọhun.

Orilẹede ẹlẹsin Islam ni Saudi Arabia, ofin Sharia ni wọn si fi ṣe gbogbo ẹjọ wọn nibẹ.

Owo ti iya Munyakho nilo lati bọ lọwọ iku jẹ $1m amọ lẹyin gbogbo ẹgbẹ lori ayelujara, wọn ko tii ri ju ida 5% owo naa lọ.

Ijọba kenya ti wa n bẹbẹ fun akoko diẹ si ki wọn le ko owo na jọ fun iya Munyakho.

Idunadura ti n waye laarin mọlẹbi ọdaran naa atawọn ẹbi ẹni toṣekupa lori akoko ti wọn le ko owo naa jọ.

Asiko ti ọkunrin naa n ṣiṣẹ ni ija waye laarin oun ati alabaṣiṣẹ rẹ kan ko to gun oloogbe naa pa.

Idajọ ẹwọn ọdun marun un ni wọn kọkọ ṣe fun ọdaran naa amọ wọn yi idajọ rẹ si idajọ iku lẹyin ẹjọ kotẹmiọrun kan to waye lọdun 2014.

Ile ẹjọ ti fun ẹbi Munyakho ni ọjọ karundinlogun, oṣu Karun un, ọdun 2024 yii ko san owo naa fun ẹbi ọkunrin to ṣekupa tabi ki oun naa dero ọrun, ọjọ naa si ti kọja.

Dorothy Kweyu atawọn ọmọ rẹ mẹsan an ya fọto idile kan

Oríṣun àwòrán, Dorothy Kweyu

Àkọlé àwòrán, Dorothy Kweyu surrounded in 2002 by her nine children - Stephen Munyakho can be seen in glasses in the back row
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Labẹ ofin ẹsin Islam, eeyan le san owo ‘diyah’ gẹgẹ bii owo gba mabinu fun mọlẹbi ẹni ti wọn ba ṣekupa tabi ṣe leṣe.

O tun le mu adinku ba iye ọjọ ti irufẹ ọdaran to ṣeku pa eeyan yoo lo ni ọgba ẹwọn tabi ki wọn dari jin ọdaran naa patapata.

Orilẹede bii ogun lo n lo ilana owo diyah yii nilẹ Larubawa, to fi mọ awọn apaka ipinlẹ lawọn orilẹede kan ni Afrika bii Sudan ati Naijiria.

Iwe mimọ awọn Musulumi faye gba sisan diyah – ti wọn pe ni owo ẹjẹ, eyii ti anọbi Muhammad ṣalaye ninu ẹkọ rẹ pe rakumi ọgọrun un ni owo diyah ẹni ti wọn ba ṣẹkupa, yala wọn mọọmọ pa ẹni naa ni tabi wọn ṣeṣi pa.

Amọ laye ode oni, owo ni wọn n fi diyah gba dipo rakunmi.

Onimọ nipa ẹsin Islam kan, Sheikh Husseini Zakaria sọ fun BBC pe iye owo maalu kan jẹ ẹgbẹrun lọna ọgbọn owo ilẹ Saudi, tabi $8,000.

To n tumọ si pe ẹnikẹni ti yoo ba san owo ẹmi ẹni to ṣekupa gbọdọ san nnkan bii $800,000.

Ẹwẹ, nigba ti BBC kan si i, ijọba Saudi kọ lati sọ ohunkohun lori ọrọ naa amọ o dupẹ lọwọ ijọba Kenya fun ipa to n ko lori ọrọ ọhun.

Obinrin kan n wo oju foonu rẹ pẹlu aworan orukọ BBC Africa

Oríṣun àwòrán, Getty Images/BBC