'Kò sí àǹfàní kankan tí à ń rí, òṣì àti ìṣẹ́ la fi ń lo ayé wa'

Ilu kekere ni ilu Ugba Edogori Amorji Nike jẹ nipinlẹ Enugu.
Awọn to tẹ ilu naa do wa lati ipinlẹ Ebonyi, ati lati ijọba ibilẹ Ezeagu ati Isi Uzo ni Enugu.
Lati asiko ogun abẹle Biafra l'awọn eeyan ilu naa sọ pe awọn ti de ibẹ.
Iṣẹ agbẹ ni ọpọ olugbe ilu Ugba Edogori Amorji Nike yan laayo.
Ko si awọn nnkan amayedẹrun niluu naa, eyi to n jẹ k'awọn alaboyun to ba fẹ bímọ maa rinrin ajo lọ sibi to jinna lati lọ bimọ.
Bakan naa l'awọn ọmọde ilu naa n saisan latari omi odo ti ko dara ti gbogbo ilu n mu.
Ngozi Anyamalu to jẹ ọkan lara awọn olugbe ilu ọhun sọ pe Ọlọrun l'awọn maa n woju rẹ tabi ki awọn ti ẹsẹ ile bọọ nigba kugba ti alaboyun ba ti fẹ bímọ.
"A o ri ounjẹ jẹ ni Ugba Edogori Amorji Nike"
Ngozi Anyamalu sọ fun BBC Pidgin wi pe atijẹ nira fawọn tori ko si ilẹ t'awọn le fi maa dako.
Ẹwẹ, ijọba ipinlẹ Enugu ti sọ pe awọn eeyan lati agbegbe Ezza ni ipinlẹ Ebonyi lo n gbe ni ilu naa l'ọna aitọ.
Kọmiṣọna fun eto iroyin ni ipinlẹ Enugu, Aka Eze Aka ṣalaye pe awọn oṣiṣẹ to n ṣiṣẹ kiri lati ibi kan si ibomiran ni wọn tẹdo si ilu naa.
Awu Chibueze toun naa jẹ olugbe ilu Ugba Edogori Amorji Nike ṣalaye bi o ti padanu oju rẹ lori arun oju ti ko mọ ohun kan nipa rẹ.
Chibueze ni ''iṣẹ oko ni mo n ṣe ki n to ni ipenija oju.
Ti a ba ni ile iwosan ni ilu wa ni, bo ya n ko ba ri iwosan si oju mi."
Chibueze n tiraka lati bọ ara rẹ lẹyin ti iyawo rẹ ti ku.
Ọrọ Ejiofor Anslem naa dabi ọrọ Chibueze ni.
Ejiofor di alaabọ ara lẹyin to lọ gba itọju lọdọ nọọso abẹle kan tori ko si ile iwosan ni ilu wọn.
Amọ, Ejiofor ni oun ko ni kaarẹ pẹlu igbiyanju oun lati jẹ eeyan laye bo tilẹ jẹ pe oun ni ipenija ara.

Gomina ipinlẹ Enugu lati kọ 260 ile iwosan alabọde
Gomina Peter Mbah ipinlẹ Enugu ṣeleri loṣu kejila ọdun 2023 to kọja wi pe ijọba oun yoo kọ ọtalelugba ile iwosan alabọde káàkiri ipinlẹ naa.
Amọ, olori ilu Ugba Edogori Amorji Nike, Cyprain Obasi sọ pe "awọn oloselu maa n wa si ilu wa lasiko ibo, ti wọn si maa n seleri fun wa lati ṣe oriṣiiriṣii nkan.
Amọ, wọn maa n gbagbe wa ti wọn ba ti wọle tan.
Niṣe ni ijọba maa n ri wa bi ẹni to ti ku."
Obasi fikun ọrọ rẹ pe ko si ile ẹkọ kankan ni itosi tawon ọmọde ilu naa le maa lo, bakan naa ni o sọ pe iṣoro omi mimu jẹ ọkan lara awọn ipenija t'awọn araalu Ugba Edogori Amorji Nike n koju.
Kọmiṣọna eto iroyin ni ọpọ lo maa n gbagbe pe awọn eeyan kan n gbe ni ilu Ugba Edogori Amorji Nike.
Ṣugbọn o ṣeleri pe ijọba gomina Mbah ti ṣetan lati mu idagbasoke ba awọn agbegbe kan to fi mọ Ugba Edogori Amorji Nike.
O ni awọn eeyan ilu naa yoo janfani eto ijọba ọhun.















