Mo ti ṣetán láti gorí ìtẹ́ Olubadan -Olakuleyin

Alagba Owolabi Olakuleyin ti ipo Olubadan kan

Ẹni ti ireti wa pe yoo jọba ilu Ibadan bayii, Alagba Owolabi Ọlakulẹyin,ti sọ pe tabi ṣugbọn kan ko si, oun ni ipo Olubadan kan.

Ọlakulẹyin sọrọ yii lọjọ Ẹti, ọjọ kẹtadinlogun oṣu karun-un ọdun 2024 yii.

Lasiko ti ikọ alabẹwo lati ọdọ Gomina Ṣeyi Makinde lọ ki baba naa nile rẹ lagbegbe Alalubọsa, n’Ibadan lo sọ bẹe.

Alagba Ọlakulẹyin ni oun ti ṣetan lati gun ori itẹ, ati pe ọpẹ lo kan lọrọ oun.

‘’Olúwa ti sọ pé èmi nipò Olúbàdàn kàn, mo sì mọ̀ dájú pé èmi ló kàn’’

Aworan Olakuleyin ati ikọ alabẹwo lati ọdọ Ijọba Ọyọ

Alagba Ọlakulẹyin to sọrọ pẹlu ohun to ja geere, si iyalẹnu ọpọ eeyan to wa nibẹ, sọ pe, “ Inu mi dun lati ri awọn ikọ alabẹwo lati ọdọ gomina.

‘’Nigba ti wọn sọ fun mi pe ẹ n bọ, ẹsẹkẹsẹ ni mo sọ fawọn oloye mi pe ki wọn maa bọ, ki wọn jẹ ka jọ gba yin lalejo.

‘’Inu mi dun pe awọn eeyan mi wa nibi pẹlu mi.

‘’Mo ti ṣetan patapata. Mo mọ pe Ọlọrun wa lẹyin mi. O ti sọ pe emi ni ipo Olubadan kan, emi naa si mọ lododo pe emi lo kan, asiko mi ree.’’

Baba loun ko ni i ja awọn eeyan kulẹ, ati pe gbogbo ajọṣepọ rere to n gbe ilẹ Ibadan ro lawọn yoo jọ jere rẹ. Ko ni i bajẹ laelae.

Ninu ọrọ rẹ, alaga ikọ̀ to ṣabẹwo naa, Amofin agba Bolaji Ayorinde, ṣalaye pe lẹyin tawọn afọbajẹ ti fi orukọ ọmọ oye Owolabi Ọlakulẹyin ranṣẹ, abẹwo tọ si i lati ọdọ ijọba.

Ayọrinde sọ pe Gomina funra rẹ ko ba wa paapaa, bi ko ṣe pe o wa ni irin ajo kan ni.

O ni ti Gomina Makinde ba ti de, yoo waa yọju si ọba Ibadan to kan yii lati ṣe Baba kẹ ẹ pẹ si i.

Awọn yooku ti wọn kọwọọrin pẹlu Amofin Ayọrinde ni Ọgbẹni Ṣẹgun Ọlayiwọla ati Sẹnetọ Monsura Sunmọnu.

lọbalọba nipinlẹ Ọyọ Ọgbẹni Segun Ọlayiwọla ati Ṣẹnitọ Mọsura Ṣumọnu ni wọn jọ kọwọ rin ni bi abẹwo naa.

Aworan awọn olóyè