Tí ìjọba kò bá yọ àfikún owó iná kúrò, ìwọde wa yóò di ìyanṣẹ́lódì - Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ fọ́nmú

Apapọ ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC ati TUC gbe ọfiisi ileeṣẹ Disco to n pina ati ajọ NERC to n mojuto ọrọ ina mọnamọna ni Naijiria tipa niluu Abuja, Eko, Ibadan, Osogbo ati kaakiri awọn ipinlẹ Yoruba lati fẹhonu han lori afikun owo ina ti ijọba kede rẹ laipẹ.
Awọn oṣiṣẹ yabo ọfiisi ileeṣẹ IEDC to n pina ni Ikeja l'Eko nibi ti wọn ti n kọrin, ti wọn ṣi n pe fun iyọkuro afikun owo ina ọba.
Awọn oṣiṣẹ ko jẹ k'awọn eeyan to n ṣiṣẹ pẹlu ajọ Disco ati NERC ri aye wọ ọfiisi wọn lẹyin ti wọn ti di gbogbo ọna ti wọn le gba kọja.
Ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC fi agadagodo ti ọfiisi ajọ NERC pa l'Abuja

Aarẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC, Joe Ajaero lo ṣiwaju awọn oṣiṣẹ lonii ọjọ Aje niluu Abuja nibi ti wọn ti n ṣe ifẹhonuhan tako afikun owo ina ọba ti wọn ṣi gbe ọfiisi ajọ to n ri ọrọ ina mọnamọna tipa.
Awọn oṣiṣẹ n beere fun ayọkuro afikun owo ina ti ijọba kede rẹ laipẹ yii ni kiakia.
Wọn ni awọn oṣiṣẹ ko tii le ra ounjẹ jẹ pẹlu N30,000 owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ, níbẹ ni ijọba tun ti ṣe afikun owo ina ti ko ṣe deedee tẹlẹ.

Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ti sọ fun ijoba tẹlẹ pe, awọn fun wọn di ọjọ kejila, osu karun-un, ọdun 2024 lati ri daju pe wọn wa nnkan ṣe si afikun owo naa.
Nigba ti Ijọba si kuna lati wa nnkan se si, wọn pe ara wọn jọ lati ti awọn ile ise naa pa, ile ise NERC ati DisCos.
Apapọ ẹgbẹ oṣiṣẹ ti ileeṣẹ IBEDC ati NERC pa l'Oyo
Agbarijọpọ ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC àti TUC ipinle Oyo sọ agadagodo ṣẹnu ilẹkun ile iṣe awọn oṣiṣẹ to wa nilẹ iṣẹ ajọ to mojuto ina manamana ọba (IBEDC) to wa ni agbegbe Ringroad ati Magara niluu Ibadan.
Ifẹhonuhan han naa lo bẹrẹ laarọ oni ni dede aago meje aabo laarọ yii.
Lara awọn oun ti wọn kọ sinu iweagbelawọ wọn ni, "Nigeria Ko faramo ẹkunwo owo ina monamona,iya yii pọ ẹgbẹ oṣiṣẹ ko fọwọsi ẹkun wo ina monamona,awọn oṣiṣẹ orilẹ-ede yii kofẹ ẹkunwo ina monamona".
Alaga egbe awọn oṣiṣẹ ipinlẹ oyo Kayode Martins ati akẹgbẹ rẹ lati ẹgbẹ awọn to n ṣọwọ TUC Rantí Gbenle-Wemimo ni otogẹ bayii.


Ẹgbẹ oṣiṣẹ ko le laju silẹ ki Ijọba apapọ ma gbowo le gbogbo ohun tí awọn ọmọ orilẹ-ede yii n jẹ igbadun ninu iṣejọba.
Martins ni,"lati igbati ijọba ti yo ekunwo lori epo bẹntiro,nisẹ ni wọn n fi oju pọn awọn ọmọ orilẹ-ede yii, pẹlu afikun to tun ba owo ina monamona, o fihan wi pe ijọba yii ko laanu awọn mekunu loju".
Awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ ipinlẹ Oyo rọ Aarẹ Bola Tinubu ati minisita Adebayo Adelabu lati yii ipinnu wọn pada nitori ẹgbẹ oṣiṣẹ kọ afikun to ba owo ina monamona.
Ti ijọba ko ba yọ afikun owo ina kuro, ifẹhonuhan wa yoo di iyanṣẹlodi - Ẹgbẹ oṣiṣẹ Kwara

Alaga ẹgbẹ osisẹ NLC ẹka ti ipinlẹ Kwara Muritala Saheed Olayinka loni ọjọ kẹtala osu karun-un ọdun 2024 sọ pe o di ọranyan fun ijọba lati tẹti si awọn tabi ki awọn gunle iyansẹlodi gbogbogbo.
O sọ eyi nibi ifẹhonuhan lori ọwọn gogo ina ọba ti ẹgbẹ NLC ati TUC bẹrẹ loni.
Awọn ẹgbẹ ọhun lo korajọ si olu Ileesẹ ina ọba (IBEDC) to wa lagbegbe Challenge, ni ilu Ilorin ti o jẹ olu ilu ipinlẹ ọhun, wọn si gbe e ti pa.
Yatọ si ti eleyi, ṣe ni awọn kan tun kọja lọ si Ileesẹ IBEDC to wa ni Baboko, Ilorin lati ri daju pe oun naa wa ni titi pa.
Lati aago meje owurọ ni wọn ti parapọ sibẹ ti wọn o si gba osisẹ IBEDC kankan laaye lati kọja sinu ọfisi wọn.
Nigbati alaga ẹgbẹ osisẹ (NLC) ni ipinlẹ ọhun, iyẹn Comrade Muritala Saheed Olayinka n ba BBC News Yoruba sọrọ, o ni awọn ko ni dawọ ifẹhonuhan naa duro titi ijọba yoo fi din owo ti araalu n san lori ina mọnamọna ku.
O ni wọn kii se pe ina ko duro dede sugbọn wọn tun fi owo kun iye owo ina, o si jẹ inira fun gbogbo ọmọ orilẹ-ede Naijiria, ati olowo, ati mẹkunu.
O salaye pe ẹgbẹ NLC ati TUC ti sekilọ saaju ki wọn da owo ina mọnamọna naa pada, sugbọn wọn kọti ọgbun sii, pe idi niyi ti awọn fi gunle ifẹhonuhan.
O fi kun-un pe titi wọn yoo fi yi ipinnu wọn pada, awọn naa yoo ri pe Ileesẹ ina ọba wa ni titi pa.
Apapọ ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC ati TUC ti ileeṣẹ IBEDC ati NERC pa l'Ekiti
Apapọ ẹgbẹ osisẹ NLC ati TUC ni ipinlẹ Ekiti darapọ mo ifẹhonuhan lori bi ijoba apapo Naijiria ṣe fi owo kun iye owo ina monamona yabo ilé ise NERC ti o wa ni opopona Iworoko ati ọfisi IBEDC ti o wa ni agbegbe Ajilosun Ado-Ekiti.
Alaga ẹgbẹ osisẹ TUC ni ipinlẹ Ekiti, Sola Adigun lọ siwaju ifẹhonuhan naa lọ si ofisi NERC pẹlu akowe ẹgbẹ osisẹ NLC Israeli Taiwo ni dede ago meje owuro ti wọn si fi agadagodo ti ẹnu gate ti wọn si tesiwaju lọ ọfisi IBEDC ni agbegbe Ajilosun ti wọn ti gbe ibe naa ti paa pẹlu agadagodo.
Nigba ti alaga egbe osisẹ TUC Ọgbeni Sola Adigun ati akọwe ẹgbẹ osisẹ NLC Israel Taiwo ni ipinlẹ Ekiti ba awọn akoroyin sọrọ ni ohun ti ẹgbẹ awọn n bere fun ni lati da owo ina pada si bi o ṣe wa tẹlẹ ati wipe ki ile isẹ monamona pese prepaid meter fun gbogbo Ile ti o wa ni Naijiria.
Wọn ni awọn ko ni si kọkọrọ agadagodo ti wọn fi ti ẹnu ọna ọfisi NERC àti IBEDC ni ipinlẹ Ekiti, afi ti awọn adari ẹgbẹ wọn ni Abuja ba fun awọn ni àṣẹ.
Agbara wa ko gbe afikun owo ina mọnamọna - Ẹgbẹ oṣiṣẹ ipinlẹ Osun

Apapọ egbe òṣìṣẹ́ NLC ati TUC se iwọde tako afikun owo ina mọnamọna ti wọn fi kun.
Iwọde naa lo bẹrẹ loni ọjọ Kẹtala osu Karùn-ún ọdun 2024 yii niluu Osogbo nipinlẹ Ọsun.
Orin ti awọn ẹgbẹ naa nkọ ni wi pe, awa ko ni gba fun ijọba to fi ara ni wa ni orile-ede yii ati wi pe, awa ko ni gba ki wọn fi owo kun owo ina mọnamọna rara.
Alaga ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC nipinlẹ Ọsun, Christopher Arapasopo o ni idi ti iwọde Ifẹhonuhan fi waye ni bi owo ina mọnamọna ti di ohun ti ọpọ eeyan ko le ra tabi san owo naa mọ.
O ni" awọn ko ni gba fun oṣiṣẹ ileesẹ ina mọnamọna kankan lati wọ ofisi wọn titi ijọba yoo fi da afikun owo ina naa pada si eyi ti agbara yoo gbe.
Christopher wa tun fi kun ọrọ rẹ wi pe, ki gbogbo osisẹ ijọba apapọ, Ìpínlẹ̀ ati aladani paapa gbogbo ara iluu ko dide ki wọn jọ sowọ pọ ja ija naa.
Alaga ẹgbẹ osisẹ TUC ẹ̀ka ti lpinlẹ Osun, Abimbola Fasasi ti se apejuwe ijọba bi ika eeyan ati amọtara ẹni nikan bi wọn se fi kun owo ina mọnamọna.
Abimbola tun tesiwaju wi pe, ki iseijọba Bola Ahmed Tinubu ko jawọ kuro ninu iwa ati maa ni ara iluu lara.
Ẹgbẹ oṣiṣẹ ipinlẹ Ondo ko jade fun ifẹhonuhan tako afikun owo ina ọba

Ẹgbẹ osisẹ ti ẹka ipinlẹ Ondo ti kọ iha ko kan mi si aṣẹ aarẹ ẹgbẹ naa Joe Ajaero to pe fun iwọde ifehonuhan lọ awọn ileeṣẹ apinaka jake jado orileede yii tako yiyọ owo iranwọ ina monamona.
Iyalẹnu nla lo jẹ bi ileeṣẹ BBC Yoruba ṣe sagbewo si olu ileeṣẹ apinaka Ipinlẹ Ondo ni Nepa n'iluu Akure to si jẹ pe ko si ifarahan ẹgbẹ awọn osisẹ de bi pe wọn yoo se ifehonuhan loriko naa.
Lasiko abewo yii ni a ri wi pe enu ona ileese naa wa ni ti ti pa, sugbọn ki i se latọwọ awọn adari osisẹ sugbọn latọwọ awọn osisẹ ileeṣẹ naa, ti wọn ni wọn yanselodi latari afikun owo ina manamana.
Eniyan perete lara awọn osisẹ ileeṣẹ naa ni wọn pejọ si ẹnu ọna abawole.
Ọkan lara osisẹ naa ti ko fẹ jẹ ki orukọ rẹ di mimọ salaye pe wọn gun le iyanselodi lati le jẹ ki ijọba mu adinku deba owo ina monaona bi o se safikun rẹ pe ko si oṣisẹ ti yoo wọ inu ileeṣẹ naa ti ti ti ijọba yoo fi gbe igbese ti o yẹ.
Ninu ifọrọwerọ pẹlu alaga ẹgbẹ NLC nipinlẹ Ondo Victor Amoko lati mọ idi ti ipinlẹ naa ko fi ni nkankan ṣe pẹlu ifẹhonuhan awọn oṣiṣẹ jakejado Naijiria tako yiyọ owo iranwọ ina mọnamọna, Ogbẹni Amoko salaye pe NLC ati TUC Ipinlẹ Ondo ko i ti ni asọye lori igba ti wọn yoo ṣe iwọde ifehonuhan l'Ondo.
Amoko sọ di mimọ pe ko pọn dandan ki wọn ṣe ifehonuhan yi pẹlu awọn ipinlẹ to ku lọjọ kan naa, sugbọn wọn yoo ṣe ipade lati mọ ọjọ gan ti wọn yoo yan lati se iwọde ifehonuhan yii.
Akitiyan lati ba alaga TUC Comrade Clement Fatuase sọrọ lo jasi pabo.
Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ gùnlé ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn láti tako àfikún owó iná mọ̀nàmọ́ná

Oríṣun àwòrán, NLCNG.ORG
Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lorileede Naijiria ti Nigeria Labour Congress, NLC ti kede sita pe awọn yoo bẹrẹ iwọdẹ ifẹhonuhan lori afikun owo ori ina mọnamọna kaakiri orileede Naijiria.
Ninu atẹjade ti akọwe ẹgbẹ naa, Chris Uyot buwọ lu lọjọ kẹjọ, oṣu karun-un, ọdun 2024, eyi ti ẹda rẹ tẹ BBC lọwọ, oni ọjọ Aje, ọjọ kẹtala, oṣu karun-un ni iwọde ọhun yoo waye.
Uyot sọ pe awọn yoo fẹhonu wọn han ni ọfiisi Nigerian Electricity Regulatory Commission(NERC) ati AEDC to wa niluu Abuja.
Bẹẹ lo tun sọ pe gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ wọn kaakiri ipinlẹ to wa lorileede yii ni yoo jade lati fẹhonuhan lati kopa ninu ifẹhonuhan ọhun, bẹrẹ lati agogo meje owurọ.
O ni ipinnu yii wa lẹyin ipade ti igbimọ amuṣẹṣe ẹgbẹ naa, iyẹn Central Working Commission ṣe, ti wọn si fi ẹnu ko wi pe awọn ko le tẹwọ gba afikun owo ori ina mọnamọna.

Oríṣun àwòrán, NLC
Ki lo de ti ẹgbẹ fi gun le iwọde naa?
Bi ẹ ko ba gbagbe, ninu oṣu kẹrin ọdun yii ni ijọba apapọ nipaṣẹ ileeṣẹ NERC ni oun buwọ lu afikun lori owo ina mọnamọna fun awọn onibara wọn to wa labẹ isọri ti wọn pe ni Band A.
Afikun ọhun ni wọn kede ninu atẹjade ti igbakeji alaga NERC, Musliu Oseni buwọ lu.
Oseni sọ pe awọn onibara wọn yoo bẹrẹ sii san naira marundinlọgbọnlenigba (N225/kWh) dipo naira mejidinlaadọrin (N68/kWh).
Lẹyin eyi ni ileeṣẹ NERC tun kede pe awọn ti din afikun owo naa ku si naira mẹfalenigba-le-mẹjọ (N206.8/kWh).
Afikun owo yii ni ijọba sọ pe yoo jẹ ki awọn le tọju owo to to tiriliọnu kan aabọ (N1.5tr) naira.
Ijọba tun jẹ ko di mimọ pe afikun naa yoo bẹrẹ sii fẹsẹ mulẹ lati ọjọ kẹta, oṣu kẹrin, ọdun 2024, pẹlu ileri wi pe awọn onibara to wa lori isọri Band A yoo bẹrẹ sii jẹ igbadun ina fun ogun wakati lojumọ.
Bi iroyin ọhun ṣe jade ni ile igbimọ aṣoju-ṣofin, apapọ ẹgbẹ oṣiṣẹ, ẹgbẹ awọn agbẹjọro lorileede yii, ẹgbẹ to n ri sọrọ okoowo, ohun amuṣọrọ ati iṣẹ agbẹ, to fi mọ gbogbo awọn onibara ina mọnamọna ni wọn dide lati tako afikun naa.
Ile igbimọ aṣoju-ṣofin ranṣẹ pe awọn alakoso NERC lati wa sọ idi ti wọn fi fowo kun owo ori ina mọnamọna
Ṣugbọn nigba to n sọrọ niwaju ile igbimọ aṣofin lori idi pataki ti ijóba fi gbe igbesẹ ọhun, Minisita fọrọ eto ina ati agbara, Adebayọ Adelabu jẹ ko di mimọ pe gbogbo Naijiria ni yoo wa ninu okunkun fun oṣu mẹta gbako bi awọn ko ba fi kun owo ori ina mọnamọna.
















