Àwọn ọmọ ìkókó mẹ́fà jóná ní ilé ìwòsàn

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ko din ni ọmọ tuntun mẹfa to ku sinu iṣẹlẹ ijamba ina to waye ni ile iwosan kan ni ilu Delhi, lorilẹede India, gẹgẹ bi awọn ọlọpaa lorilẹede naa ṣe sọ.
Alẹ ọjọ A amẹta ni ijamba ina naa waye ni ile iwosan naa to wa lẹkun kan ti wọn n pe ni Vivek Vihar lolu ilu orilẹede India.
Awọn omo aṣẹṣẹbi mejila lo wa ni ẹka naa ni ileewosan ohun, gẹgẹ bi ọga ọlọpaa Surendra Choudhary ṣe sọ, bi o tilẹ jẹ wi pe ọkan ninu awọn ọmọ naa ti jade laye ki ina naa to bẹrẹ si ni jo.
Awọn alaṣẹ lorilẹede naa n sọ wi pe, ẹni to ni ile iwosan naa, ẹni to ti na papa bora bayii, yoo foju wina ofin.
- Kílódé táwọn orílẹ̀èdè kan kìí ṣe fẹ́ rí Palestine gẹ́gẹ́ bíi orílẹ̀èdè?
- Ìjọba da ẹgbẹẹgbẹ̀rún ẹ̀fọn tí wọ́n ti pa kádàrá rẹ̀ dà síta láti gbógun ti àìsàn ibà
- Wo orílẹ́èdè Adúláwọ̀ márùn-ún tí ètò ọrọ̀ ajé wọn tóbi àmọ́ tí òṣì àti ìṣẹ́ ń báwọn èèyàn wọn fínra
- Ta a ni Ebrahim Raisi, ààrẹ Iran tó kú nínú ìjàmbá ọkọ̀ òfurufú?
Minisita agba fun ilu Delhi, Arvind Kejriwal salaye pe ‘ibanujẹ nlanla’ ni iṣẹlẹ ijamba ina naa jẹ.
“Iwadii ṣi n lọ lati mọ ohun to ṣe okunfa ina naa, ẹnikẹni ti aje iwa aibikita lori ijamba ina naa ba si ṣi mọ lori yoo jẹ iyan rẹ niṣu.”
Adari ileeṣẹ panapana ilu Delhi, Atul Garg fi to ileeṣẹ akoroyinjọ Press Trust of NIndia leti pe ọkọ panapana mẹrinla ni wọn ko lọ si ileewosan naa kati pa ina ọhun.
Amọṣa o ni “agbara ina naa pọ gan an ni nitori ibugbamu agba afẹfẹ idoola ẹmi Oxygen to wa nibẹ “
Ki ni awọn alaṣẹ ijọba lorilẹede naa n sọ?
Oloru ìjọba orilẹede India, Narenda Modi fi si oju opo X rẹ pe: “Ijamba ina to waye ni ile iwosan kan ni ilu Delhi bani lọkan jẹ pupọ.”
Saaju ni ọjọ Abamẹta, “ijamba ina nla “miran ti kọkọ ṣẹlẹ ni gbagede ere igbafẹ kan ni ilu Rajkot to wa ni ipinlẹ Gujarat lẹkun iwọ oorun orilẹede India

Oríṣun àwòrán, screenshot
Ko din ni ọmọde mẹtadinlọgbọn to jona sinu ijamba ina naa, gẹgẹ bí awọn alaṣẹ nibẹ ṣe sọ. Pupọ awọn ti fi ara kaasa ina naa ni wọn jẹ ọmọ lde ti wọn lọ ṣere igbafẹ nibẹ.














