‘Àwọn láńlọọ̀dù kọ̀ láti fún mi nílé nítorí n kò rẹwà lọ́mọbìnrin’

Aworan ọmọbinrin kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Michael Ngene
    • Role, BBC Journalist
    • Reporting from, Lagos

Lati ni ibugbe ṣe pataki pupọ fun ẹda eeyan kaakiri agbaye. Ohun to si tun ṣe pataki ni fun awọn eeyan lati ni ile lori, paapaa julọ awọn ọdọmọbinrin ti wọn jẹ omidan.

Ko yẹ ko si wahala tabi iṣoro fun ọkunrin tabi obinrin lati ni ile, yala ayagbe ni tabi akọgbe.

Ṣugbọn bi nnkan ṣe ri bayii, awọn ọdọmọbinrin kan n la oriṣiriṣi iṣoro kọja lati ni ile lori ni Naijiria.

‘Ohun ti oju ti ri’

Aworan omobinrin kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọmọbinrin kan to pe orukọ ara rẹ ni Olive Emodi sọ fun wa pe oju oun ri mabo ko to di pe oun ri ile gba niluu Eko.

O ni ọpọ awọn lanlọọdu ni wọn gbe ofin kalẹ, eyi to lodi si ki ọdọmọbinrin lati maa gbe ninu ile wọn.

“Awọn lanlọọdu kan sọ fun mi pe awọn ko le fun mi ni ile nitori ti wọn ko fẹ ki awọn ọkunrin maa pọ ninu ile wọn.”

“Ọkan lara wọn sọ fun mi pe awọn obinrin maa n ni ọrẹkunrin to pọ, ti wọn si maa n wa wọn wa sile ni gbogbo igba. O ni lawọn igba miiran, awọn ọkunrin yii maa n pade ara wọn, ti wọn si maa bẹrẹ ija pẹlu ara wọn.

“O sọ fun mi pe ija wọn maa n ba dukia jẹ ninu ile oun.

“Ohun to ba mi lọkan jẹ julọ ni igba ti alabagbe mi kan sọ fun mi pe bi o ba fun mi nile, mi o gbọdọ jẹ ki agogo mẹsan-an alẹ lu ki n to wọle.”

Siwaju sii ni Olive tun ṣalaye fun BBC pe iya onile kan sọ fun oun pe idi toun kii ṣe e gbe ile fun awọn ọmọbinrin ni pe wọn maa n tete ka ọpọlọpọ nnkan kun ju.

Awon agbegbe kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Bisọla Adejumọ sọ fun BBC pe alabagbe oun sọ fun oun pe nitori oun ko dun un wo lọmọbinrin ni ko jẹ ki wọn gbe ile silẹ fun oun.

O ni “O beere lọwọ mi pe 'ta ni ẹ?, mi o kii n gbe ile silẹ fun awọn ọmọbinrin ti ko ba ti rẹwa’.”

Bakan naa, Sarah Orji naa jẹ ọmọbinrin toun naa ni iṣoro ati ipenija to pọ lasiko to n wa ile ti yoo maa gbe.

Sarah ni, “lanlọọdu kan gba lati gbe ile silẹ fun mi, ṣugbọn iyawo rẹ lo sọ pe rara.

“Mi o mọ idi ti iyawo ọkunrin naa ko ṣe fẹ ki ọkọ rẹ gbe ile silẹ fun mi, wọn ko si jẹ ki n mọ boya ọkọ rẹ gba.

“Nigba ti mo beere lọwọ obinrin naa nipa idi ti ko ṣe fẹ ki wọn fun mi ni ile, ohun to sọ ni pe ‘ọkunrin nikan lo le gbe inu ile mi, mi o fẹ ọmọbinrin’.

“Ọkan lara awọn to n gbe ile silẹ fawọn eeyan, eyi ti awọn oloyinbo n pe ni ajẹnti (House Agent) sọ fun mi pe ki n lọ wa ọkọ bi mo ba fẹ wọ fasiti.”

Eyi ba ni lọkan jẹ.

O ṣe pataki fun gbogbo eeyan lati pa imọ wọn pọ wi pe ikorira fun awọn ọmọdebinrin ti wọn n wa ile lati gbe di ohun atijọ.

Ṣugbọn sibẹ, ki lo wa de ti awọn tọkọ-tiyawo kii fẹẹ ki awọn ọlọmọbinrin ti wọn ko tii ṣe igbeyawo gbe ninu ile wọn?

Idi ti a ko ṣe n gbe ile fun awọn ọmọbinrin

Aworan okunrin kan to n dahun ipe

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọmọbinrin kan toun naa n wa ile sọ pe ọpọ awọn onile toun ba ṣiṣẹ pọ ko gba awọn ọdọmọbinrin sile lati maa gbe nitori ti wọn ko fẹ ki wọn ma san owo ile.

Idowu Gbenga jẹ iya onile nipinlẹ Eko.

O ni awọn ara oun kii fẹ fun awọn ọlọmọbinrin ni ile lati gbe nitori pe ninu wọn lo n gbe igbe aye ti ko dara, ati pe pupọ ninu wọn ni ko mọ bi wọn ṣe n tun ile ṣe.

Siwaju sii lo ni ki oun to le fun ọdọmọbinrin ni ile gbe, oun nilo lati ṣe iwadii daadaa nipa awọn imọ ati irori rẹ daadaa.

O ni bi ọdọmọbinrin ba mura to ṣi ara rẹ silẹ, oun ko nii gbe ile silẹ fun un.

Idowu tun fi kun ọrọ rẹ pe “Mi o kii gbe ile silẹ fun ọdọmọbinrin to ti ni ọmọ ṣugbọn ti ko tii ṣe igbeyawo, nitori pe wọn fẹ ni ile lati maa gbe, ṣugbọn to jẹ pe iṣoro ni yoo jẹ fun wọn lati san owo ile.”

‘Kii ṣe iwa wọn ni ẹkun Ila-Oorun’

Aworan okunrin kan to n gbategun niwaju ita ile re

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọkunrin kan to ni ile nipinlẹ Eko, Uche Peter Okafor ṣalaye pe ikorira si awọn ọdọmọbinrin ko si ninu iwa ati iṣesi awọn ara agbegbe Owowa Anyanwu.

Okafor ni “Mi o kii kọ lati gbe ile mi silẹ fun awọn ọdọbinrin ti wọn ko tii si nile ọkọ, ohun to ṣe pataki si mi ni pe ki wọn maa ri owo ile mi san.”

Siwaju sii lo sọ pe awọn onile kan kii fẹẹ gbe ile silẹ fun awọn ọlọmọbinrin nitori pe awọn miran ninu wọn maa sọ ile yin di ile ayẹyẹ fun awọn ọrẹ wọn.

Lapa keji, Okafor sọ pe nigba miran, awọn ọlọmọbinrin yii maa n fẹ ba awọn to n tọju ile tabi awọn onile lajọṣepọ, eyi ti yoo jẹ ki awọn to n tọju ile naa gba iyekiye owo lọwọ wọn.

Ki wa ni ofin sọ?

Aworan agbejoro

Oríṣun àwòrán, FRED NZEAKO

Agbẹjọro Fred Nzeako sọ fun BBC pe ofin ko lodi si ki awọn onile tabi awọn agbanisile gbe ile silẹ fun awọn ọdọmọbinrin.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe “Ofin ko tako o wi pe ki wọn ma ṣe gbe ile silẹ fun ẹnikẹni, yala ọkunrin ni tabi obinrin, bo tilẹ jẹ pe onile lo le sọ iru ẹni toun fẹẹ gba sile.

“Ibi ti ofin ti koro oju ni pe nigba ti onile ba sọ pe oun ko nii gbe ile silẹ fun ọmọbinrin ti ko ba tii ṣe igbeyawo.

“Bi ibikankan ba wa ti onile ba ti sọ pe oun ko nii gbe ile silẹ fun ọlọmọbinrin, ile ẹjọ le pe iru onile bẹẹ lati beere idi to fi ṣe ipinnu naa.

“Ti iwadii ba wa pada fi idi rẹ mulẹ nipa erongba yii, ti wọn si rii pe ohun ti onile naa kọ sita tako ofin, ile-ẹjọ le fi iya jẹ iru ẹni bẹẹ labẹ ofin.”