"Akẹ́kọ̀ọ́gboyè fásitì ni mí, ìfẹ́ sí iṣẹ́ ọwọ́ ló mú mi kọ́ iṣẹ́ àtúnṣe AC mọ́tò"
Ori lo mọ isẹ asela, ẹni ti yoo ga, ẹsẹ rẹ yoo tiirin.
Ile ẹkọ fasiti ni Ayotomiwa Razak, ẹni ọdun mejilelogun, ti kẹkọ gboye imọ ijinlẹ, tó sì gba ipo First class, eyi to tumọ si pe ori rẹ pe pupọ.
Amọ lasiko to wa nile ẹkọ, ni Ayotomiwa ti bẹrẹ si kọ isẹ ọwọ nipa bi wọn ti n se atunse ẹrọ to n mu inu mọto tutu.
Nibayii to ti di ọga isẹ funra rẹ, Ayotomiwa ba BBC Yoruba sọrọ kori ohun to mu ko kọ isẹ naa bi o tilẹ kawe de fasiti.
Bakan naa ni Ayotomiwa salaye ọpọ iriri ti oju rẹ ri lẹnu ẹkọṣẹ naa ati ọna to fẹ gba fi iṣẹ naa jẹun.

"Bi mo ba pẹ de ibi isẹ, maa jẹgba, ọpọ apa gba lo wa lara mi"
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori ohun ti oju rẹ ri niẹnu isẹ, Ayotomiwa ni bi o tilẹ jẹ pe akẹkọ fasiti ni oun, ti oun fi wa kọ isẹ, sibẹ, wọn maa n na oun.
"Ọga mi kii ya mi sọtọ laarin awọn ọkunrin, ohun ti wọn ba n se fawọn ọkunrin, naa ni wọn n se fun mi.
Koda, wọn maa n na mi, ti mo ba pẹ de ibi isẹ, ti ọpọ apa ẹgba si wa lara mi.
Sugbọn ohun to dun mi julọ, ti n ko le gbagbe ni onibara wa kan to kọ lati gbe isẹ mọto rẹ fun mi.
Onibara naa ni ọmọ ẹkọsẹ ni mi , ṣga mi nikan si lo le tun ẹrọ yinyin inu ọkọ oun ṣe.
Mo wa n rọ awọn eeyan pe iru iwa bayii ko dara to. Mọto ti ọkunrin naa ko jé ki n se ki ọga mi to de, emi naa ni mo papa se isẹ naa."

"Mo beere pe se mo le fi isẹ ti mo kọ naa jẹun, ọga mi ni ki n maa fori ti i"
Ayotomiwa tẹsiwaju pe nigba ti ominu n kó oun lori iṣẹ ti oun kọ naa ati ọjọ iwaju rere to wa fun, oun ba ọga oun sọrọ nipa rẹ.
"Mo bi ọga mi leere pe se mo le fi isẹ ti mo kó naa jéun amó 'sgá mi ni ki n maa fori ti i nitori ere wa fun iforiti.
Ifẹ si isẹ ọwọ si lo mu ki n kọ isẹ naa, emi si ni mo tọ ọga mi lọ pe ko fi mi se akọwe rẹ, ti yoo maa kọ iye awọn onibara to wa silẹ.
Ọgá mi si gba mi sisẹ, ti mo si n sisẹ naa lẹyin ti mo kẹkọ gboye tan.
Mo si n rọ awọn onibara lati ye fi oju tẹmbẹlu ẹni to ba n kọsẹ lọdọ ọga kan nitori ẹyin lo n di akukọ."







