Oronpoto Animation: Akin Alabi ní kò dára bí eré aláwòrán fáwọn ọmọdé ṣe jẹ́ aláwọ̀ funfun

Àkọlé fídíò, Oronpoto Animation: Akin Alabi ní kò dára bí eré aláwòrán fáwọn ọmọdé ṣe jẹ́ aláwọ̀ funfun

Ni ọpọ igba ta ba ri ere alaworan to wa fun awọn ọmọde lori ayelujara tabi mohun maworan, awọn alawọ funfun lo maa n se jade.

Amọ ọmọ Yoruba kan ree, Akin Alabi to n lakaka lati gbe asa Yoruba larugẹ, paapaa nidi ki awọn ọmọde mọ nipa asa, ede, iwọsọ ati itan wa.

Akin Alabi, to sẹsẹ se ere alaworan kan fawọn ọmọde ni ede Yoruba sọ fun BBC pe ko dara to bo se jẹ ere alaworan tawọn alawọ funfun se jade ni ede wọn nikan lawọn ọmọde wa n wo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Alabi ni ipinnu oun lati fopin si eyi lo mu ki oun se agbejade ere alaworan Orompoto ninu eyi ti awọn alawọ dudu ti kopa, ti wọn si sọ ede wa.

O ni isu mẹrin pere ni oun lee se ni ere alaworan ninu itan naa, to si n kesi awọn onileesẹ nlanla atawọn eeyan to nifẹ agbega asa ati ede Yoruba lati dide, se iranwọ owo fun oun, ki isẹ naa lee pari.