Oluwo fún ìyàwó Ọmọọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Meghan ni orúkọ Yorùbá

Oríṣun àwòrán, Oluwo of Iwo
Oluwo ti ilẹ Iwo, Oba Abdulrosheed Adewale Akanbi ti fi orukọ Yoruba da iyawo Ọmọọba ilẹ Gẹẹsi, Meghan Markle lọla.
Eyi waye lasiko ti wọn pade nibi ayẹyẹ ti ileeṣẹ ologun gbe kalẹ lati yẹ Duke ati Duchess si ni ile itura Delborough niluu Eko.
Oluwo ni orukọ Yoruba ti iyawo Ọmọọba yoo ma jẹ ni “Adetokunbo” nigba ti wọn pade nibi ayẹyẹ naa.
“Inu mi dun lati fun Meghan ni orukọ Yoruba “Adetokun, to tumọ si pe “Ade ti pada wa lati oke okun”
Iyawo Ọmọọba Harry, Meghan Markle ninu ifọrọwerọ kan to ṣe lọdun 2022, ni ayẹwo fihan pe iṣẹda oun pe oun jẹ ọmọ Naijiria jẹ ida mẹtalelogoji.

Bẹẹ ba gbagbe, Ọmọọba Harry, oludasilẹ idije Invictus Games fun awọn ologun to ti farapa ninu ogun, lo kọwọ rin pẹlu iyawọ rẹ, Meghan lati ṣe abẹwo ọlọjọ mẹta si orilẹede Naijiria, nibi to ti lọ se abẹwo si awọn ologun ni ile iwosan, to si n ṣe iwuri fun wọn.
Bakan naa ni Ọmọọba tun kopa ninu ere idaraya pẹlu awọn ologun ati awọn akanda ẹda.
Nigba to n sọrọ, Oba Akanbi kan sara si Ọga agba fun Ileeṣẹ ologun, Ọgagun Christopher Musa, fun bi o lewaju lati ma bu ọla fun awọn akikanju ologun to farapa lasiko ti wọn n da bobo orilẹede wọn pẹlu bi o ṣe gbe Ọmọọba Harry wa si Naijiria.

Oríṣun àwòrán, Oluwo of Iwo
Ọba Akanbi tun jẹ ko di mimọ abẹwo awọn tọkọtaya yii yoo tun jẹ ki ibaṣepọ to damọran wa laarin Naijiria ati Iyawo Ọmọọba Harry, Maghan.
O ni yoo si tun fi anfani si lẹ fun orilẹede Naijiria lati gba alejọ idije Invictus Game ti ọdun 2027.
“Inu mi dun si awọn ọga ileeṣẹ ologun. Wọn n fun awọn ologun yii ni iwuri to yẹ, ti wọn si mu inu wọn dun
“Abẹwo Duke ati Duchess ti Sussex, Ọmọọba Harry ati Meghan Markle jẹ eyi ti yoo fi itan balẹ.
“Yoo mu ibaṣepọ nla wa nipa eto abo, ti yoo si tun fun orilẹede Naijiria ni anfani lati gba alejo idije Invictus Games lọdun 2027.
A n foju sọna lati gba alejo idije Invictus – Gomina Sanwoolu
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Gomina Babajide Sanwoolu ti ipinlẹ Eko kan sara si bi Ọmọọba Harry ati Meghan ṣeeṣe abẹwo si orilẹede Naijiria lati ṣe iwuri fawọn ologun to farapa ninu ogun.
Gomina sọ eyi nigba to n gba awọn tọkọtaya naa ni alejọ ni ile ijọba Eko, o ni idije yoo fun awọn ologun ni anfani lati mọ pe ko ti tan fun, ti wọn ko si ni ma ri ara wọn gẹgẹ bi ẹni ti ilu ko fẹran.
“Mo kan sara si Duke ati Duchess ti Sussex fun eyi ti wọn gunle yii. Inu wa dun pupọ, ti a si ṣetan lati fọwọsowọpọ pẹlu wọn lati ran awọn ologun wa lọwọ .”















