Kí ló lè mú kí Oba Benin máa dunnú báyìí pẹ̀lú ijó lẹ́sẹ̀?

Oríṣun àwòrán, Others
Ọba Benin, Ọba Ewuare Keji ni idunnu ṣubu laayọ fun nigba to tẹwọgba awọn nnkan iṣẹnbaye meji lati orilẹede Germany.
Ileeṣẹ ìjọba to n risi nnkan iṣẹnbaye lorilẹede Naijiria, NCMM lo gbe awọn nnkan naa lọ fun Ọba Benin.
Awọn nnkan iṣẹnbaye naa igi ati apoti tí Ọba Esigie ati Ọba Eresonye lo nigba aye wọn.
Lọdun 1897 ni awọn oyinbo wọ Aafin Ọba Benin, ti wọn si ji ọpọlọpọ nnkan gbe lọ.
Ileeṣẹ ìjọba NCMM gba àwọn nnkan iṣẹnbaye naa lọwọ Ijọba Germany lọdun 2022.
Alage NCMM, Olugbile Holloway lo gbe awọn ere iṣẹnbaye naa fun Ọba Benin.
Nígba to n sọrọ, Holloway jẹri pe ajọsepọ yoo wa laarin ìjọba ati ilu Benin lati mu idagbasoke fun asa Edo.
"NCMM yoo fọwọsowọpọ pẹlu ilu Benin lati se afihan awọn nnkan iṣẹnbaye yii fun araalu.
"Nnkan ti ẹ n wo iwaju wa ni ere iṣẹnbaye ti wọn gbe kuro ni Aafin ni ọdun 1897.
"Awọn nnkan yii ti ṣe iwuri fun ilu Benin nìkan sugbọn fun orilẹede Naijiria, ti a ko si ni dẹkun ṣíṣe isẹ wa ni ọna to tọ."
Nigba to ṣe afihan awọn nnkan iṣẹnbaye naa, Ọmọ N Ọba N Edo, Uku Akpolokpolo Ewuare II pẹlu awọn oloye ki ijo mọlẹ, ti wọn si n dupẹ lọwọ awọn alalẹ ati Olodumare.
Ọba dupẹ lọwọ ijọba orilẹede Germany ati Naijiria fun akitiyan wọn.
Bẹẹ ba gbagbe, orilẹede Sweeden naa kede pe awọn yoo da nnkan iṣẹnbaye mọkandinlogoji pada si ilu Benin.















