Ta a ni Ebrahim Raisi, ààrẹ Iran tó kú nínú ìjàmbá ọkọ̀ òfurufú?

Oríṣun àwòrán, Getty image
Lẹyin ikede ileeṣẹ tẹlifiṣan orilẹ-ede Iran to fidi ẹ mulẹ pe Aarẹ orilẹ-ede naa, Ebrahim Raisi, ti jade laye ni awọn eeyan ti n ranṣẹ ibanikẹdun si ilu naa.
Ọkọ ofurufuru ti aarẹ naa wa lo jabọ sibi to lewu.
Minisita ọrọ abẹnu Iran tilẹ sọ pe awọn awọn to fẹẹ palẹmọ ọkọ ofurufu ọhun ṣi n gbiyanju lati de ibi ti ijamba naa ti ṣẹlẹ ni.
O ni oju ọjọ ko ti i daa rara lati de ibudo iṣẹlẹ aburu to gba ẹmi Aarẹ Raisi lọjọ Aiku ọsẹ yii.
Ṣugbọn ta ni Ebrahim Raisi? Iru eeyan wo lawọn eeyan Iran mọ ọ si?
Ọdun wo lo dori aleefa atawọn ibeere mi-in tawọn eeyan n beere la mu idahun rẹ wa yii.
Ebrahim Raisi
Ẹni ọdun mẹtalelọgọta ni Oloogbe Ebrahim Raisi lasiko to pade iku lọjọ kọkandinlogun, oṣu karun-un ọdun 2024.
Ọdun 2021 lo di aarẹ Iran, eyi si ni igbakeji to gbiyanju ipo naa.
Igbiyanju akọkọ rẹ lati di aarẹ orilẹ-ede naa ko so eso rere.
Aafa to gbona bii apaara ti ko si gba gbẹrẹ lawọn eeyan mọ ọn si i.
Wọn si ti ni afojusun tẹlẹ pe Ebrahim Raisi yii yẹ nipo aarẹ naa lati ọdun 1989.
Wọn lo yẹ ko ṣe olori orilẹ-ede Iran lẹyin Ayatollah Khamenie to wa nipo ọhun lati ọdun 1989.
Ni 2019, Oloogbe Raisi di olori ẹka idajọ ni Iran.
Ko too doloogbe yii, Ebrahim Raisi ni igbakeji alaga ajọ to n ri si yiyan olori mi-in sipo.

Ààrẹ Iran Ebrahim Raisi tí ọkọ̀ òfurufú rẹ̀ já lulẹ̀ ti jáde láyé

Oríṣun àwòrán, Reuters
Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni yajoyajo ti sọ pe aarẹ orilẹede Iran, Ebrahim Raisi ti ọkọ ofurufu rẹ ja lulẹ lọjọ Aiku ti jade laye.
Ileeṣẹ iroyin orilẹede Iran lo fidi ọrọ yii mulẹ.
Gẹgẹ bi iroyin naa ṣe sọ, minisita ọrọ ilẹ okeere, Hossein Amir-Abdollahian to kọwọọ rin pẹlu aarẹ Raisi naa padanu ẹmi rẹ ninu ijamba baalu ọhun.
Ṣaaju lawọn oṣiṣẹ adoola ẹmi to lọ sibi ti baalu naa ja si sọ pe ko si ami wi pe eeyan kankan ye ninu ijamba ọkọ ofurufu naa.
Ẹlikopita to gbe aarẹ Raisi naa ni iroyin sọ pe iṣẹ rẹ daru lẹyin to kọja nibi ti kurukuru ti pọ gan loju loju.
Ilu Tabriz lapa ariwa guusu Iran ni aarẹ Raisi n lọ ki ijamba yii to ṣẹlẹ.
Iroyin tun sọ pe awọn eeyan mẹta mii naa tun ba iṣẹlẹ ọhun lọ yatọ si aarẹ Raisi ati minisita ilẹ okeere.
Ọkọ̀ òfúrufú tó gbé Ààrẹ Iran, Ebrahim Raisi já lulẹ̀

Oríṣun àwòrán, Iran presidential website
Ọkọ oju ofurufu ẹlikọpita kan to gbe Aarẹ Ebrahim Raisi ti orilẹede Iran ti ja lulẹ.
Iroyin ni Aarẹ wa ọhun ninu ọkọ ofurufu naa lasiko ijamba ọhun to waye lọjọ Aiku.
A tun gbọ pe minisita ilẹ okeere orilẹede naa, Hossein Amirabdollahian, wa ninu ọkọ naa pẹlu Aaarẹ Raisi.
Minisita fun ọrọ abẹle sọ pe awọn adoola ẹmi ti n gbiyanju lati lọ sibi ti ọkọ ofurufu naa ja si, amọ oju ọjọ ti ko ṣe dede n ṣkoba fun igbiyanju wọn.
A ko tii le sọ ipo ti awọn ero inu ọkọ naa wa lasiko ti a n ko iroyin yii jọ wa.
Gẹgẹ bi ohun ti a gbọ, ilu Tabriz to wa ni ariwa iwọ oorun orilẹ-ede naa ni Aarẹ Raisi n lọ lẹyin to kuro ni ala orilẹede Azerbaijan, nibi to ti ṣi awọn adagun omi Qiz Qalasi ati Khodaafarin.
Ileesẹ iroyin Fars news agency jabọ pe o ṣoro lati lọ si agbegbe ti ẹlikọpita naa ja si latari bi oju ọjọ ṣe ri.
Wọn ni awọn oke nla to wa nibẹ, to fi mọ awọn igi gogoro mu ko ṣoro lati ri iwaju.
Ibi ti iṣẹlẹ na ti waye jẹ aadọta kilomita si ilu Tabriz.
Ẹwẹ, awọn elikọpita meji mii ti wọn jọ kọwọ rin balẹ layọ ati alaafia.















