Female Car Painter: Modupe ní Ọkùnrin máa ń dẹnu ìfẹ́ kọ òun tàbí fi òun ṣe yẹ̀yẹ́ torí ó jẹ́ obìnrin tó ń kun mọ́tò lọ́dà

Àkọlé fídíò, Female Car Painter: Èmi ní obìnrin àkọ́kọ́ tí yóò máa ṣiṣẹ́ akunmọ́tò ní Ibadan

Ohun ti ọkunrin le se, awsn obinrin le se ju bẹẹ lọ ni Yoruba maa n sọ.

Bo si se ri ree pẹlu obinrin kan, Modupe Olagunju, ẹni to yan isẹ kikun mọto ni ọda laayo, to si jẹ obinrin akọkọ ti yoo maa sisẹ naa nilu Ibadan.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Modupe ni iya oun lo pọn ni dandan fun oun lati kọ isẹ naa nigba ti oun si wa nile ẹkọ girama, eyi toun fi n jẹun lonii.

O salaye pe ọpọ ipenija ni oun ba pade lẹnu isẹ naa nitori awọn ọkunrin kan maa n dẹnu ifẹ kọ oun, ki wọn to gbe isẹ fun oun tabi ki wọn maa se yẹyẹ pe oun n sisẹ ọkunrin.

Bakan naa lo fikun pe sọọbu oun nikan da jona nigba ti oun bẹrẹ isẹ naa, eyi to da omi tutu si oun lọkan, tawọn ọkunrin kii si fẹ ki oun gba isọ sọdọ wọn.

Àwọn ìtàn mánigbàgbé tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Modupe Olagunju wa gba awọn obinrin nimọran lati kọ isẹ ọwọ mọ ẹkọ iwe, ki wọn si tun bẹrẹ nibi kekere, ki wọn ma baa se ju agbara wọn lọ.