Ṣé lóòótọ́ ni àwọn kan n fi ìforúkọsílẹ̀ NIMC lu àwọn èèyàn ní jìbìtì?

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Fun gbogbo ọmọ ati olugbe orileede Naijiria lasiko yii, numba ati kaadi idanimọ ṣe pataki pupọ, gẹgẹ bi alakalẹ ijọba apapọ fun gbigbogun ti iwa jibiti ati ọdaran.
Lati bi ọdun meloo ṣeyin ni ijọba apapọ orileede yii ti kan an nipa fun gbogbo ọmọ orileede Naijiria lati ni nọmba idanimọ wọn, ati lati so ẹrọ ibanisọrọ papọ mọ nọmba idanimọ.
Eyii ni ijọba apapọ lohun ṣe lati dẹkun iwa ijinigbe, jibiti ati oniruuru iwa ọdaran kaakiri.
O ti wa di dandan fun gbogbo ẹni to ba fẹẹ ni apo aṣuwọn nile ifowopamọ yoowu lorileede Naijiria lati ni nọmba idanimọ, ki wọn si so o papọ mọ nọmba aṣuwọn wọn.
Latigba ti eto iforukọsilẹ fun ninu nọmba idanimọ ti a mọ si National Identity Management Commission, NIMC ni awọn eeyan ti n ni oniruuru ipenija ati adojukọ bii aṣikọ orukọ, ọjọ ibi ati bẹẹbẹẹlọ.
Pupọ awọn to n koju ipenija yii ni wọn si n fẹ ṣe atunṣe lasiko, ṣugbọn ti oju opo ayelujara ileeṣẹ NIMC naa si n koju ipenija ni gbogbo igba, eyi ti ko jẹ ki awọn eeyan ṣe aṣeyọri lati yanju iṣoro wọn.
Eyi ti wa la ọna atijẹ silẹ fun awọn kan lati maa fi lu awọn araalu ni jibiti, nipa gbigba owo lọwọ wọn pẹlu ẹtanjẹ wi pe awọn yoo ba wọn tan iṣoro wọn.
Lọjọ Ẹti, ọsẹ yii ni alakoso agba fun ileeṣẹ to n ri sọrọ iforukọsilẹ naa, Abisoye Coker-Oduṣọtẹ jẹ ko di mimọ pe ọwọ awọn ti tẹ awọn kan to n fi orukọ ileeṣẹ wọn lu araalu ni jibiti.
Coker-Oduṣọtẹ sọ pe owo ti ko din ni ẹgbẹrun lọna ọgọfa naira ni wọn n gba lọwọ awọn eeyan lati fi tan wọn jẹ pe wọn yoo ba wọn yanju iṣoro ti wọn ba ni.
O fi kun un pe itosi ẹka ileeṣẹ wọn ni awọn to n lu jibiti naa ṣi ayederu ọfiisi si, ti wọn si tun ni ayederu oju opo ayelujara lati maa fun awọn eeyan ni nọmba idanimọ ti ko wa lati ọdọ awọn.
Ninu ọrọ rẹ, Coker-Oduṣọtẹ ṣalaye pe “Mo fẹẹ sọrọ lori ilọnilọwọgba, irufin ati titapa si ofin aabo aṣiri ẹni. Nigba ti a ṣe iwadii wa, a ṣakiyesi pe nitosi awọn ọfiisi wa, awọn kan n pe ara wọn ni oṣiṣẹ wa.
“Awọn wọnyi lọ si ayederu ojo opo ayelujara, ati pe ṣọọbu ti awọn eeyan ti n ṣiṣẹ ori ayelujara (Cyber Cafe), ti wọn si n gba owo lọwọ awọn eeyan.
“Awọn iforukọsilẹ ti n ṣe fun awọn eeyan yii ko de ọdọ wa, ọpọ ọmọ Naijiria ni wọn si ti lu ni jibiti.
“A ko nii gba wọn laaye lati maa ṣebi ẹni pe ara wa ni wọn jẹ. Ọpọ awọn eeyan ti sọ owo wọn nu lori igbesẹ yii. Mo gbọ nipa iṣẹlẹ kan nitosi ọkan lara awọn ọfiisi wa, nibi ti wọn ti gba ẹgbẹrun lọna ọgọfa naira lọwọ obinrin kan lati ṣe ayiapda ọjọ ibi rẹ.”
Nigba to n sọ nipa bi awọn eeyan ṣe fi orukọsilẹ si, Oduṣọtẹ ni awọn to le ni miliọnu lọna ọgọrun-le-ni-meje (107.34m) lo ti fi orukọ silẹ loṣu karun-un, ọdun yii, ni afikun si awọn miliọnu mẹrinlelaadọrun (104m) to fi orukọsilẹ loṣu kejila, ọdun 2024.















