Ìjọba Eko dáwọn ọmọ Osun tó ń gbé Eko padà sílé, gómìnà Adelele fọnmú

Aworan

Oríṣun àwòrán, Facebook/Babajide Sanwoolu ati Ademola Adeleke

Ni opin ọsẹ to kọja ni iroyin gbode pe ijọba ipinlẹ Eko da awọn eniyan eniyan ipinlẹ Osun pada si ilu wọn, ti wọn si ko wọn kuro ni ipinlẹ Eko.

Kọmiṣọna feto iroyin ipinlẹ Eko, Gbenga Omotoso ninu atẹjade kan to fi sori ikanni X rẹ lọjọ Karun-un, oṣu Karu-un ọdun 2024 ni pe ko din ni eeyan 450 to n hu iwa ko tọ ni ipinlẹ Eko ni awọn ti ko kuro ni aarin igboro.

Omotoso ni 79 ninu awọn eeyan naa ni ijọba Eko ti fi si ile itọju ti wọn ti maa tọju wọn, ti wọn si maa yi wọn lọkan pada lori awọn iwa ti wọn n wu.

O ni awọn eeyan yooku rọ ijọba Eko lati ran awọn lọwọ ki awọn le pada si ilu awọn ti awọn ti wa si ipinlẹ Eko ti awọn si ṣe bẹẹ.

Omotoso ni igbesẹ yii, lati maa da awọn eeyan ti wọn nilo amojuto ati itọju pada si ipinlẹ koowa wọn yoo tẹsiwaju lojuna ati fọ ipinlẹ Eko mọ tonitoni, àti lati ri pe eto aabo ipinlẹ Eko duro ire.

Wọn ni lara awọn eeyan ti awọn ran lọwọ naa lo jẹ awọn eeyan ipinlẹ Osun atawọn ipinlẹ mii.

Igbesẹ ijọba ipinlẹ Eko ti wa n fa awuyewuye bi awọn kan ṣe n sọ pe nnkan ti ijọba Eko ṣe ko ba ofin mu ati pe o jẹ titẹ ẹtọ awọn eniyan ti ọrọ naa kan loju mọlẹ.

Ṣugbọn Omotoso ni ipinnu ijọba ipinlẹ Eko ni igbesẹ naa ati pe awọn ṣi tun maa tẹsiwaju lori rẹ.

O ni bi awọn to n tọrọ owo, atawọn ti ko ni alafia to peye ṣe n wọ ipinlẹ Eko lojumọ ti pọ pupọ ju, to si n fa ibẹrubojo sọkan awọn olugbe Eko.

Gomina ipinlẹ Ademola Adeleke ni ọrọ naa ya oun lẹnu nigba ti oun gbọ ati pe oun maa kan si akẹgbẹ oun ni ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu lati fidi ohun to ṣẹlẹ mulẹ gan-an.

Yatọ si gomina ipinlẹ Osun, oludije sipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu Labour Party, Peter Obi naa bu ẹnu atẹ lu igbesẹ naa to si ni o lodi sofin Naijiria.

Se loootọ ni pe ilu Ilesha ni wọn ko awọn eeyan naa lọ?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ohun ti a gbọ ni pe ilu Ilesha ni ijọba ibilẹ Ilesha West ni awọn ọkọ bọgini ti ijọba Eko fi da awọn eeyan naa pada si ja wọn si.

BBC News Yoruba kan si ilu Ilesha boya a maa ṣe awari diẹ ninu awọn eeyan naa.

Ọjọ meji gbako ni akọroyin wa lo ni ilu Ilesha fun iwadii awọn eeyan ọhun amọ gbogbo akitiyan akọroyin wa lati le ri awọn eeyan naa ba sọrọ lati le bere iriri wọn lo ja si pabo.

Akọroyin wa to lọ si ilu Ilesha ko ri ẹnikankan ninu awọn ti wọn da pada si ipinle Osun lati ipinle Eko naa.

A ṣe alaba pade arabinrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Adebimpe Oluwole to n gbe ni agbegbe Sabo niluu Ilesha to si ni oun ri ọkan lara awọn eeyan naa.

O ni ọpọ lara awọn eeyan ti wọn da pada sile ọjun ni ko si nkankan to n ṣe wọn rara nitori pe oun ni eeyan kan ninu wọn to sọ fun oun pe gbogbo awọn ni ko si nnkan to ṣe awọn.

Arabinrin Adebimpe wa rọ Gomina Ademola Adeleke lati se ipade pọ pẹlu Gomina Ipinle Eko Babajide Sanwoolu ki oun gbogbo le lọ bo se yẹ ko ri.

BBC Yoruba kan si Kola Olabisi ẹni ti o wa fun eto iroyin fun ẹgbẹ Oselu APC nipinlẹ Osun.

Kola Olabisi naa fidi Isẹlẹ naa mulẹ pe o ku diẹ ka to ohun ti ijọba ipinle Eko se.

O ni, "o yẹ ki asọ ye wa laaarin ipinle mejeeji ki iru igbesẹ naa to waye."

O tesiwaju pe, ki ni ipa ti Gomina Ademola Adeleke ti ko lori ọrọ naa lati igba ti o ti ṣẹlẹ? Ati wi pe, se ìjọba Ìpínlẹ̀ Osun fi oju kan awọn eeyan ti ìjọba Ìpínlẹ̀ Eko da pada yii?

O woye pe ilu ti wọn ko awọn eeyan naa lọ lo jẹ ilu ti awọn ọmọ ganfe pọ si julọ ni ipinle Osun ati pe oun ko mọ ohun to le ṣẹlẹ ti ìjọba Gomina Ademola Adeleke ko ba wa awọn eeyan naa.

Kola Olabisi wa rọ gbogbo olugbe IpInlẹ Osun ki wọn ṣe ara wọn ni oju ni alakan fi n ṣọri lakooko yii, paapa julọ awọn olugbe ilu Ilesha.

Ki ni ijọba ipinlẹ Osun sọ lori ọrọ yii?

Gbogbo akitiyan lati le ba agbẹnusọ fun Gomina Ipinle Osun Olawale Rasheed lo jasi pabo.

Sugbọn a kan si Kọmisọna fun eto Iroyin nipinle Osun, Kolapo Alimi.

Kolapo Alimi ni ohun ti ijọba ipinle Eko se ko dara rara ati wi pe oju oṣelu ni awọn ara ilu yoo fi maa wo iṣẹlẹ naa.

O ni Gomina Ademola Adeleke ti ba Gomina Babajide Sanwoolu sọrọ lori Isẹlẹ naa, ti Gomina Ipinle Eko ni oun ko mọ nkankan lori igbesẹ naa rara.

Kolapo Alimi tun wa fi kun ọrọ wi pe awọn ko dakẹ lori Isẹlẹ naa ati wi pe, Gomina Ademola Adeleke ti yan awọn igbimọ kan lori Isẹlẹ naa.

O sọ pe ootọ ni awọn ko ri ẹnikankan ninu awọn eeyan naa lẹyin fidio to jade sita lori ayelujara.

Ìwà tí kò bójúmu ni ìjọba Eko hù yìí - Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn

Waheed Lawal ẹni to jẹ aja fun ẹtọ ọmọniyan nipinlẹ Osun ti sapejuwe Ìwa ti ijọba ipinlẹ Eko gẹgẹ eyi tí ko boju mu ti ko si tun ba ofin mu pẹlu nípa igbesẹ ti wọn gbe lati da awọn ọmọ ipinlẹ Osun pada sile.

Lawal nigba to n ba BBC sọrọ, o ni igbesẹ ti ijọba ipinle Eko gbe dabi bi ẹni ti ko ni arojinlẹ rara.

O ni, iwa to le da wahala silẹ ni iwa naa ati wi pe, ofin orile-ede yii fi aye gba ẹnikẹni lati gbe ibi to ba wu lati gbe.

Waheed Lawal tun tesiwaju wi pe, o yẹ ki Gomina Babajide Sanwoolu fi ọrọ naa to Gomina Ademola Adeleke ti Ìpinlẹ Osun leti ki iru igbesẹ naa ko to waye.

Waheed Lawal tun wa sọ wi pe, oju ti oun fi wo ọrọ yii ni wi pe, o ti ni ọwọ oselu ninu, to ba si ri bẹẹ ko dara rara.